Oliver De Coque
Oliver De Coque | |
|---|---|
| Orúkọ àbísọ | Oliver Sunday Akanite |
| Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | King of Highlife |
| Ọjọ́ìbí | 14 Oṣù Kẹrin 1947 Ezinifite, Nnewi South, Anambra State, Nigeria |
| Aláìsí | 20 June 2008 (ọmọ ọdún 61) |
| Irú orin | Igbo highlife |
| Occupation(s) | Singer, songwriter, record producer, composer, lead guitarist |
| Years active | 1965–2008 |
| Labels | Olumo Records Nigeria Limited, Ogene Records |
| Associated acts | Prince Nico Mbarga, Sunny Agaga, Jacob Oluwale |
Oliver Sunday Akanite ni won bi ni ojo kerinla osu kerin, odun 1947, o se alaisi ni ojo ogun, osu kefa, odun 2008. Orúkọ rinagije rẹ̀ ń jẹ́ Oliver De Coque, tí a mọ̀ sí olórin ile igbo ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, olùkọrin àti oni gítà, àti ọ̀kan lára àwọn olórin ìgbàlódé tó gbajúmọ̀ jùlọ ní Áfíríkà tó ti wà fún ogójì ọdún nínú iṣẹ́ orin highlife. Lílo orin ìbílẹ̀ Igbo àti bí ó ṣe ń lo orin gítà Congo lọ́nà tó gbòòrò ló mú kó di olórí nínú orin highlife ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Orúkọ Oliver lórí ìtàgé, "Oliver De Coque", bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti ń kọrin Ekpili ní ọdún 1976. Wọ́n kọ́kọ́ pe ẹgbẹ́ orin rẹ̀ ní " Oliver de coque àti àwọn akọrin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ", àwọn ènìyàn sì máa ń pè é ní " Oliver De Ka Okwe " nítorí ìfẹ́ ti o ni si Okwe (draft).[1] Bí àkókò ti ń lọ, ó gba oruko ìnagijẹ yii áti ṣẹ̀dá orúkọ ìdílé náà Oliver De Coque.
Ìgbésí ayé àti iṣẹ́ ìbẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí De Coque ní Ezinifite, Ìpínlẹ̀ Anambra, Nàìjíríà ní ọdún 1947, nínú ìdílé Igbo. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún pẹ̀lú orin Ekpili, a sì kọ́ ọ ní gítà láti ọwọ́ onígìtá ọmọ orílẹ̀-èdè Congo kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Piccolo, ẹni tí ń gbé ní Nàìjíríà. De Coque jẹ́ ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ orin juju Sunny Agaga àti Jacob Oluwale, ó sì di olókìkí ní agbègbè náà nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ́langba.
De Coque gba àfiyèsí kárí ayé lẹ́yìn tí ó ṣeré ní London ní ọdún 1973, iṣẹ́ gítà rẹ̀ sì hàn nínú àwo orin Prince Nico Mbarga ti ọdún 1977 Sweet Mother .
Nínú ayẹyẹ pàtàkì kan, Alaafin ti Oyo nígbà náà, Oba Lamidi Adeyemi Kẹta, fi je “Ọba Orin highlife ti Áfíríkà ní ọdún 1994, nítorí bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kara nínú iṣẹ́ ọrin kiko re.
Awo orin àkọ́kọ́ rẹ̀, Messiah Messiah, je gbigbe jade ní ọdún 1977. Ni apapọ, De Coque ṣe igbasilẹ awọn awo-orin mẹ́tàléláàdọ́rùn ún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin rẹ̀ ni a mọ̀ pé ó wà nínú orisi ara orin ti a mon si ogene, tí ó da orin òde òní pọ̀ mọ́ orin ìbílẹ̀ Igbo. Awọn orin ti o ti ko ni "People's Club of Nigeria", "Nempi Social Club", "Biri Ka Mbiri", "Ana Enwe Obodo enwe", "Nnukwu Mmanwu" ati "Identity", orin Identity yi lo ọpọlọpọ ọsẹ ni Radio Nigeria 2's Top Ten ni 1981.
Yàtọ̀ sí iṣẹ́ rẹ̀, De Coque máa ń ṣeré pẹ̀lú ẹgbẹ́ orin Igede International Band, tí àrakunrin rẹ̀ Eugene jẹ́ olórí.
Ìgbésí ayé àti iku re.
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]De Coque ni ọmọ mejila, ninu won ni omokunrin merin wa, pẹlu Solar De Coque, Safin De Coque (Darlington Akanite), Edu De Coque (Chinedu Akanite), ati Ikenna Akanite.
Wọ́n fún De Coque ní ìwé ẹ̀rí ọlá nínú orin láti Yunifásítì ti New Orleans.[2]
De Coque kú ní ọjọ́ ogún oṣù kẹfà ọdún 2008 lẹ́yìn ti o ni dídúró lílù ọkàn. Lẹ́yìn náà ni ọmọ rẹ̀ sọ pé De Coque ti ṣe pàtàkì fún iṣẹ́ ṣíṣe ní ọdún 2008 ṣùgbọ́n ó ti gbèrò láti wá ìmọ̀ràn dókítà ní oṣù ti o se alaisi.[3]
Igbe Aye ti o fi lele
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹrin ọdún 2021, Google Doodle ṣe àfihàn De Coque láti ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin.
Àkójọ di e lara orin re
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Messiah Messiah (1977)
- Odiri (2002)
- Biri ka m biri
- People's Club
- Chukwu Kelu Uwa Cho Ya Nma
- Father Father
- Opportunity (1982)
- Nwanne Di Na Mba
- All Fingers Are Not Equal
- Onye China Azo
- Ka Anyi Bilibe Ndu
- Messiah Messiah
- Uwa Cholu Obi Umeani[4]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Okonkwo, Henry (2016-11-05). "Being Oliver the Coque's son has been demanding, yet rewarding – The Sun Nigeria". The Sun Nigeria. Retrieved 2026-07-28.
- ↑ "Oliver De Coque: Four tins you fit no know about di Nigerian Guitarist". BBC News Pidgin. 2021-04-14. Retrieved 2026-07-28.
- ↑ Kingsley, Ediale (2026-06-10). "How Oliver De Coque most kept secret took him to early grave". National Daily Newspaper. Retrieved 2026-07-28.
- ↑ "Oliver de coque Songs, Albums & MP3 Download 2026". HighlifeNg. 2025-06-10. Retrieved 2026-07-28.