Remi Abiola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Remi Abiola
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
  • oṣere
  • oludari ere
  • oluberejade
Olólùfẹ́Moshood Abiola
Àwọn ọmọ2

Rẹ̀mí Abíólá (Oṣù Kẹẹ̀jọ Ọdún 1953 - Oṣù Keèje Ọdún 2009) jẹ́ òṣèré fiimu ti Ìlu Nàìjíríà àti ìyàwó olóògbé Moshood Abíola, ẹni tí ó ṣe pàtàkì nínú olùṣòwò àti olósèlú ìlú Nàìjíríà.[1] Rèmi? kú sí Ìlu New York ní ọjọ́ mókàndínlógbòn, Oṣù Keèje, ọdún 2009 lẹ́hìn tí ó pàdánù ogun pẹ̀lú aìsàn cancer. Ó fi àwọn ọmọ méjì sáyé lo tí orúko won sì n jẹ́ Abímbọ́lá Umardeen ati Ọlájùmòké Adétòun.[2][3][4]

Iṣẹ́ ìṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Rẹ̀mí kọ́ṣẹ́ òṣèré ní ilé-ìwé tó n bẹ fún eré orí-ìtàgé ní Ìlu England ní àwọn ọdún 70 lẹ́hìn tí ó kúrò ní ìdi isẹ́ Nigerian Airways gẹ́gẹ́ bi olùtọ́jú èro baalu. Nígbàtí ó padà wá sí Nàìjíríà, ó ṣe àfẹ́rí àwọn ipa ó sì tún kópa nínú eré Telifíṣọ́nù tí Báyò Àwálá àti Olóyè Túndé Olóyède ṣe, èyítí wọ́n gbé jáde lóri NTA Channel 10.[5][6]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]