Nse Ikpe-Etim
Nse Ikpe-Etim | |
---|---|
Nse ni ọdún 2016 | |
Ọjọ́ìbí | 21 Oṣù Kẹ̀wá 1974 Lagos, Lagos State, Nigeria |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | òṣèré |
Olólùfẹ́ | Clifford Sule (m. 2013) |
Website | Nseikpeetim.com |
Nse Ikpe-Etim (tí a bí ní ọdún 1974) jẹ́ òṣèré ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà. Òkìkí rẹ̀ kàn ní ọdún 2008 fún ipa rẹ̀ nínú Reloaded. Wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ Dirama Òṣèrébìrin tó dára jù fún ẹ̀dá-ìtàn "Nse" nínú "Journey to Self ní Africa Viewers Awards lọ́dún 2014.
Ibẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbé-ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Etim ní ọjọ́ kọkànlélógún, Oṣù Ọ̀wàrà, Ọdún 1974 ní ìlú Èkó. Etim lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ Awa àti Ilé ẹ̀kọ́ àwọn ológun (Command Primary School) ní ìlú Kaduna, ó tẹ̀síwájú ní St Louis College, Jos àti Kọ́lẹ́jì Ìjọba Àpapọ̀ ní ìlú Jos àti Ìlọrin. Ó sọ pé iṣẹ́ bàbá rẹ̀ bí òṣìṣẹ́ Báànkì àpapọ̀ ló fa gbígbé tí àwọn ń gbé kiri gbogbo àgbègbè. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ tíátà ní Yunifásítì Calabar. [1][2][3] [4] [5]
Ìgbésí ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Etim ní àkọ́bí nínú àwọn mẹ́fà. Ó sọ pé ohun ni àwọn alágbàtọ́ tí wọ́n jẹ́ òyìnbó nínú Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ Toolz. Ọjọ́ kẹrìnlá ọdún 2013 ló fẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ Clifford Sule ní ìlànà ìgbéyàwó-òfin ní Èkó. Lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó Ìbílẹ̀ ní ìlú rẹ̀ Akwa Ibom àti Èkó. Ìlú Ọba (London) ló ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ báyìí , tí ó jẹ olùkọ́ni àgbà ní Iléẹ̀kọ́ Yunifásítì Middlesex tí ó sì má ń wà ṣiṣé fíìmù ní Nàìjíríà[6] [7] [8] [9] [10]
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Etim bẹ̀rẹ̀ eré orí ìtàgé ní ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì ní ọmọ ọdún méjìdínlógún. Eré àkọ́kọ́ tí ó ti kọ́kọ́ hàn ni eré àtìgbàdégbà "Inheritance". Nígbà tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Yunifásítì, ó kúrò ní agbo fíìmù ráńpẹ́ láti dáwọ́lé àwọn ohun mìíràn kí ó tó wà kópa nínú fíìmù Reloaded tí Emem Isong ṣe, àwọn òṣèré tí wọ́n jọ kópa ni Ramsey Nouah, Rita Dominic, Ini Edo àti Desmond Eliot. Ní oṣù Ọ̀pẹ, ọdún 2019, wọ́n ṣe àfihàn rẹ̀ nínú àkójọ àwòrán Collaborative Polaris, lábẹ́ Ìfọmọnìyànṣe Supernova, wọ́n ṣe Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún pẹ̀lú àwọn èèyàn bíi William Coupon, Bisila Bokoko àti Adé Adékọ́lá.
Ní ọdún 2020 ó kópa nínú eré Quam's money tí ó sòpọ̀ mọ́ eré Tope Oshin, New money.
Ní ọdún 2021, ó kópa pẹ̀lú Richard Mofe-Damijo àti Zainab Balógun nínú eré Ṣèyí Bàbátọ́pẹ́ tí ò pè ní Wine.[11][12] [13][14] [15]
Àkójọ Fíìmù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Odun | Fiimu | Ipa | Awọn akọsilẹ |
---|---|---|---|
2003 | Emotional crack | Olupese Olupilẹṣẹ | |
Venom of Justice 2 | |||
2008 | Reloaded | pẹlu Ramsey Nouah, Desmond Elliot Rita Dominic, Ini Edo, Uche Jombo & Stephanie Okereke </br> Ti yan fun Oṣere ti o dara julọ ni ipo idari ni 5th African Movie Academy Awards | |
Ọdun 2010 | Bursting Out | pẹlu Genevieve Nnaji, Susan Peters & Majid Michel | |
Inale | Ori | pẹlu Caroline Chikezie, Hakeem Kae-Kazim & Ini Edo | |
2011 | Inale | pẹlu Ramsey Noah, Majid Michel, Stephanie Okereke & Desmond Elliot | |
Memories of My Heart | pẹlu Ramsey Noah, Ini Edo, Uche Jombo & Monalisa Chinda | ||
Kiss and Tell | Tena | pẹlu Joseph Benjamin, Desmond Elliot, Uche Jombo & Monalisa Chinda | |
Spellbound | Mary | pẹlu Joseph Benjamin, Desmond Elliot, Uche Jombo & Chioma Chukwuka | |
2012 | Phone Swap | Mary | pelu Wale Ojo, Joke Silva & Lydia Forson |
Mr. and Mrs. | Susan Abbah | pẹlu Joseph Benjamin & Barbara Soky | |
The Meeting | Bolarinwa | pẹlu Rita Dominic, Femi Jacobs, Kate Henshaw, Jide Kosoko & Chinedu Ikedieze | |
Journey to Self | Nse | pelu Dakore Akande & Chris Attoh | |
Black November | Amofin | pẹlu Mickey Rourke, Vivica Fox, Hakeem Kae-Kazim & Kim Basinger | |
Ọdun 2013 | Broken | Mariam Idoko | pẹlu Kalu Ikeagwu & Bimbo Manuel |
Blue Flames | pelu Omoni Oboli & Kalu Ikeagwu | ||
Hustlers | pelu Chelsea Eze & Clarion Chukwura | ||
Ọdun 2014 | Devil in the Detail | Helen Ofori | pẹlu Adjetey Anang |
The Green Eyed [16] | pelu Kalu Ikeagwu ati Tamara Eteimo | ||
Tunnel | pelu Femi Jacobs ati Waje | ||
In Between [17] [18] | pẹlu Pascal Amanfo | ||
2015 | The Visit | Ajiri Shagaya | pẹlu Blossom Chukwujekwu, ati Femi Jacobs |
Heaven's Hell | Alice Henshaw | pelu Bimbo Akintola, OC Ukeje ati Damilola Adegbite | |
Fifty | Kate | pelu Ireti Doyle, Omoni Oboli ati Dakore Akande | |
2016 | Stalker | Kaylah | pẹlu Jim Iyke, ati Caroline Danjuma |
A Trip to Jamaica | pelu Ayo Makun, Funke Akindele | ||
2017 | American Driver | Nse Ikpe-Etim | pẹlu Evan King, Jim Iyke, Anita Chris, Nse Ikpe Etim, Nadia Buari, Emma Nyra, Ayo Makun, Laura Heuston, McPc the Comedian, Michael Tula, Andie Raven |
Àwọn Àmì Ẹ̀yẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Awọn itọkasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2020-08-22. Retrieved 2020-10-07.
- ↑ http://www.gistmania.com/talk/topic,117626.0.html
- ↑ http://www.gistmania.com/talk/topic,117626.0.html
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2020-10-07.
- ↑ http://www.dailytimes.com.ng/article/2012-zafaa-nominees-announced
- ↑ https://www.youtube.com/watch?v=B6x86m9msG4
- ↑ http://www.bellanaija.com/2013/02/18/bn-exclusive-nse-ikpe-etim-is-now-mrs-clifford-sule-photos-from-their-civil-ceremonywedding-celebratory-dinner/
- ↑ http://www.nigeriafilms.com/news/20619/8/nse-ikpe-etims-hubbys-15-year-old-son-jermaine-sul.html
- ↑ http://www.gistus.com/23593/nse-ikpe-etims-traditional-wedding-hold-april-4th
- ↑ http://www.gistus.com/21899/ms-nse-ikpe-etim-clifford-sule
- ↑ http://www.bellanaija.com/2009/10/22/nse-ikpe-etim-%E2%80%93-an-interview-with-nollywood%E2%80%99s-it-girl-by-bola-aduwo/
- ↑ http://www.bellanaija.com/2012/11/07/the-2012-exquisite-lady-of-the-year-eloy-awards-ty-bello-omotola-jalade-ekeinde-toolz-ini-edo-tiwa-savage-chimamanda-ngozi-adichie-other-powerful-women-make-the-nominees-list/
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2014-02-27. Retrieved 2020-10-07.
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2021-10-30. Retrieved 2020-10-07.
- ↑ "Here's a first-look at Dimeji Ajibola's forthcoming crime thriller 'Shanty Town'". Pulse Nigeria. 2021-05-13. Retrieved 2021-07-04.
- ↑ https://web.archive.org/web/20140316215756/http://www.nollywooduncut.com/movies-coming-soon/430-nse-ikpe-etim-kalu-ikeagwu-blossom-chukwujekwu-the-green-eyed
- ↑ https://web.archive.org/web/20140910195733/http://blog.irokotv.com/2014/05/nse-ikpe-etim-gives-up-her-life-in.html
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2020-10-11. Retrieved 2020-10-07.