Oghenekaro Itene
Oghenekaro Itene | |
---|---|
Oghenekaro ní ìlú Los Angeles, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà | |
Ọjọ́ìbí | Oghenekaro Lydia Itene October 24th Benin city, Nigeria |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Benin |
Iṣẹ́ | Actress, Humanitarian, Entrepreneur |
Gbajúmọ̀ fún | Tinsel |
Website | Official website |
Oghenekaro Lydia Itene jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti olùṣòwò.
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oghenekaro Itene wá láti Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà, ṣùgbọ́n wọ́n bi ní Ìlú Benin, Ìpínlẹ̀ Ẹdó níbi tí ó dàgbà sí. Ó jẹ́ akẹ́kọ-gboyè láti ilé-ìwé gíga Yunifásítì ìlú Benin. Òun ni àbígbẹ̀yìn nínu àwọn ọmọ mẹ́fà ti òbí rẹ̀. Àkọ́kọ́ ṣíṣe eré ìtàgé rẹ̀ wáyè nígbàtí ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eré ìtàgé ní ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ́mọ ọdún mẹjọ.[1]
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Itene ṣe ìfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi òṣèré ní ọdún 2013 nínu fíìmù Shattered Mirror, èyí tí olùdarí rẹ̀ n ṣe Lancelot Imasuen Oduwa. Ó kópa gẹ̀gẹ̀ bi Simi nínu eré kan tí ilé-iṣẹ́ Total Recall ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀. Ó sinmi ṣíṣe fíìmù fún bi ọdún kan sááju kí ó tó wá padà ní ọdún 2015 nígbà tí ó fi kópa nínu eré Mnet Africa kan táa pè ní Tinsel. Ó tún hàn gẹ́gẹ́ bi Sonia nínu fíìmù Glass House, èyí tí Africa Magic ṣe àgbékalè rẹ̀ ní ọdún 2016.
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn fíìmù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Shattered Mirror (2014)[2]
- Born Again Sisters (2015)[3]
- The Prodigal(2015)[3]
- Glass House (2015)
- Esohe (2017)[4][5]
- Away From Home(2016)[3]
- The Quest (2015)[3]
- Chase (2019 film)
Àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Tinsel
- Lincoln Clan[6]
- The Sanctuary
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Oghenekaro Itene". IMDb. Retrieved 7 October 2017.
- ↑ Editor, Online (30 July 2016). "Oghenekaro Itene A New Flame in Nollywood". Retrieved 7 October 2017.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 "Oghenekaro Itene is an Actor based in Nigeria. - StarNow". www.starnow.com. Retrieved 7 October 2017.
- ↑ Rep, Ent (3 October 2017). "Oghenekaro Itene soaring higher - Vanguard News - Fastest News Delivery Handle". Retrieved 7 October 2017.
- ↑ "Esohe movie premieres in Houston, Texas". 11 June 2017. Retrieved 7 October 2017.
- ↑ "Actress Oghenekaro Itene Stars in ‘Lincoln’s Clan’, Lights Up Movie Scene in South Africa". Retrieved 7 October 2017.