Noimot Salako-Oyedele

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Noimot Salako-Oyedele
Igbá kejì Gómìnà ìpìnlẹ̀ Ògùn
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
29 May 2019
AsíwájúYetunde Onanuga
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí{{ Ọjọ Ìbí àti ọjọ orí, Ọjọ kẹjọ, osù kínní {Seere}, Ọdún 1966.}}
Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressives Congress
(Àwọn) olólùfẹ́Alhaji Bode Oyedele
ProfessionReal Estate Consultant

Nòímòt Sàlàkó -Oyèdélé, jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ, olósèlú, onímọ̀ nípa ohun ìní, omo bíbí orílẹ̀ èdè Nàíjírìa ti a bí ní ọdún 1967,bàbá rẹ̀ Lateef A. Salako NNOM, CON jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ àwọn òògùn àti Olùkọ́ ni fásitì ilẹ̀ Ìbàdàn. Ó jẹ́ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, orílẹ̀ èdè Nàijiria. Ó di igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn lẹ́hìn tí ó borí pẹ̀lú Dàpọ̀ Abíọdún, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, ní ọdún 2019 nínú ìdìbò gómìnà fún ìpínlẹ̀ Ògùn, lábẹ́ àsìá All Progressive Congress (APC) sáájú Yétúndé Ọnànúgà, igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ náà tẹ́lẹ̀.

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí Ayé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Onímọ̀-ẹ̀rọ Nọ́ìmọ́t Sàlàkọ́-Oyèdélé ní ọjọ́ kẹjọ, Osù Kínní, ọdún 1967 sínú ẹbí olóògbé Ọ̀jọ̀gbọ́n Lateef àti Ìyáàfin Rahmat Adebísí Sàlàkọ́. Aràbìnrin náà jẹ́ ọmọ bíbí Ilẹ̀ Àwórì, Ọ̀tà ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Adó - Odò/Ọ̀tà nì Ìpìnlẹ̀ Ògùn.

Ẹ̀kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ońimọ̀- ẹ̀rọ Noimot gba oyé ìmọ ìjìnlẹ̀ nínú Isẹ́ -ìlera láti Kọ́lẹ́ẹ́jì Sáyẹ̀nsì àti Ìmọ̀-ẹ̀rọ ti Imperial ní London, UK, bẹ́ẹ̀ni ó ní ìmọ̀ oyè ti Sáyẹ̀nsì abáni Kọ́lẹ́.

Iṣẹ́ ìṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Onímọ̀-ẹ̀rọ Noimot Sàlàkọ-Oyèdélé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní United Kingdom, níbi tí ó ti siṣẹ́ gẹ́gẹ́bí Onímọ̀-`èrọ kàwégboyè àti olùdárí Iṣẹ́ àkànse ní Ove Aruo & Partners láàrin 1989 sí 1995. Bákanná Ó siṣẹ́ gẹ́gẹ́bí Ògá àgbà ní NOS Nigeria Limited láàrin 1995-2014. Ó di Olùdárí àti Alákoso ní Glenwood Property Development Company láàrin 2014-2015 níbi tí ó tí siṣẹ́ gẹ́gẹ́bí Alákoso Ìdàgbásókè Ìsòwò gbogbogbò. Arábìnrin náà di Adelé Olùdárí Ògá àgbà ti Grenadines Homes Limited ńi ọdún 2015, ipò tí ó dìmú títí ó fi bèrè òsèlú, tí ó sì wọlé gẹ́gẹ́bí igbákejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn.

Òsèlú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní osù kẹta,ọdún 2019, àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ògùn dìbò yàn án gẹ́gẹ́bí igbákejì Gómìnà Ọlọ́lájùlọ Ọmọba Dàpọ̀ Abíọ́dún.