Jump to content

Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Obafemi Awolowo)
Obafemi Awolowo
Olórí Agbègbè Apáìwọ̀òrùn Nàìjíríà
In office
Ọjọ́ kínín Oṣù kẹwá ọdún 1954 – Ọjọ́ kínín Oṣù kẹwá ọdún 1960
Arọ́pòSamuel Akintola
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíỌjọ́ kẹfà oṣù kẹta ọdún1909
Ikenne, Ipinle Ogun
AláìsíMay 9, 1987(1987-05-09) (ọmọ ọdún 77)
Ikenne
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAction Group
ProfessionAmòfin, Olóṣèlú

Jeremiah Obáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tí a bí ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹta (Ẹrẹ́nà) ọdún 1909, ti o sí ku lọjọ́ kẹ́sàn-án oṣù karùn-ún (Èbìbí) ọdún 1987, jẹ́ olósèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ẹ̀yà Yorùbá. Awólọ́wọ̀ jẹ́ olórí fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Yorùbá àti ọ̀kan nínú àwọn olóṣèlú pàtàkì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1][2][3]

Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀

A bí i ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹta ọdún 1909 ní Ìkẹ́nnẹ́ tó wà ní ìpínlẹ̀ Ògùn lónìí. Ọmọ àgbẹ̀ tí ó fi iṣẹ́ àti oògùn ìṣẹ́ sọ ara rẹ̀ di ọ̀mọ̀wé, Awólọ́wọ̀ lọ ilé ẹ̀kọ́ Anglican àti Methodist ní Ìkẹ́nnẹ́ àti sí Baptist Boys' High School ní Abẹ́òkúta.[4] Lẹ́yìn rẹ̀ ó lọ sí Wesley College ní Ìbàdàn tí ó fi ìgbà kan jẹ́ olú-ìlú Agbègbè Apáìwọ̀òrùn Nàìjíríà láti ba di Olùko. Ní ọdún 1934 , ó di olùtajà àti oníròyìn. Ó ṣe olùdarí àti alákòóso Ẹgbẹ́ Olùtajà Àwọn Ọmọ Nàìjíríà (Nigerian Produce Traders Association) àti akọ̀wé gbogbogbòò Ẹgbẹ́ Àwọn Awakọ̀ Ìgbẹ́rù Ọmọ Ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigerian Motor Transport Union). [2]

Awólọ́wọ̀ tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì gba ìwé ẹ̀rí kékeré ní ọdún 1939, kí ó tó lọ láti gba ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ gíga nínú ìmọ̀ owó ní ọdún 1944. Ìgbà yìí náà ló tún jẹ́ olóòtú fún ìwé ìròyìn Òṣìṣẹ́ Ọmọ Ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigerian Workers). Ní ọdún 1940 ó di akọ̀wé Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigerian Youth Movement) ẹ̀ka Ìbàdàn, ibi ipò yìí ni ó ti ṣolórí ìtiraka láti ṣe àtúnṣe Ìgbìmọ̀ Aláṣẹ Ìdámọ̀ràn Fún Àwọn Ọmọ Ìbàdàn (Ìbàdàn Native Authority Advisory Board) ní ọdún 1942.

Ẹnu ọ̀nà ilé Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀

Ní ọdún 1944 ó lọ sí ìlú Lọ́ńdọ́nù láki kọ́ ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ òfin bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá Ẹgbẹ́ Ọmọ Odùduwà sílẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1947 ó darí padà wálé láti wá di agbẹjọ́rò àti akọ̀wé àgbà fún Ọmọ Ẹgbẹ́ Odùduwà. Lẹ́yìn ọdún méjì, Awólọ́wọ̀ àti àwọn aṣíwájú Yorùbá yòókù dá ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group sílẹ̀, èyí tí ó borí nínú ìbò ọdún 1951 ní Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Nàìjíríà. Láàárín ọdún 1951-54 Awólọ́wọ̀ jẹ́ Alákòóso Fún Iṣẹ́ Ìjọba àti Ìjọba Ìbílẹ̀, ó sì di Olórí Ìjọba Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1954 lẹ́yìn àtúnkọ Ìwé Ìgbépapọ̀ Àti Òfin (constitution).Gẹ́gẹ́ bí Olórí Ìjọba Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ Nàìjíríà, Awólọ́wọ̀ dá ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sílẹ̀ fún gbogbo ọ̀dọ́ láti rí i pé mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà gba le ka.

Jàgídíjàgan ní apá ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ilé ọnà Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀

Nígbà tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbòmìnira ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá ọdún 1960, Awólọ́wọ̀ di Olórí Ẹgbẹ́ Alátakò (Opposition Leader) sí ìjọba Abubakar Tafawa Balewa àti Ààrẹ Nnamdi AzikiweÌlú Èkó. Àìṣọ̀kan tó wà láàárín òun àti Samuel Ládòkè Akíntọ́lá tó dípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí fìdí hẹ Olórí Ìjọba ní Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn mú ni ó dá fàá ká ja tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1962. Ní oṣù kọkànlá ọdún yìí, Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà fi ẹ̀sùn kan Awólọ́wọ̀ wí pé ó dìtẹ̀ láti dojú ìjọba bolẹ̀. Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ ó tó oṣù mọ́kànlá, ilé-ẹjọ́ dá Awólọ́wọ̀ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n lẹ́bi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀, wọ́n sì rán wọn lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá. Ọdún mẹ́ta péré ni ó lo ní ẹ̀wọ̀n ní ìlú Kàlàbá tí ìjọba ológun Yakubu Gowon fi dá sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ ọdún 1966. Lẹ́yìn èyí Awólọ́wọ̀ di Alákòóso Ìjọba Àpapọ̀ fún Ọrọ̀ Okòwò. Ní ọdún 1979 Awólọ́wọ̀ dá ẹgbẹ́ òṣèlú kan, Ẹgbẹ́ Òṣèlú Ìmọ́lẹ̀, sílẹ̀.

Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ṣaláìsí ní ọjọ́ àìkú ọjọ́ kẹsàn-án oṣù karùn-ún ọdún 1987 ní ìlú Ìkẹ́nnẹ́. Lẹ́yìn ikú Awólọ́wọ̀ Ìjọba Àpapọ̀ yí orúkọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ilé-Ifẹ̀ padà sí Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwòrán rẹ̀ wà lórí owó Ọgọ́rùn-ún náírà fún ìṣẹ̀yẹ gbogbo ohun tó ṣe fún ìdàgbàsókè ilẹ̀ Yorùbá àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Àwọn ìwé tó kọ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Awo on the Civil War; Memoir, 1981
  • voice of Courage: Selected Speeches of Chief Obafemi Awolowo; Collection of Speeches, 1981
  • Voice of Reason: Selected Speeches of Chief Obafemi Awolowo; Collection of Speeches, 1981
  • Thoughts on the Nigerian Constitution; Ideological Text, Oxford University Press, 1968

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]