Ọ̀nà tí a lè pín òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá sí: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Content deleted Content added
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 14:09, 27 Oṣù Kínní 2008

ÀGBÉYÈWÒ ODÚN ÒRÌSÀ BÀBÁ SÌGÌDÌ NÍ ÌLÚ ILÉ-IFÈ

ADÉOYÈ, ADÉRÓNKÉ MOTÚNRÁYÒ


ÒNÀ TÍ A LÈ PÍN ÀWON ÒRÌSÀ ILÈ YORÙBÁ SÍ

Enu kò kò lórí iye àwon òrìsà tó wà nílè Yorùbá. Bí àwon kan se so pé òkànlénígba òrìsà ló wà ní aàfin Òòni béè náà ni àwon kan n so pé irinwó òrìsà ó lé òkan (401deities) ló wà lóde ìsálayé à ò lè so pàtó iye òrìsà ilè Yorùbá tó wà pèlú iye òrìsà tí a ti ménu bà lókè yìí, nítorí pé kì í se gbogbo òrìsà tó rò láti òde-òrun wá sí òde-ìsálayé ni à n pè ní òrìsà. A rí àwon abàmì nnkan mìíràn tí àwon ènìyàn so di òrìsà. Béè a sì rí àwon alágbára àtijó tí a so di eni òrìsà èyí tí Òrìsà Bàbá Sìgìdì tí ìwádìí yìí dá lé lórí wà. Pèlú gbogbo àlàyé wònyìí, òpòlopò onímò ló ti gbìyànjú láti pín Òrìsà ilè Yorùbá sí orísìírìísìí ònà. Àwon kan pín in sí ònà méjì, àwon kan pín in sí ònà mérin. Bákan náà ni a tún rí àwon kan tí wón pín òrìsà ilè Yorùbá sí ònà márùn-ún. Awolàlú àti Dòpèmú (1979:73) gbà pé ònà méta ni a lè pín òrìsà ilè Yorùbá sí. Bí wón se pín won nì yí:

Ìpia Kínní: ní Òrìsà atèwònrò. Àwon wònyí ní òrìsà tó fi èwòn rò láti ìsàlú òrún rò sí òde-ìsálayé. Àpeere: ní Ifá, Odùduwà, Obàtálá, Òsun, Ògún, Èsù, àti béè béè lo.

Ìpín Kejì ni àwon tí a so di òrìsà léyìn ikú won nítorí ohun ribiribi tí wón gbé se nígbà ayé won. Àpeere ni àwon òrìsà bíi Agemo, Yemoja, Morèmi, Olúorogbo, Èlúkú, Àgan, Bàbá Sìgìdì, àti béè béè lo.

Ìpín Kéta ni àwon èmí àìrí bíi iwin, èbora, àti òrò. Dáúdà (1994: 5) nínú ìwádìí tí ó se pèlú alàgbà Oládépò Obasá, èyí tó se àkosílè rè nínú isé àpílèko rè, so pé ònà mérin ni a lè gbà pín àwon Òrìsà Òrìsà ilè Yorùbá sí. Àwon ni àwon òrìsà atèwònro bíi Odùduwà, Sàngó, Oya, Èsù àti béè béè lo. Ìpín Kejì ni àwon akonidòòsà. Àpeere ni: Èsìnmìnrìn, àti béè béè lo. Ibodòrìsà ni ó wà ní ìpín kéta. Àwon ni àwon omo tí a so di òrìsà nítorí ìbí tí a bí won. Àpeere ni Ìbejì. Ìpín kérin jé àwon òrìsà tí ó je mó èyà ara wa bíi: orí, esè, okó, òbò, ìdí, enu, àti béè béè lo.

Léyìn àgbéyèwò isé tí àwon ènìyàn kan ti se lóríi ònà tí a lè gbà pín àwon òrìsà ìlè Yorùbá, nínú èrò tèmi, pínpín òrìsà sí ìsòrí mérin ni mo fara mó nítorí ìsòrí yìí ló sàlàyé fínnífínní gbogbo nnkan tí a kà sí òrìsà nílè Yorùbá.

Àwon ònà mérìn tí àwon onímò pín in sí ni: òrìsà atèwònrò, àwon èdá tí a so di òrìsà léyìn ikú won, àwon òrìsà nípa ìbí, àti àwon àdàmòdì òrìsà.

Iwe ti a yewo

ÀGBÉYÈWÒ ODÚN ÒRÌSÀ BÀBÁ SÌGÌDÌ NÍ ÌLÚ ILÉ-IFÈ

APÁ KAN NÍNÚ ÌDÁNWÒ ÀSEKÁGBÁ FÚN GBÍGBA OYÈ B.A.(HONS) YORÙBÁ NÍ ÈKA ÈKÓ ÌMÒ ÈDÁ ÈDÈ ÀTI ÈDÈ ADÚLÁWÒ OBÁFÉMI AWÓLÓWÒ YUNIFÁFITÍ ILÉ-IFÈ.

LÁTI OWÓ

ADÉOYÈ, ADÉRÓNKÉ MOTÚNRÁYÒ

OSÙ ÒPE, 2007.

L.O. Adewole - supervisor