Olajumoke Akinjide
Olajumoke Akinjide | |
---|---|
Minister of State for Federal Capital Territory (FCT) | |
Arọ́pò | Ramatu Tijani Aliyu |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 4 Oṣù Kẹjọ 1959 Oyo State, Nigeria |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Peoples Democratic Party (Nigeria) |
Bàbá | Richard Akinjide |
Alma mater | King's College London, Harvard Law School |
Occupation | Business, Politician |
Ọlajumọ̀ké̩ Akinjide tí a bí ní ojó kerin osù kejò odún 1959, ó jé Olóṣèlú Nàìjíríà láti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ Nàìjíríà.Ó jẹ́ mínísítà ipinle fún(FCT)[1] ti àrẹ Naijírià tó jẹ sé̩yìn fàkalẹ̀ (Goodluck Jonathan)ní osù kéje,Ọdún 2011láti ṣiṣẹ́ ní ìgbìmọ̀ oriléèdè Nàìjíríà.[2]
Ìbẹ̀rẹ̀ayé àti ẹbí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọlájùmọ̀kẹ́ Akínjídé,tí a tún mò̩ sí jùmọ̀kẹ́ Akinjide,a bi ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ ọdún 1959 ní ìlú Ìbàdàn,ní ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀nà-Àrà ní àgbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sínú ẹbí ìlú mọ̀-ọ́n ká Adájọ́ tí ó ti di olóògbé pa,Osuolale Abimbola Richard Akinjide, Adájọ́ Àgbà (SAN).[3][4]
Ìṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]láàrín oṣù karù-ún sí oṣù kẹsàn-án ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi amúgbá lẹ́gbẹ̀ẹ́ pàtàkì fún àrẹ lórí ọ̀rọ̀ orí ìlú Àbújá[5][6] lẹ́yìnáà ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i amúgbá lẹ́gbẹ̀é̩ pàtàkì àrẹ lórí àwọn ọ̀rọ G7 àti àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà lókè òkun lábẹ́ àrẹ ìgbànáà Olusegun Obasanjo.
Ó sì tún jẹ́ Òṣèlú Ẹsè̩ kùkú,àti wípé ó jẹ́ olùdíje sí ilé ìgbòmọ̀ asòfin àgbà,Àrin gbùngbùn ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ Àbùradà ẹgbẹ́ ìṣèlu PDP[7][8] ní o̩dún 2011, ní ọdún kanánnà tí wọ́n yàn-án sí ipò mínísítà.[9][10]
Ètò-Ẹ̀kó̩
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Akinjide lọ sí Maryhill Convent School, Idi-Ape, Iwo,Agodi,ní ìlú ìbàdàn, lati ọdún1963 sí ọdún 1968, níbi tí ó ti gba ìlé ẹ̀rí ilé ìwé aláàkọ́ bẹ̀rẹ̀ tí ó sì tẹ̀síwájú sí ilé ìwé girama, ní Ibadan lati 1969 sí1974 níbi tí ó ti gba West African School Certificate(WASSCE).[11]
Akinjide gba ìwé è̩ri LLB (Hons) láti King's College London, àti ìwé ẹ̀rí master's degree nínu ìmọ̀ òfin (LLM) láti ilé ẹ̀kó̩ òfin Harvard ní òkè òkun (United States.)[12]
Ó wà lára àwọn tó gba ọ̀wọ́ ipò kinni nínú ìdánwò English Solicitors.
Akinjide ní ìwé ẹ̀rí mẹ́jì gẹ́gé̩ bí i Agbe̩jó̩rò àti Olùfisùn ní ilé e̩jọ́ aṣòfin tó gajù lo̩ ti Nàìjíríà àti gẹ́gẹ́ bí i Solicitor of England àti Wales.[13]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "The Amazon – Profile of Oloye Olajumoke Akinjide". Vanguard Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-08-22. Retrieved 2022-08-28.
- ↑ "Olajumoke Akinjide". Citizen Science Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-08-28.
- ↑ "Akinjide's daughter vies for Senate seat". The Guardian. 21 December 2009.
- ↑ "Olubadan, CCII, honour Akinjide, Makinde, six Others". Daily Post. 20 November 2013.
- ↑ "Nigeria: Obasanjo's Aide Commended For Enlightenment Effort". All Africa.
- ↑ "Meet The 3 Leading Oyo Female Politicians". Inside Oyo. 19 August 2017.
- ↑ "I remain a staunch PDP member – Ex-Minister, Jumoke Akinjide reacts to defection rumour". Daily Post. 7 August 2018.
- ↑ admin (2022-05-15). "Jumoke Akinjide: The Governor Backpedaling, Feature Of A Listening Leader — Isiaka Kehinde". OyoInsight (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-12.
- ↑ "NEW CABINET: A CASE FOR JUMOKE AKINJIDE". The Nigerian Voice.
- ↑ Aka, Jubril Olabode (February 2012) (in en). Nigerian Women of Distinction, Honour and Exemplary Presidential Qualities: Equal Opportunities for All Genders (White, Black Or Coloured People). Trafford Publishing. ISBN 978-1-4669-1554-1. https://books.google.com/books?id=A0I5gsKiDasC&dq=jumoke+akinjide+special+assistant+to+the+president&pg=PA226.
- ↑ Admin (2016-09-27). "Akinjide-Balogun, Mrs Jumoke". Biographical Legacy and Research Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-12.
- ↑ "LinkedIn Profile of Olajumoke Akinjide". LinkedIn.
- ↑ "Biography Questionnaire - Women Who's Who" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-12.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]