Ogun Àgbáyé Kìíní

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Ogun Àgbáyé Kìíní
300px
Clockwise from top: Trenches on the Western Front; a British Mark IV tank crossing a trench; Royal Navy battleship HMS Irresistible sinking after striking a mine at the Battle of the Dardanelles; a Vickers machine gun crew with gas masks, and German Albatros D.III biplanes
Date 28 July 1914 – 11 November 1918 (Armistice Treaty)

Treaty of Versailles signed 28 June 1919

Location Europe, Africa and the Middle East (briefly in China and the Pacific Islands)
Result Allied victory; end of the German, Russian, Ottoman, and Austro-Hungarian Empires; foundation of new countries in Europe and the Middle East; transfer of German colonies to other powers; establishment of the League of Nations.
Belligerents
Allied (Entente) Powers Central Powers
Commanders
Leaders and commanders Leaders and commanders
Casualties and losses
Military dead:
5,525,000
Military wounded:
12,831,500
Military missing:
4,121,000
Total:
22,477,500 KIA, WIA or MIA ...further details.
Military dead:
4,386,000
Military wounded:
8,388,000
Military missing:
3,629,000
Total:
16,403,000 KIA, WIA or MIA ...further details.

ÌJÀ OGUN ÀGBAYÉ KÌÍNÍ Láti ojó ti aláyé ti dáyé ni àwon ìwò búburú bí i: jàgídígàgan, wàhálà. Irúkèrúdò ti wà nínú ìgbésí ayé omo ènìyàn. Rògbòdìyàn kò yé selè, béè nì làásìgbò kò roko ìgbàgbé. Ìdàrúdàpò nínú ebí, Àríyànjiyàn láàárin òré. Gbónmisi, omi ò to kò yé wáyé láàárín ìlú sí ilu, abúléko sí abúléko. Gbogbo àwon nnkan ló ń parapò tí ó sì ń di ogun.

Tí a bá fi ojú sùnnnkùn woo gun àgbáyé kìíní, a óò rí wí pé gbogbo rògbòdìyàn, àjàkú akátá tó wáyé, kò sèyìn ìwà ìgbáraga, owú jíje, èmi ni mo jùó lo, ìwo lo jùmí lo láàárín àwon omo adárúwurun. Àwon àgbà sì bò wón “àìfàgbà fénìkan ni kò jé káyé ó gún”. Nígbà tí enìkan bá rò pé òun ló mo nnkan se jú, èrò tòun ló tònà jù, kò sí eni tó gbódò ta ko ohun tí òun bá so. Àwon nnkan wònyí tó máa ń bí ogun, nígbà tí elòmírà bá ta ko irúfé èèyàn béè tàbí kí ó je gàba lé òun lórí. Bí ogun se máa ń selè láàárin ìlú sí ìlú ló máa ń selè láàárín orílè-èdè sí orílè-èdè.

Ara àwon nnkan tí ó sokùn fa ogun àgbáyé àkókó nìyí Ogun àgbáyé àkókó yìí bèrè láàárin orílè-èdè méjì kan tí orúko won ń jé Austria-Humgary ati Serbia. Ìlú kékeré kan ní awon orílè-èdè méjèèjì yìí ń jà lé lórí. Orílè-èdè àkókó ló kókó gba ìlú yìí lówó èkejì nínú ogun kan tó wáyé ní odún 1908. Orílè-èdè kejì wá ń dún kòkò lajà láti gba ìtú yìí padà. Sáájú àsìkò yìí, àwon ìsèlè kan sèlè tí ó bèrè sí mú kí àwon orílè-èdè àgbáyé máa se gbún-ùn gbùn-ùn gbún-ùn sí ara won. Sáájú ogun àgbéyé kìíní, àwon orílè-èdè ló máa ń je gàba lórí àwón orílè-èdè mìíràn nígbà máà, kò pé kò jìnnà tí àwon orílè-èdè tí wón ní mú sìn yìí bèrè ń jà fún òmìnira.

Orílè-èdè [Belgium] gba òmìnìra ní odún 1830, nígbà tí ilè [Germany] gba tiwon ní 1871. Ìjà òmìnìra wá bèrè sí ní ta òpòlopò orílè-èdè lólogbó, wón bèrè sí jà fún òmìnira. Àwon orílè-èdè amúnisìn kókó tako èyí, síbèsíbè, won kò rí nnkan se si èyí. Gbogbo àwon tí wón tí wón ti jé gàba lé lórí bèrè sí jà fún òmìnira. Gbogbo won kóra pò. Bí wón se ń se èyí ni òrò eléyàmèyà bèrè sí selè, àti àwón ìsòro tí ó rò mó eléyàmèyà. Àwon nnkan wònyí ló sokùnfà rògbòdìyàn ogun nígbà náà yàtò sí èyí, wíwá àwon òyìnbó sí ilè aláwò dúdú [Africa] wà lára àwon nnkan to sokùnfà ogun àgbáyé kìíní. Owó ló gbé àwon òyìnbó dé ilè aláwò dúdú, wón wá ri pé yíò rorùn fún àwon láti rí nnkan àlùmóónì tí wón ń fé tí àwon bá mú ilè aláwò dúdú sìn. Sùgbón nígbà tí àwon òyìnbó wònyí dé ilè aláwò dúdú, ìjò bèrè sí wáyé láàárin won lórí orílè-èdè tí oníkálukú won yíò mú sìn. Nígbà tí wón ń pín ilè aláwò dúdú láàárin ara won, bí won se pin kò té àwon orílè-èdè amúnisìn kan lórùn lórí bí wón se pín àwon orílè-èdè aláwò dúdú láàárin ara won nígbà náà Àyorísí gbogbo wàhálà yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé àkókó. Àwon orílè-èdè alágbára wònyí bèrè sí funra sí ara won, wón sì bèrè sí ní kó nnkan ijà olóró jo. Àwon orílè-èdè kan bèrè sí ní bá ara won sòré láti gbógun ti orílè-èdè mìíràn. Nígbà tí ogun yìí yóò fi bèrè, awon orílè-èdè alágbára pín ara won sí ònà méjì òtòòtò.

Orílè-èdè [Germany], [Austria-Hungary] ati [Italy] wà ní egbé kan, nígbà tí orílè-èdè [Britain], [France] àti [Pussia] wà nínú egbé kejì, Ní ojó kejìdínlógún osù kefà odún 1914 [18/6/1914] ni okùnrin kan tó ń jé Gavrilo Princip tí ó jé omo ilè Serbia sekú pa omo Oba orílè-èdè Astria-Hungary tí orúko rè ń jé Francis Ferdinand eni tó ye kó di oba ní orílè-èdè náà. Èyí kò sèyìn ìgbìyànjú Serbia láti gba àwon èyà tí Austria-Hungary ti kó sínú ìgbèkùn nínú ogun tí wón ti jà télè. Ikú omo oba yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé nígbà tí orílè-èdè Astria-Hungary gbaná je. Wón pinu láti gbógun ti ilè Serbia. Bí wón se ń se èyí ni ilè Russia tí ó jé òré ilè Serbia kéde pé àwon yíò gbógun tí ilè Austria-Hungary. Àwon orílè-èdè àgbáyé gbìyànjù láti pètù sí wàhálà yìí. Ilè

Austria-Hungary fún ilè Serbia ní àwon nnkan tó le mu ogun yìí wolè, sùgbón ilè Serbia kò tèlé àwon nnkan wònyí. Látàrí èyí, ilè Austria-Hungary kéde ogun lé Serbia lórí ní ojó kejìdínlógbòn osù kejo odún 1914 [28/8/1914]. Bí ilè Austria-Hungary se se èyí tan ni orílè-èdè Russia náà kéde ogun lé ilè Austria-Hungary lórí. Bí ilè Russia se se èyí tán ni ilè Germany kìtò fúnwòn pé tí wón bá danwò, àwon yíò gbógun tìwón. Nígbà tí ilè Austria-Hungary ríbi tí òrò yìí ń to, wón tesè dúró fún ìjíròrò pèlú ilè Russia. Ilè Germany pàse láti tú àwon omo ogun tí wón ti kójo télè kó fún ogun yìí ká. Ile Russia ko etí ikún sí àse tí ilè Germany lórí àse yìí. Èyí ló mú kí ilè Germany kéde ogun lé ilè Russia lórí ní ojó kìíní osù kejo odún 1914 [1/8/1914]. Ní ojó kejì sí èyí ni ilè ni ilè France náà kéde ogun lé ilè Germany náà lórí. Ní ojó keta ni ilè Germany kéde ogun lé ilè France lórí padà.

Sáájú kí ogun tó bèrè, ilè Belgium tí kòwé ránsé sí àwon orílè-èdè tó kù pé tí ogun bá bèrè, àwon kò ní lówó síi. Gbogbo àwon orílè-èdè wònyí sì fowó sí ìwé tí ilè Belgium ko síwon. Sùgbón nígbà tí ogun bèrè, ilè Germany pinu láti gba ilè Belgium kojá láti ko lu ilè France. Sùgbón ilè Belgium kò jálè pé àwon ti pínú pé àwon kò ní dá sí ìjà. Èyí mú kí ilè Germany bínú, wón sì pínú láti gbógun tí ilè Belgium.

Ìpin ìlè Germany yìí mú kí ilè Britain dá sí òrò yìí, wón kìlò fún ilè Germany láti ro ìpin àti gbógun ti ilè Belgium ní èèmejì nítorí pé gbogbo àwon ni àwon fi owó si pé ilè Belgium kò ní lówó si ogun yìí nítorí náà, kí wón má se gbógun ti ilè Belgium. Ilè Germany kò jálè láti gba oro yìí yèwò, èyí sì mú kí orílè-èdè Britan kéde ogun lé ilè Germany lóri ní ojó kerin osù kejo odún 1914 [4/8/1914].

Ilè Turkey náà dá sí ogun yìí ní osù kewàá odún 1914. Nígbà tí ilè France náà da si ní osù kokànlá odún 1914. Báyìí ni ogun yìí di ogun àgbéyé, tí ó di ìjà àjàràn. Gbogbo àwon orílè-èdè tí awon orílè-èdè alágbára wònyí ń se àkóso lé lórí tí wón ń mú sìn pàápàá jùlo ní ilè adúláwò [Africa] àti ilè Lárúbáwá ni gbogbo won náà múra láti gbè séyìn àwon ògá won láti bá àwon orílè-èdè yòókù jà tí èyí sì di isu atayán-an yàn-an káàkiri orílè-èdè àgbáyé.

Ní osù kerin odún 1917 ni ile America náà kéde ogun lé ilè Germany lórí látàrí bí won se kolu àwon ara ilè America nínú okò ojú-oni ti èyí si tako ìlànà ogun jìjà. Òfin sì wà wí pé tí orílè-èdè méjì bá ń jà, àwon omo ogun ara won nìkan ní wón dojú ìjà ko. Orílè-èdè Germany rú òfin yìí. Èyí sì bí ilè America nínú, ìdí nìyí tí wón fi dá’ sí ogun àgbáyé ní odún 1917.

Ogun àgbáyé tó bèrè ní ojó kejìdínlógbòn osù keje odún 1914 [28/7/1914] parí ní ojó kokànlá osù kókànlá odún 1918[11/11/1918] léyìn odún mérin, osù méta àti ojó mérìnlá tí ogun ti bèrè. Owó tí àwon orílè-èdè àgbáyé ná sí ogun yìí tó Ogórùn-ún méjì Bílóònù dólà [Two Hundred Billons Dollas] owó ilè America láyé ìgbà náà tí owó níyì. Bí i ogójì mílíònù [Fourty Millions] omo ogun orílè-èdè àgbáyé ló bá ogun yìí lo kí á sèsè má so ti àwon ogun ojú-oun bí i mílíònù méwàá [Ten millions] tí ó ará ìlú tá kìí se sójà ló sòfò nínú ogun àgbéyé yìí.

Síbèsíbè, wàhálà tó sokùnfà ogun àgbáyé àkókó tí àwon èèyàn rò pé yíò yanju tàbí níyanjú. Wàhálà yìí ló tún sokùnfà ogun àgbáyé kejì àti àwon ogun tó tún wáyé léyìn ogun àgbáyé kìíní. Ní ìparí, ogun kìí se nnkan tí ó dára. Àwon àgbà bò wón ní eni tí ogun ba pa kù ní ń ròyìn ogun. Ogun máa ń fi òpòlopò èmí àti dúkìé sòfò. Yorùbá tún bò wón ní eni tí sàngó bá tojú rè jà rí kò ní báwon bú olúkòso. Enì tí Ogun bá jà lójú rè rí, kò ní be olórun kí ogun tún wáyé ní ojú òun. Olórun kò ní jé kí á ri ogun.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]