Pupa
Pupa jẹ́ àwọ̀ tí ó wà ní ìpẹ̀kun ìgbì-ìmọ́lẹ̀ tó gùn jù lọ nínú àwọ̀n ìmọ́lẹ̀ tí ojú ènìyàn lè rí. Ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọ̀ ọsàn, ó sì dojú kọ́ àwọ̀ àlùkò. Ìjìnnà ìgbì rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí 625 sí 750 nanomita.[1] Pupa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àwọ̀ àkọ́kọ́ nínú àwọ̀n RGB, ṣùgbọ́n nínú àwọ̀n CMYK, ó jẹ́ àwọ̀ àfikún tí a ń rí ṣẹ̀dá nípa dídà àwọ̀ magenta pọ̀ mọ́ eefee. Pupa tún jẹ́ àwọ̀ àtakò sí cyan. Àwọ̀ pupa ní oríṣiríṣi ìrísí àti ìjìnlẹ̀. Ó lè jẹ́ pupa tí ó mọ́lẹ̀ tí ó ní ìrẹ̀pọ̀ ofeefee, gẹ́gẹ́ bí scarlet àti vermillion, tàbí pupa tí ó ní ìrẹ̀pọ̀ búlúù, gẹ́gẹ́ bí crimson. Ní ti ìjìnlẹ̀ àwọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ láti pupa tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bí pínkì títí dé pupa tó dúdú jinlẹ̀ bí burgundy.[2]
Ìpìlẹ̀ṣẹ̀ Ọ̀rọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]“Pupa” jẹyọ láti inú Gẹ̀ẹ́sì àtijọ́ rēad, tí ó sì jẹ́ ìyípadà láti inú Proto-Germanic "raudaz" àti Proto-Indo-European "h₁rowdʰós". Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí pupa. Ọ̀rọ̀ "h₁rowdʰós" sì jẹ́yọ láti inú gbòngbò"h₁rewdʰ-" èyí tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún àwọn ọ̀rọ̀ Latin ruber àti rūfus, Gíríìkì Àtijọ́ ἐρυθρός, àti Sanskrit rudhirá. Ìlò “red” gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọ̀ ni èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n kọ́kọ́ ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 700 lẹ́yìn ikú Jésù. [3]
- Mars appears to be red because of iron oxide on its surface.
- Artist's impression of a red dwarf, a small, relatively cool star that appears red due to its temperature
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>tag; no text was provided for refs named "Georgia State University Department of Physics and Astronomy". - ↑ Maerz, A; Paul, M. R. (1930) (in en). A dictionary of color. New York: McGraw-Hill Book Co.. OCLC 1150631.
- ↑ Maerz, A.; Paul, M. R. (1930) (in en). A Dictionary of Color (1st ed.). New York: McGraw Hill. p. 203. OCLC 1150631. https://archive.org/details/dictionaryofcolo0000aloy/.