Ṣàngó: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Content deleted Content added
New page: Sàngó Yorùbá bò won ni àjànàkú kojá a morí nnkan fìrí, bí a bá rí eerin, káwípe a rí eerin ní òrò sàngó jé láàrin àwon òrìsà i...
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 15:41, 14 Oṣù Kejìlá 2006

Sàngó

Yorùbá bò won ni àjànàkú kojá a morí nnkan fìrí, bí a bá rí eerin, káwípe a rí eerin ní òrò sàngó jé láàrin àwon òrìsà ile e Yorùbá. Sàngó jé òrìsà takuntakun kan gbògíì laarin àwon òrìsà tókù ní ilè e Yorùbá. Ó jé orisà tí ìran rè kún fún ìbèrù. Ìrísí, ìse ati isoro re paapaa kún fún ìbèrù nígbàtí ó wà laaye nítorípé ènìyàn la gbo pe sàngó je télè kí ó tó di òrìsà ààrá. Itan so wipe omo Òrányàn ni sangó i se ati pe Oya, Òsun ati Obà je iyawo re.

Ìhùwàsì búburú ati dídá wàhalá ati ìkolura pèlú ìjayée-fàmílétè-kí-n-tutó pò lówó sàngó gégé bi Oba to bee titi ó fi òtéyímiká. Èyí jásí wípé tomodé tàgbà dìtè mó o. Wón fi ayé ni í lára. Ó sì fi ìlú Òyó sílè nígbèyìn-gbéyín. Ó pokùnso sí ìdí igi àyàn kan lébà ònà nítòsí Òyó nígbàtí Oya: Ìyàwo re kan tókù náà sì di odò.

Ogbón tí àwon ènìyàn sàngó tókù dá láti fi bá àwon òtá rè jà nípa títí iná bolé won àti béèbéè lo ni ó so sàngó di òrìsà tí won ń bo títí dòní tí wón sì ńfi enu won tuba wípé sangó kòso: Oba koso.

ÀWON ORÚKO TÍ SÀNGÓ Ń JÉ

Orísirísí orúko ni a mò sàngó nínú èyí tí gbogbo won sì ní ìtumò tàbí ìdí kan pàtó ti a fi ńpè béè. Àwon oniko bii ìwònyìí.

1. Olukoso: Enití a mò mo kòso tàbí oba tí ó wolè sí kòso.

2. Arèfúnjayé:

3. Àjàlájí:

4. Ayílègbe Òrun:

5. Olójú Orógbó: nítorípé orógbó ni obì tirè, òun ni ó sì máa ńsàféérí nígbà ayé rè. Orógbó náà sì ni a maa nlo ni ojúbo saàngó titi di onì.

6. Èbìtì-àlàpà-peku-tiyètiyè: Orisa tí ó máa ńfi ìbínú gbígbóná pa ènìyàn ni àpalàyà tàbí àpafòn.

7. Onibon òrun: gégé bí òrìsà ó ń mú kí ààrá sán wá lati ojú òrun pèlú ìrókèkè tó lágbára.

8. Jàkúta: gégé bí orisa tí nfi òkúta jà (edun ààrá). Irufe òkúta kékeré kan tí ó máa sekúpa ènìyàn nípasè sàngó

9. Abotumo-bí-owú: Òrìsà o lee wole pa eniyan baje bi eni pe eru nla ni o wolu iru eni bee.

10. Èbìtì-káwó-pònyìn-soro: Irufe Orisa ti o je wipe ìsowó-sekupa asebii re maa ńya ènìyàn lénu gidigidi.

11. Alágbára-inú-aféfé: Òrìsà tí ó jé wípé owoja a re, máa ńwá láti inú aféfé tàbí òfurufú ni.

12. Abánjà-majebi: òrìsà tíí jà láì sègbè léhìn asebi tàbí se àsìmú elòmíràn fún onísé ibi.

13. Lánníkú-oko-oya: Òrìsà tí o ni èrù iku níkàwóó.

14. Òkokonkò èbìtì: Òrìsà tí ó le subú lu ènìyàn bii ìgànnán tí ó ti denukolè.

15. Eléèmò: Òrìsà tí ó ni èèmò.

AWON IWE ITOKASI

1. Daramola Olu [1967] Awon Asa ati Orisa Ile Yoruba. Lati owo Olu Daramola ati jeje Adebayo

2. Adeoye C. L. [1985] Igbagbo ati Esin Yorùbá. Ibadan. Evans Brother. Press