Jump to content

Netumbo Nandi-Ndaitwah

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Netumbo Nandi-Ndaitwah

Nandi-Ndaitwah in 2022
President-elect of Namibia
Taking office
21 March 2025
SucceedingNangolo Mbumba
3rd Vice President of Namibia
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
4 February 2024
ÀàrẹNangolo Mbumba
AsíwájúNangolo Mbumba
Deputy-Prime Minister of Namibia
In office
21 March 2015 – 4 February 2024
Alákóso ÀgbàSaara Kuugongelwa
AsíwájúMarco Hausiku
Arọ́pòJohn Mutorwa
Minister of International Relations and Cooperation
In office
4 December 2012 – 4 February 2024
Alákóso Àgbà
AsíwájúUtoni Nujoma
Arọ́pòPeya Mushelenga
Minister of Environment and Tourism
In office
21 March 2010 – 4 December 2012
Alákóso ÀgbàNahas Angula
AsíwájúWillem Konjore
Arọ́pòUahekua Herunga
Minister of Information and Broadcasting
In office
2005–2010
Alákóso ÀgbàNahas Angula
AsíwájúNangolo Mbumba
Arọ́pòJoel Kaapanda
Minister of Women Affairs and Child Welfare
In office
2000–2005
Alákóso ÀgbàHage Geingob
Asíwájúposition established
Arọ́pòMarlene Mungunda
Director General of Women Affairs
In office
1996–2000
Alákóso ÀgbàHage Geingob
Deputy Minister of Foreign Affairs
In office
21 March 1990 – 21 March 1996
Alákóso ÀgbàHage Geingob
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Netumbo Nandi

29 Oṣù Kẹ̀wá 1952 (1952-10-29) (ọmọ ọdún 72)
Onamutai, South West Africa (now Namibia)
Ọmọorílẹ̀-èdèNamibian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúSWAPO
(Àwọn) olólùfẹ́Epaphras Denga Ndaitwah
Alma materKeele University
Glasgow Caledonian University
OccupationPolitician

Ndemupelila Netumbo Nandi-Ndaitwah (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá ọdún 1952), tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ jẹ́ NNN,[1][2] jẹ́ olóṣèlú orílẹ̀-èdè Namibia, tí ó di Ààrẹ orílẹ̀-èdè Namibia lẹ́yìn tí ó gbégbá orókè nínú ìdìbò tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ kẹta oṣu Kejìlá ọdún 2024.[3] Nípa èyí, ó di Ààrẹ ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún ti Namibia àti obìnrin àkọ́kọ́ tó máa gorí oyè náà. Láti oṣù kejì ọdún 2024 ni ó ti wa ní ipò Igbá-kejì Ààrẹ Namibia. Òun náà ni Ààrẹ-bìnrin àkọ́kọ́ tí ẹgbẹ́ òṣèlú SWAPO máa ni, bí ó ṣe jẹ́ pé òun ni olùdíje ti ẹgbẹ́ náà yàn kalẹ̀ fún ètò ìdìbò ti ọdún 2024. Ní ọdún 2017, ẹgbẹ́ òṣèlú SWAPO yan Nandi-Ndaitwah gẹ́gẹ́ bí i igbá-kejì Ààrẹ SWAPO, èyí sì mu kó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tó máa wà ní ipò náà.

Nandi-Ndaitwah ti fìgbà kan jé igbá-kejì Prime minister ti Namibia láti ọdún 2015 wọ ọdún 2024, minister of International Relations and Cooperation láti oṣù Kejìlá ọdún 2012 wọ ọdún 2015, àti gẹ́gẹ́ bí i minister of Environment and Tourism láti oṣù Kẹta ọdún 2010 wọ oṣù Kejìlá ọdún 2012. Ó ti jẹ́ ọmọ-ẹgbé National Assembly ti Namibia tipẹ́ tipẹ́.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Netumbo Nandi ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá ọdún 1952 sínú ìdílé Justina Nekoto Shaduka-Nandi àti Petrus Nandi ní Onamutai, South West Africa (èyí tó wà ní agbègbè Oshana, ní Namibia lónìí).[4] Bàbá rẹ̀ jé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ní ìjọ Àgùdà. Ó jẹ́ ọmọ kẹsàn-án láàárín àwọn ọmọ mẹ́tàlá ti àwọn òbí rẹ̀ bí.[5] Ndaitwah kàwé ní St. Mary's Mission ní Odibo.[6]

Nandi-Ndaitwah lọ sí ẹ̀yìn odi ní ọdún 1974, ó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ SWAPO ní orílẹ̀-èdè Zambia. Ó ṣiṣẹ́ ní olú ilé-iṣẹ́ SWAPO ní Lusaka, láti ọdún 1974 wọ ọdún 1975, ó sì lọ sí Lenin Higher Komsomol School ní Soviet Union láti ọdún 1975 wọ 1976. Ó gba oyè diploma níbẹ̀. Ní ọdún 1987, ó gba oyẹ̀ post-graduate diploma nínú ìmọ̀ public administration and management láti Glasgow College of Technology, ní United Kingdom, ní ọdún 1988 ó tẹ̀ síwájú láti gba oyè post-graduate diploma, nínú ìmọ̀ international relations, ní Keele University, àti ní UK bákan náà. Ní ọdún 1989, Nandi-Ndaitwah gboyè master's degree láti Keele University.[7]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olóṣèlú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nandi-Ndaitwah di aṣojú ẹgbẹ́ SWAPO ní Zambia láti ọdún 1976 títí wọ ọdún 1978 àti aṣojú àgbà ní Zambia láti ọdún 1978 wọ ọdún 1980. Láti ọdún 1980 wọ 1986, òun ni aṣojú àgbà SWAPO ní apá Ìlà-Oòrùn ilẹ̀ Africa, èyí tí ó wà ní Dar es Salaam. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ SWAPO láti ọdún 1976 wọ ọdún 1986 àti Ààrẹ Namibian National Women's Organisation (NANAWO) láti ọdún 1991 wọ ọdún 1994.[8]

Láti ọdún 1990 ni ó ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ National Assembly of Namibia. Ó fìgbà kan jẹ́ igbá-kejì Minister of International Relations and Cooperation láti ọdún 1990 wọ 1996. Ọdún 1996 sì ni ó gba oyè Mínísítà, gẹ́gẹ́ bí i director-general of Women's Affairs ní ọ́fíìsì Ààrẹ, níbí ti ó ti ṣiṣẹ́ títí wọ ọdún 2000. Ní ọdún 2000, ó gba ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ láti di Mínísítà, wọ́n sì fún un ní ojúṣe láti ṣàkóso ẹ̀ka Women Affairs and Child Welfare.[9]

Netumbo Nandi-Ndaitwah ní ọdún 2015

Láti ọdún 2005 wọ ọdún 2010, òun ni minister of information and broadcasting ní ẹ̀ka Namibia. Lẹ́yìn náà ni ó wà ní ipò minister of environment and tourism títí wọ oṣù Kejìlá ọdún 2012, tí wọ́n yàn án sí ipò minister of foreign affairs.[10]

Lábẹ́ ìdarí Ààrẹ Hage Geingob, wọ́n yan Nandi-Ndaitwah gẹ́gẹ́ bí i igbá-kejì prime minister ní oṣù Kẹta ọdún 2015, lásìkò kan náà tí ó jẹ́ minister of international relations and cooperation.[11] Nandi-Ndaitwah ti fìgbà kan wà ní ipò ìgbìmọ̀ SWAPO àti Politburo. Òun náà ni akọ̀wé ẹgbẹ́ òṣèlú náà fún information and mobilisation, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ agbẹnusọ wọn.[12][13]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Mumbuu, Edward (November 16, 2022). "SWAPO Braces for Vote Showdown". New Era Live. https://neweralive.na/swapo-braces-for-vote-showdown-camps-brimming-with-confidence-as-congress-nears/. 
  2. "Naimibia Elects Its First Woman President". CBS News. December 4, 2024. https://www.cbs19news.com/namibia-elects-its-first-woman-president/article_f90dcde1-0ac9-520b-9f0a-27e240975025.html. 
  3. "Namibia will have its first female leader after the VP wins presidential election for ruling party". KTALnews.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2024-12-03. Retrieved 2024-12-03. 
  4. "Nandi-Ndaitwah's moment of truth" (in en-ZA). The Namibian. 14 April 2022. https://www.namibian.com.na/nandi-ndaitwahs-moment-of-truth/. 
  5. Mongudhi, Tileni (2023-04-21). "Nandi-Ndaitwah's moment of truth". The Namibian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 7 October 2024. Retrieved 2024-11-25.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. Dierks, Klaus. "Biographies of Namibian Personalities, N". klausdierks.com. Archived from the original on 20 September 2023. Retrieved 11 June 2022.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. Hopwood, Graham. "Who's Who, entry for Netumbo Nandi-Ndaitwah". Namibia Institute for Democracy. Archived from the original on 11 June 2011. Retrieved 8 January 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named NID2
  9. "Nandi-Ndaitwah Netumbo". Parliament of Namibia. Retrieved 11 June 2022. 
  10. Shipanga, Selma; Immanuel, Shinovene (5 December 2012). "Transition team picked". The Namibian. http://www.namibian.com.na/indexx.php?archive_id=103168&page_type=archive_story_detail&page=525. 
  11. "Geingob announces Cabinet". The Namibian. 20 March 2015. https://www.namibian.com.na/index.php?id=134889&page=archive-read. 
  12. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named NID3
  13. "Nandi-Ndaitwah Netumbo". Namibian Parliament (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-02-13.