Nguyễn Chánh Thi
{{subst:afd|help=off}}
Nguyễn Chánh Thi (Ọjọ́ kẹtàlélódún Oṣù kejì ọdún 1923 – Ọjọ́ kẹtàlélódún Oṣù kẹfà ọdún 2007) jẹ́ ológun ilẹ̀ Vitenam (ARVN).[1] Wọ́n mọ̀ọ́ sí àwọn ipa tí ó kó nínu fifipá gba ìjọba ní bí 1960 tí ó sì wà lára àwọn ológun tí o ṣe ìjọba Gúúsù Vietnam láti ọdún 1964 sí 1966, tí ó sì jẹ́ wípé nígbà tí ọ̀gá ológún òfúrufú ti ilẹ̀ Vietnam àti alákóso tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nguyễn Cao Kỳ borí rẹ̀, ó kọjá sí Àmẹ́ríkà. Wọ́n mọ̀ọ́ sí àwọn ìwà àìbìkítà tí kò ń fẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ U.S, àwọn olórí ẹgbẹ́ ní Amẹ́ríkà sì fi ọwọ́ sí bí wọ́ ṣe yọ Thi lóyẹ̀. Thi darapọ̀ mọ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Faransé nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ti àwọn Japan sì kóo mógun lọ nígbà tí wọ́n dojú ogun kọ French Indochina nígbà ogun àgbáyé kejì. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, ó na pápá bora. Ó padà darapọ̀ mọ́ ológun Vietnam tí Faransé tí State of Vietnam ń ṣalábò fún, èyí, ní oṣù kẹwá ọdún 1955, di ARVN àti Republic of Vietnam (Gúúsù Vietnam). Ó jà fún alákóso ìgbà yẹn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ngô Đình Diệm nígbà 1955 Battle for Saigon. Thi mú orí Diệm wú tí ó sì jẹ́ kí ó maa pèé ní “ọmọ mi” tí ó sì sọ ọ́ di apàṣẹ Airborne Brigade.
Ní ọdún 1960, Thi ṣíwájú ìfipá gba ìjọ́ba lọ́wọ́ Diệm, ń sọ wípé ológun dásí òṣèlú. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí borí ṣùgbọ́n Thi kò fi taratara fẹ́ borí ogun náà tí ó sì fa ìdíwọ́ fún ìfipá gba ìjọ́ba náà, lẹ́yìn tí Diệm fi ẹ̀tàn ṣèlérí lati ṣe àtúnṣe láti fi àkókò ṣòfò kí àwọn ènìyàn tiẹ̀ lè gbàá sílẹ̀. Thi sá kúrò ní ìlú lọ sí Cambodia, ṣùgbọ́n, ó padàwà lẹ́yìn tí wọ́n yọ Diệm tí wọ́n sì paá ní oṣù kọkànlá ọdún 1963.[2] Ó di igbákejì apàṣẹ ti I Corps lábẹ́ Nguyễn Khánh, tí ó sì bá ọ̀gá rẹ̀ gbàjọba lẹ́yìn oṣù mẹ́ta. Thi di apàṣẹ 1st Division, kí ó tó di alákóso I Corps lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ lọ́dún náà.[3]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Sullivan, Patricia (2007-06-27). "South Vietnamese Gen. Nguyen Chanh Thi". Washington Post. Retrieved 2009-10-11.
- ↑ Blair, p. 70.
- ↑ Shaplen, p. 230.