Ẹ̀fọn: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Content deleted Content added
New page: ÈFÒN Ara àwon kòkòrò tí ó n fò ni èfon. Wón tún máa n pè é ní yànmùyánmú. Àwon èfon burú gan-an ni nítorí pé wón máa n...
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 08:56, 16 Oṣù Kẹta 2008

ÈFÒN

Ara àwon kòkòrò tí ó n fò ni èfon. Wón tún máa n pè é ní yànmùyánmú. Àwon èfon burú gan-an ni nítorí pé wón máa n tan àìsàn ká. Èfon tí ó bá jé ako kò léwu. Èfon tí ó bá jé abo ni ó máa n fa èjè ènìyàn tàbí ti eranko mu. Ibi tí ó ti n fa èjè mu yìí ni ó ti máa n tan àìsàn ká. Àwon èfon kan máa n tan malaria ká. Àwon kan máa n tan ibà apónjú ká.

Orí omi ni àwon èfon máa n yé sí. Léyìn òsè kan sí márùn-ún, eyin yìí yóò pa yóò di ‘larvae’, eléyìí ní yóò di ‘pupae’ kí ó tó wá di èfon léyìn ojó méta.

A le fín oògùn sí èfon láti pa á tàbí kí a máa jé kí ó rí omi yé sí tàbí kí a máa sin àwon eja kan tí ó máa n je eyin wònyí. Ti a ba fe sun, a le fi neeti yi beedi wa po ki efon ma baa je wa.