Amẹ́ríkà Látìnì: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Content deleted Content added
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 16:45, 28 Oṣù Kínní 2008

Iselu ni Latin America

Asa Yoruba ni Latin America

ÀSÀ ÀTI ÌSÈJOBA ÀWON YORÙBÁ NÍ LATIN AMERICA AFRICAN (YORUBA) CULTURE IN LATIN AMERICA

YORUBA IN DIASPORA

LÁTI OWÓ

OYÈLÓWÒ, LAWRENCE OLÚFÉMI

Ìfáàrà

“E tókó máa wa ìjoba òsèlú ná

Èyí tókù a ó sì fi fún yin

Àpilèko yìí se àgbéyèwò ìbásepò láàrin Afíríkà (Yorùbá) àti ètò ìsèjoba ni Latin America, àti ní pàtàkì jùlo bi won se igbógun tí àwon ènìyàn Afíríkà nípa kíkópa nínú ìsèjòba Latin Amerika. Nígbà tí Brazil yóò dúró gégé bii burè fún síse àlàyé ní òrín kinníwín Afro-Brazilian ni a o máa fiwé àwon ohun tí ó sele ni orílè-èdè Afro-Latin America nípa ètò ìsèjoba àti ìgbési aye won ni ayé àtijó àti ayé òde òní.

Isé yìí yóò yiri bi àwon ènìyàn ilè Afíríka tí se àmúlùmálà àsà òlàjú àti òsèlú ibi ti won ba ara won. Ìbéèrè ni pé n jé ìgbé ayé àwon ènìyàn ilè Adúláwò ni orílè èdè Latin America dábòbò àsà àti ìse won láti èyìn wà bí? Tàbí ó mú ki àyípadà o de bá àjosepò won?

Nígbà tí a bá sòrò nípa Afíríkà ni àsìkò òwò erú, Yorùbá jé èyà kan pàtàkì tí àsà àti ìse won borí to si gbajúmò jú láàrin àwon èyà ilè Afíríká yòókú. Fún àpeere gbogbo àsà àti ìse Yorùbá bíi èsìn, ìbòrisà àti ìgbàgbó won ni won mu ni òkúnkúndùn ní òkè òkun níbi tí wón kó won lo gégé bíi erú. Èyí kìí se àsodùn rárá pé kàkà ki kìnníùn se akápò Ekùn, oníkálukú yóò se ode tirè lótòòtò. Nítorí náà a rí àwon erú tí wón gbà pé àwon yóò maa se àsà àti èsìn won bi àwon ti n se nígbà tí wón wà ni Afíríkà, àwon erú ti won gbà pé won kò ní se àsà àti èsìn ìlú aláwò funfun ni won pàgó (cadomble) tí Yorùbá si je asaájú fún àwon yòókù.

Ohun tí a n so ni pe kàkà ti Yorùbá yóò fi faramó àsà, èsìn àti ìse ibi ti won ba ara won, èsìn àti àsà ti won ni won gbe láruge tí ó si gbilè débi pe àwon èyà Afíríkà mìíràn darapò mo won ti won si jo n bo àwon òrìsà bíi Èlà, Ògún, Sàngó, Obàtálá, sanponna, Obalufon àti àwon irúnmolè yòókù ni òkè okun. Lára àwon ìlú tí àwon ènìyàn wa ni: Lati America, Bahia, Guayana, Brazil, Haiti, Alagre, Cuba, Columbia, Trinidad abbl. Nínú isé yìí a o lo Afíríkà tàbí àwon ènìyàn ilè Adúláwò dípò Yorùbá fún ìtumò lékùnréré nípa ìgbésí ayé won ní orílè-èdè Amerika.

Afro-American ni àwon ènìyàn tí won kó ni erú ní Afíríkà lo sí orílè-èdè Amerika (New world) àwon ni won n sise tí wón si n gbé àárín Amerika. Afro-Latin America ni àwon erú láti ilè Afíríkà ti won kó won gba Amerika lo si Gúsù Amerika (south American) ní àwon ìlú bíi. Agentina, Mexico, Haiti, Cuba, Brazil abbl.

Ìyàtò tí ó wa láàrin Afro-America àti Afro-Latin America ni pé won kò gbà àwon Dúdú (Afíríkà) láàyè láti ni ìbásepò pèlú àwon aláwò funfun (oyinbo) ni Afro-America, sùgbón kò sí eléyà-mèyà ní Afro-Latin America.

Ìsòro mìíràn tí ó tún kojú àwon ènìyàn Afíríkà ni èdè, ni Afro-America, èdè ìsèjoba won ni èdè Gèésì (English) sùgbón èyí kò ri béè ní Afro-Latin America, èdè ìsèjoba ni èdè Faransé, Potogi àti Spanish (French, Prtuguese and Spanish). Èyí mú kí ó sòro fún àwon ènìyàn láti ní ìbásepò tàbí ìfikùnlukùn àyàfi ki won o ri ògbufò. Títí di odún 1970 si 1972 ni Brazil ó jé ìsòro fún àwon ènìyàn ti o n se akòròyìn láti ko nnkan nípa Afíríkà.

Àwon ìsòro mìíràn tí ó tún kojú àwon ènìyàn Afíríka ni Àríwá Amerika n títa kò àti ìkórira àwon Dúdú gbogbo ohun ti ko ba ti dara won gbà pé owo Afíríkà lo ti wa. Won kò gbà ki àwon Afíríkà ni asojú nínú ètò òsèlú àti ìjoba, bákan náà ni won ko ni ètò òsèlú àti ìjoba, bákan náà ni won ko ni ètó láti dìbò tàbí díje fún ipò kankan. Òfin kò fi ààyè sílè fún ànfààní béè. Bí ìgbógun tí àwon Adúláwò àti ìwà eleyameya se nípon tó. Síbè, àwon ènìyàn Afíríkà si ri ara won gégé bí èyà kanna, ibi yòówù ki won o wa, ìsòro yòówù ki won o maa la koja.

Bi gbogbo ìsòro tí ó n kojú àwon Afíríkà se pò tó yìí, ipa ti àwon ti ó wà ni ìpàgó kò se fi owó ró séyìn, ni osù kinni odún 1976 àwon egbé tí ó wà ni ìpàgó ni Bahia kò gba ìwé àse láti òdò àwon olópàá kí won tó se ìpàdé tàbí ìwóde.

Bákan náà ni Colombia, ni agbègbè Caribbean (àwon eru ti won sa) ni won pàgó síbè, àwon Palenquenos kò tijú láti fi ara won hàn gégé bí Afíríkà nípa ìgbé ayé won títí di òní.

Bákan náà ni a kò le sai menu ba ipa ribiribi ti Manuel Zapeta Ollivella ti se onísègùn, òpìtàn àti ònkòwé omo Afro – Colombian kó, láti ìgbà tí o ti wa ni akékòó ni o ti fi ìfé hàn si ìjàgbara àwon ènìyàn ilè Afíríkà lówó àwon amúnisìn. Ní odún 1950 o kópa nínú ìwóde ìta gbangba tí àwon akékòó Afro-Colombian University se láti tako ìwà amúnìsìn. Omo rè obìnrin tí ó jé odo Edeluma náà ko ewì lórí àwon adúláwò. Nicomedes Santa Cruz ti o je omo Peru ni eni àkókó ti o ko nnkan nípa ìsòro tí ó n kojú àwon ènìyàn adúláwò tí o pe akole re ni “congo Libre” tí o fi sori Patrice Lummba. Nínú ìwé tí o ko ni o se àfihàn ìbásepò to wà láàrin Afíríkà àti Peru. Ó so nínú ìwé re ogbón tí àwon alawo funfun n da láti mu àdínkù ba àwon Afíríkà àti bi won ó se. din agbára won kù, o fi ìwé re náà tako ìwà eléyàmèyà.

A o ni kógo jà bí a bá kùnà láti ménubà Abdias do Nascimento ti òun náà ko ìwé lórí Afro-Latin America, isé ònkòwé yìí ni o gbegba orókè láàrin àwon ònkòwé Afro-Brazilian.

Ìgúnlè

Ni ibèrè pepe ìbásepò láàrin adúláwò àti funfun dàbí omo odo si oga re (olówó re) sùgbón kò pé kò jìnnà, ìfarakínra nípa ìgbéyàwò , èsìn bèrè sí ní da àwon méjèèjì papò.

Àsèyìnwá, àsèyìnbò ikolura àti ifagagbaga àsà bèrè si ni kò ara won jo won n dá egbé sílè tí a mò sí egbe ajìjagbara lówó amúnisìn. Àwon dudu bèrè si ni ri ara won gégé bí òkan láìwo eya tàbí ìlú tàbí gbe òsùnwòn le bi iya ti n je won si.

Bí ó ti le je pé ìjàgbara láti kópa nínú ìsèjoba wáyé, sùgbón kò so èso rere. Ní odún 1920 àwon aláwòdúdú dá egbé òsèlú ti won sílè ni orílè èdè Brazil urugay àti Cuba. Ní orílè èdè Brazil ni a ti dá egbé tí a pè ní Frente Negra Brasilaira (Brazil Front) won forúko egbé náà sílè lódò àwon elétò ìdìbò gégé bí egbé òsèlú, sùgbón ìjákulè dé báa ìgbésè yìí látàrí ìfipá gba ìjoba ológun lówó ìjoba lágbádá tó wáyé. Ní odún 1937 tí o si fi òfin de egbé òsèlú síse. Léyìn èyí egbé náà tún bèrè ìpàdé won sùgbón ojú àpá kò jo ojú ara nítorí pé ìpàdé yìí kò lówó òsèlú nínú bíi ti télè.

Láàrin odún 1973 – 5 ni àwon àyípadà díè bèrè sí ní dé bá àwon adúláwò tí ó wà lábé ìjoba Brazil. Gbigba ominira orílè-èdè guinea-Bissau Mozambique àti Angol kò sàì lówó ipa ti orílè - èdè Brazil kó nínú. Bákan náà ni ipa ti Brazil ko nípa èdè àti àsà Afíríkà kìí se kèrémí. Òpò àwon èèyàn Angola ni won n se àtìpó ní Brazil.

ÌWÉ ÌTÓKASÍ

Anani Dzidizienyo (African Yoruba) Culture and the Political Kingdom in Latin America. Afro-American Studies Brown University Providence, Rhodeisland

Charles Aderenle Alade: Aspect of Yoruba culture in diaspora . Roger Bastide (1971) African Civilization in the New world. Hurst London.