Niyi Osundare
Niyi Osundare |
---|
Niyi Osundare (bí ni ọjọ́ kejìlá, Oṣù Ẹ̀rẹnà, Ọdún 1947) jẹ́ onímọ̀ èdè, akéwì, onísẹ́ lámèyítọ́ àti eléré onísẹ́ ọmọ Orílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Ìbẹ̀rẹ̀ Pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nìyí Ọ̀sundare jẹ́ aṣáájú akéwì nílẹ̀ Adúláwọ̀, eléré-onísẹ́, onímọ̀ èdè àti onísẹ́ lámèyítọ́. Ìlú Ìkẹ́rẹ́ Èkìtì ní apá ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà ni wọ́n ti bí i ni ọjọ́ kejìlá, Oṣù Ẹ̀rẹnà, Ọdún 1947. Òrìṣà tó ò gún ewì rẹ̀ ni ewì alohùn nínú àṣà Yorùbá rẹ̀, èyí ló jẹ́ kí ìwọ̀nùbọ̀nú wà nínú iṣẹ́ rẹ̀ àti àṣà ewì àgbáyé yòókù, lára wọn ni Ilẹ̀ Adúláwọ̀, Amẹ́ríkà, Amẹ́ríkà - Látìnì, Éyísà àti Yúróòpù. Ó táko ìdúnmokò mọ́ ọ̀rọ̀ sísọ bákan náà àwọn iṣẹ́ àtinúdá àti àròjinlẹ̀ ni ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ìjàǹgbara òṣèlú, òmìnira àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn Adúláwọ̀ àti agbègbè. Ó ti gba ọ́pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ lára wọn ni àmì-ẹ̀yẹ ewì Ẹgbẹ́ àwọn Òǹkọ̀wé Orílẹ̀èdè Nàìjíríà (Association of Nigerian Authors - ANA), Àmì - Ẹyẹ Ewì Commonwealth, Àmì ẹ̀yẹ ewì Tchicaya U Tam'si àti àmì ẹ̀yẹ ewì ANA tòun ti iléeṣẹ́ Cadbury lẹ́ẹ̀mejì. Ní ọdún 1991, Ọ̀sundare di akéwì Adúláwọ̀ onígẹ̀ẹ́sì àkọ́kọ́ láti gba àmì ẹ̀yẹ NOMA, bákan náà ló gba àmì ẹ̀yẹ Fonlon Nichols fún iṣẹ́ takuntakun àti ipa ribiribi rẹ̀ sí ìjàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ní ilẹ̀ Áfíríkà. Ní ọdún 2014, wọ́n gbà á wọlé sí National Order of Merit tíì ṣe ẹ̀yẹ tó ga jù ní Orílẹ̀èdè rẹ̀ fún ìmọ̀ tó tayọ àti ìseyorí àtinúdá. Ọ̀jọ̀gbọ́n afẹ̀yìntì tí ó tayọ ní Ọ̀sundare ní Yunifásítì ti Ìlú New Orleans
Ebí àti Èkó
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ẹbí àti Èkọ́:Ọ̀sundare gba oyè ẹ̀kọ́ BA. nínú Èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Yunifásítì ti Ìlú Ìbàdàn, Oyè MA ni Yunifasiti Ìlú Leeds and Oyè Ph.D ní Yunifásítì ìlú Canada. Ó jẹ olórí ẹ̀ka Gẹ̀ẹ́sì ní Yunifásítì ti Ìbàdàn ní ọdún 1993 sí 1997. Ó di Ọ̀jọ̀gbọ́n Èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Yunifásítì New Orleans ní ọdún 1997. Ọsundare ní ìyàwó àti ọmọ mẹ́ta tí wọ́n ṣì ń gbè ni Orílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Àwọn àmì ẹ̀yẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]First Prize, Western State of Nigeria Poetry Competition (1968)[11]
1981 Major Book Prize and Letter of Commendation, BBC Poetry Competition (1981)[12]
Honorable Mention, Noma Award for Publishing in Africa (1986)[13]
Honorable Mention, Noma Award for Publishing in Africa (1989)[14]
Association of Nigerian Authors (ANA) Poetry Prize (1986)[citation needed]
Joint-Winner, Overall Commonwealth Poetry Prize (1986)[15]
Kwanza Award (1991)[16]
Noma Award for Publishing in Africa (the first Anglophone African poet to receive the award) (1991)[17]
Cadbury/ANA Poetry Prize (Nigeria’s highest poetry prize). Also won the maiden edition in 1989 (1994)[18]
Fonlon/Nichols Prize for "Excellence in Literary Creativity Combined with Significant Contributions to Human Rights in Africa"; African Literature Association (ALA)’s most distinguished award) (1998)[19]
The Spectrum Books Award to The Eye of the Earth as “One of Nigeria’s Best 25 Books in the Last 25 Years” (2004)[20]
The Tchicaya U Tam'si Prize for African Poetry (regarded as Africa's highest poetry prize) (2008)[21][22]
Nigerian National Order of Merit Award (Nigeria's highest award for academic excellence) (2014)[23][24]
Àkójọ pò isẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Songs from the Marketplace (1983)-
Village Voices (1984)-
The Eye of the Earth (1986, winner of a Commonwealth Poetry Prize and the poetry prize of the Association of Nigerian Authors)-[25]
Moonsongs (1988)-
Songs of the Season (1999)-
Waiting Laughters (1990, winner of the Noma Award)-[26]
Selected Poems (1992)-
Midlife (1993)-
Thread in the Loom: Essays on African Literature and Culture (2002)-
The Word is an Egg (2002)-
The State Visit (2002, play)-
Pages from the Book of the Sun: New and Selected Poems (2002)-
Early Birds (2004)-
Two Plays (2005)-
The Emerging Perspectives on Niyi Osundare (2003)-
Not My Business (2005)-
Tender Moments:Love Poems (2006)-
City Without People: The Katrina Poems (2011)-
Random Blues (2011)-
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- "Niyi Osundare becomes first African Cover Poet for World Poetry magazine"
- "Nigeriaworld Feature Article - Letter to President Obasanjo" https://nigeriaworld.com/articles/2003/jul/072.html Archived 2022-08-30 at the Wayback Machine.
- "Merit award won't silence me as critic, says Osundare" http://www.ngrguardiannews.com/news/national-news/191915-merit-award-won-t-silence-me-as-critic-says-osundare
- https://en.m.wikipedia.org/wiki/Niyi_Osundare#cite_ref-2