Richard Akínwándé Savage
Richard Akinwande Savage | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1874 Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà |
Aláìsí | 1935 | (ọmọ ọdún 60–61)
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Onímọ̀ ìṣègùn , Oníṣẹ́ ìròyìn àti olóṣèlú |
Gbajúmọ̀ fún | Nigerian Spectator |
Olólùfẹ́ | Maggie S Bowie (m. 1899) |
Àwọn ọmọ |
|
Richard Akínwándé Savage tí wọ́n bí ní ọdún 1874, tí ó ṣaláìsí ní ọdún –1935 ni ó jẹ́ òkan lára àwọn ògúná-gbòngbò onímọ̀ ìṣègùn, oníṣẹ́ ìròyìn àti olóṣèlú ní àárín Ìpínlẹ̀ Èkó ní àsìkò ìjọba amúnisìn Gẹ̀ẹ́sì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìgbà èwe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Richard ní ọdún 1874 sí ìdílé oníṣòwò kan tí ó jẹ́ apá kan ọmọ bíbí ìlú Ẹ̀gbá ati orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Ó kẹ́kọ́ nípa imọ̀ ìṣègùn ní ilé-ẹ̀kọ́ fásitì Edinburgh, tí ó sì ṣíṣeẹ́ ní ilé-iṣẹ́ Afro-West Indian Society, bá kan náà ni ó ṣe àtúnṣe sí iwe "Iṣẹ́-Ọwọ́" (Hand Book) ní ọdún 1899 sí 1900. Ó tún jẹ́ olóòtú kékeré fún The Student. Ó kópa níbi àpérò Pan-African conference tí ó wáyé ní ìlú London nínú oṣù Keje ọdún 1900. Oun ni aláwọ̀ dúdú tó kẹ́yìn tí wọ́n yan sí ilé-ìwòsan ìjọba àmúnisìn gẹ́gẹ́ bí amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ fún ọ̀gá agba tí ó ń ṣiṣẹ́ abẹ nílé ìwòsàn náà, ṣáájú kí ọgbàẹ́ni Joseph Chamberlain tó kéde wípé àwọn Gẹ̀ẹ́sì aláwọ̀ funfun nìkan ni àwọn yóò ma fi di àyè naa láti ọdún 1902. Savage ṣiṣẹ́ fún àìmọye ọdún ní Cape Coast ní Gold Coast tí ó jẹ́ ìlú amọ́nà àwọn Gẹ̀ẹ́sì àmúnisìn tẹ́lẹ̀, tí ó padà di orílẹ̀-èdè olómìnira Ghana lóní gẹ́gẹ́ bí Onímọ̀ ìṣègùn fún ìjọba àti ilé-iṣẹ́ ìwòsàn aládáni. [1]
Ipa rẹ̀ nínú Ìṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Savage jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn tí ó léwájú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú People's Union, ẹgbẹ́ tí wọ́n da sílẹ̀ ní ọdún 1908 láti ọwọ́ ọ̀gbẹ́ni John K. Randle. Lára àwọn ṣànkò-ṣànkò inú ẹgbẹ́ẹ́ náà ni : Òrìṣàdípẹ̀ Ọbasá (1863–1940), Kítóyè Àjàsá (1866–1937)) àti Adéy3mọ Alákijà (1884–1952). Lóòtọ́ ni àwọn tí wọ́n jẹ́ agbátẹrù àti abẹnugan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni wọ́n jẹ́ akójọpọ̀ àwọn àgbà àgbà kan tí wọ́n ń fẹ́ ìṣèjọba àwa-arawa kúrò lábẹ́ àwọn Gẹ̀ẹ́sì àmúnisìn, amọ́ àwọn péréte kan tí wọ́n padà dara pọ̀ mọ́ wọn ni wọ́n ri àríwòye ọjọ́ ọ̀lá, tí wọ́n sì ní èrò rere ọ̀tò míràn lọ́kàn. Àwọn bí : Ernest Ikoli (1893–1960), tí ó jẹ́ oníwé-ìròyìn ati olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú NYM (Nigerian Youth Movement) sílẹ̀.[2]
Ẹgbẹ́ òṣèlú People's Union ń fẹ́ láti lo ìlànà pẹ̀lẹ́-pùtù láti fi gba òmìnira lọ́wọ́ awọn Gẹ̀ẹ́sì àmúnisìn, amọ́, èyí lòdì sí ìgbésẹ̀ ìjìjà-n-gbara ẹgbẹ́ òṣèlú Nigerian National Democratic Party (NNDP) tí wọ́n da sílẹ̀ ní ọdún 1922 láti ọwọ́ Herbert Macaulay.[3], amọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú People's Union túká ní ọdún 1928 lẹ́yìn iku ọ̀gbẹ́ni Randle.[2]
Ní àsìkò ọdún 1914, Savage jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n fohùn ṣọ̀kan láti dá ẹgbẹ́ National Council of British West Africa (NCBWA) sílẹ̀. [1] Púpọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ rere ẹgbẹ́ yí ni wọ́n jẹ́ ènìyàn pàtàkì ní àwùjọ gbogbo ní apá ìwò-oòrùn ilẹ̀ Afríkà. [4] Ẹgbẹ́ yí gbòórò tí ó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní nkan bí ọdún 1919, tí wọ́n sì ṣe ìpàdé àpérò àkọ́kọ́ ní ìlú Ghana ní ọdún 1920. Lára ohun tí ẹgbẹ́ yí ń bèrè fún lọ́wọ́ ìjọba àmúnisìn ni :
- Dídá ilé-ẹ̀kọ́ fáfitì sílẹ̀ ní àwọn ìlú amọ́nà tí wọ́n ń ṣàkóso lè lórí.
- Fífún àwọn ọmọ ìlú ní ànfaní láti di ipò kànkà-kànkà mú nínú ìṣèjọba wọn.
- Kíkópa tó lààmì-laaka àwọn ọmọ ìlú lórí òfin nílé aṣòfin ìjọba ní gbogbo ìlú Adúláwọ̀ tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ti ń ja gàba.[5]
Savage jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn abẹnugan tí wọ́n ṣakitiyan lórí itẹ̀síwájú ilẹ̀ Aláwọ̀ọ̀-Dúdú ní àsìkò tí ó ń ṣàtìpó ní ìlú Ghana. Ó padà sí orílẹ̀-èdè ilú Èkó ní nkan bí ọdún 1915, níbi tí ó ti ń ṣe àfikún àti akọsílẹ̀ lórí àwọn Ìwé-ìròyìn abẹ́lé ṣáájú kí ó tó da Ìwé-ìròyìn Nigerian Spectator sílẹ̀ ní ọdún 1923, àti Akibooni Press sílẹ̀. Savage ló da ìgbìmọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ NCBWA sílẹ̀ nílú Èkó. Ó sì pin ẹgbẹ́ náà sí méjì lẹ́yìn tí ó pàdánù ìyàn sípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ aṣojú-sòfin nínú ẹgbẹ́ ọmọ Ẹ̀gbá . Ó jẹ́ ògúná-gbòngbò nínú àwọn tí wọ́n dá ẹgbẹ́ náà dílẹ̀ nílú Ẹ̀gbá ní ọdún 1920, bákan náà ni Ó sì jẹ́ akọ̀wé fún ẹgbẹ́ ọmọ Ẹ̀gbá bákan náà.
Ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Richard Akínwándé Savage ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú arabìnrin Maggie Bowie, tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Scotland ní ọdún 1899 tí wọ́n sì bí ọmọ méjì péré. Àwọn ọmọ náà ni wọ́n sì yan iṣẹ́ ìpoògùn láàyò gẹ́gẹ́ bí bàbá wọn, àwọn ni : Major Richard Gabriel Akinwande Savage àti Dókítà Agnes Yewande Savage.[6]
Iku rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Richard Akínwándé Savage ṣaláìsí ní ọdún 1935.[1]
Àwọn iwe àṣàyàn itọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 Sherwood 2012, p. 263.
- ↑ 2.0 2.1 Sklar 2004, p. 48.
- ↑ Awa 1964, pp. 94–95.
- ↑ Britannica 2010, p. 185.
- ↑ Falola 2002, p. 216.
- ↑ "CAS Students to Lead Seminar On University’s African Alumni, Pt. IV: Agnes Yewande Savage". University of Edinburgh - Center for African Studies Postgraduate Students Blog. Retrieved 23 December 2016.