Nengi Adoki
Nengi Adoki | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 17 Oṣù Kínní 1990 Port-Harcourt |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Toronto |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2013–present |
Gbajúmọ̀ fún | Juju Stories |
Nengi Adoki (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Kìíní ọdún 1990) jẹ́ òṣèrẹ́bìnrin ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó gbajúmọ̀ fún àwọn ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù àgbéléwò bí i Juju Stories àti Chatroom, àti àwọn fíìmù orí ẹ̀rọ bí i The Men's Club. Wọ́n dárúkọ rẹ̀ mọ́ orúkọ àwọn gbajúgbajà òṣèré ní ọdún 2021, bẹ́ẹ̀ sì ní ó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin, tí ó sì tako ìwà ìbàjẹ́ tí àwọn agbófinró ń hù.[1][2][3]
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Nengi Adoki ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Kìíní ọdún 1990 sí ìlú Port-Harcourt, ní Ìpínlẹ̀ Rivers.[4][5] Ó dàgbà sí ìlúToronto, Canada tí ó sì gbà oyè B.A. nínú ìmọ̀ Performing Arts and Information Technology láti University of Toronto ní ọdún 2013. Nígbà tí ó wà ní University of Toronto, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùdarí eré orí-ìtàgé, bẹ́ẹ̀ sì ni ó kópa nínú àwọn eré bí i Sync Afrique, èyí tí wọ́n ṣe ní Mississauga ní ọdọọdún láti ọdún 2009 wọ ọdún 2014.[6][4][7] Adoki gba àmì-ẹ̀yẹ African Scholars' Global Impact Award láti University of Toronto ní ọdún 2019.[8] Ní ọdún 2014, ó gba ìwé-ẹ̀rí nínú ẹ̀kọ́ performing arts láti Sheridan College ní Oakville, Ontario.[5]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Léyìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Sheridan College, Adoki padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ eré ṣíṣe rẹ̀.[9] Eré rẹ̀ àkọ́kọ́ ní orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán ni Lost Girl.[9] Ní ọdún 2016, ó ṣàfihàn nínú fíìmù Bolanle Austen-Peter, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Wakaa! The Musical, tí wọ́n ṣàfihàn ní West End, ní ìlú London.[10] Ní ọdún 2018, ó kópa nínú fíìmù orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Forbidden.[11] Bákan náà ni ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erẹ́ orí-ìtàgé bí i Heartbeat the Musical àti No More Lies.[12][13]
Ní ọdún 2021, Adoki ṣe àgbéjáde fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀, èyí tí C.J. Obasi, Abba Makama, àti Michael Omunua jẹ́ olùdarí fún.[14][15] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ní Future Awards Africa ní ọdún 2022 fún iṣẹ́ náà.[16][17][18] Bákan náà ni ó ti farahàn lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà nínú fíìmù orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán bí i Back to School, The Men's Club, Inspector K, àti Baby Drama.[19][20][21] Adoki bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àwọn fíìmù apanilérìn-ín, lára wọn ni The Most Toasted Girl ní ọdún 2018, èyí tí wọ́n ṣe àfihàn àkọ́kọ́ fún ní ọdún 2020.[22][23] Eré náà dá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi tí ó ń ṣẹ̀ ní Èkó.[24]
Ní ọdún 2022, Adoki jẹ́ olú ẹ̀dá-ìtàn nínú fíìmù Chike Ibekwe, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Chatroom, ó sì tún farahàn nínú apá kejì fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Little Black Book.[25][26][27][28] Bẹ́ẹ̀ sì ni ó kópa nínú fíìmù ọdún 2023 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Trade.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Nwogu, Precious 'Mamazeus' (19 January 2022). "Top Nollywood actors of the year [Pulse Picks 2021]". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 6 August 2022. Retrieved 6 August 2022.
- ↑ "We live in society where women are scrutinized ― Nengi Adoki". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 10 May 2021. Retrieved 6 August 2022.
- ↑ Famuyiwa, Damilare (18 November 2020). "What The Men's Club has Done for Me -Nengi Adoki". eelive (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 August 2022.
- ↑ 4.0 4.1 "Get to Know Nigerian-born, Toronto Actress, Nengi Adoki". The K Scope. 21 January 2017. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ 5.0 5.1 "KOKO's Top 7 Fast-Rising Actresses to Watch Out For In Nigeria 2022". KOKO TV. 27 August 2022. Archived from the original on 18 April 2023. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ "Sync Afrique 2013 - Wakati". Too Xclusive. 15 December 2022. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ admin (27 April 2022). "SUPER ACTRESS NENGI ADOKI STARS IN THE MOVIE 'CHATROOM' – Supple Magazine" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 August 2022.
- ↑ King, Perry (10 October 2019). "Awards ceremony celebrates U of T's African scholars, community leaders". University of Toronto. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ 9.0 9.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:12
- ↑ "Wakaa the Musical to be Staged in London's West End | 21st to 25th July". BellaNaija. 18 May 2016. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ "Get the Scoop on New Series 'Forbidden' Starring Thelma Edem-Isemin, Kunle Remi, Toni Tones, Tina Mba & Nobert Young". BellaNaija. 27 June 2018. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ "Ashionye, Evaezi, others hit the stage for 'No More Lies'". The Nation. 20 July 2017. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ Adeyemo, Ifeoluwa (20 April 2021). "Bimbo Akintola, Joseph Benjamin, Bikiya Graham-Douglas, Wole Ojo and More | Meet the Cast of Africa Magic's new series, Baby Drama!". Nigerian Entertainment Today. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ "6 Questions with Nengi Adoki: Playing Joy in 'Juju Stories', Collaborative Process with Director Obasi and Teases New Episodes of 'The Most Toasted Girl'". What Kept Me Up. 27 January 2023. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ "MOVIE REVIEW: 'Juju Stories' and the magic of an anthology". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 9 April 2022. Retrieved 6 August 2022.
- ↑ "Tems, Bimbo Ademoye win Future Awards: The Full List - P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 August 2022.
- ↑ Otubu, Anjola-Oluwa (21 February 2022). "List of winners at The Future Awards Africa 2022". eelive (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 August 2022.
- ↑ "Full list: Tems, Bimbo Ademoye win at The Future Awards Africa 2022". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 20 February 2022. Retrieved 6 August 2022.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:13
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:02
- ↑ Adeyemo, Ifeoluwa (20 April 2021). "Bimbo Akintola, Joseph Benjamin, Bikiya Graham-Douglas, Wole Ojo And More | Meet The Cast of Africa Magic's new series, Baby Drama!". Nigerian Entertainment Today (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 6 August 2022.
- ↑ "'The Most Toasted Girl', A New Web Series Coming Your Way". Exquisite Mag. 23 September 2020. Retrieved 23 September 2023.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:42
- ↑ Ofoma, Dika (30 April 2022). "Nengi Adoki on Becoming Joy, the Witch, in Juju Stories". Dika Thinks. Retrieved 23 September 2023.
- ↑ Stephen, Onu (25 April 2022). "New contemporary movie, CHATROOM, premieres in Lagos". Premium Times. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ Nwogu, Precious (22 July 2022). "Little Black Book: TNC Africa debuts season 2 trailer". Pulse.ng. Retrieved 28 September 2023.
- ↑ "Award winning actors star in Chatroom". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 27 March 2022. Retrieved 6 August 2022.
- ↑ "Omawumi, Tony Umez, others star in Chatroom". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 3 April 2022. Retrieved 6 August 2022.