Pẹ́pẹ́yẹ

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Pẹ́pẹ́yẹ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ omi abẹ̀mí tí ó lè gbé ní orílẹ̀ àti nínú omi. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Pẹ́pẹ́yẹ pín sí nínú ẹbí wọ́n tí ó ń jẹ́ Anatidae; ọ̀pọ̀lọpọ̀ Pẹ́pẹ́yẹ ni wọ́n lè gbe ní inú omi iró àti omi iyọ̀ . kan wà tí wọ́n. Pẹ́pẹ́yẹ ní akọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ní abo.[1]

Ìrísí wọn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Pẹ́pẹ́yẹ jẹ́ ẹyẹ tí ó gùn lọ́rùn, ẹnu wọn ṣe sọọrọ, Orí wọn rí gbungbu, ara rẹ̀ wú lọ́tún lósì,tí ó si mu kí ara rẹ̀ rí roboto diẹ̀. Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí pàlàbà, ọmọ ìka ẹsẹ̀ mẹ́ta péré ni ò ní, awọ yíyi tẹ́ẹ́rẹ́ kan ni ó so àwọn ọmọ ìka mẹ́tẹ̀ta náà pọ̀ mọ́ra wọn; tí ó si jẹ́ kí ó rí bí àjẹ̀. Ohun tí ó sọ pẹ́pẹ́yẹ di ẹyẹ ni fífò tí Òun náà lè fò bí àwọn ẹyẹ tí ó kù nínú igbó tí Won ń gbe orí igi.[2]==Ónjẹ̀ rẹ̀== Ko sí irúfẹ́ ónjẹ tí pẹ́pẹ́yẹ kìí jẹ àmọ́ ó fẹ́ràn koríko tàbí èpò,ẹja wẹẹrẹ,kòkòrò, ekòló àti bẹ́ẹ bẹ́ẹ lè.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Ducks Browse by Shape, All About Birds, Cornell Lab of Ornithology". Online bird guide, bird ID help, life history, bird sounds from Cornell All About Birds. Retrieved 2019-12-08. 
  2. "duck - Definition, Types, & Facts". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2019-12-08. 
  3. "Definition of DUCK". Definition of Duck by Merriam-Webster. 2019-12-08. Retrieved 2019-12-08.