Jump to content

Sharks F.C.

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Sharks
Fáìlì:Sharks FC (logo).png
Full nameSharks Football Club
Nickname(s)The Blue Angels
Founded1972
Dissolved2016
GroundSharks Stadium
(Capacity: 5,000)
LeagueNigeria National League
2015ipò 17 (sọ̀kalẹ̀ padà)
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Home colours
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Team colours
Away colours

Sharks Football Club jẹ́ ẹgbẹ́ bọ́ọ̀lù ẹlẹ́sẹ̀ ti Nàìjíríà tí ó wà ní Port Harcourt, Ìpínlẹ̀ Rivers. Wọ́n ń ṣeré nínú ìpele òkè jùlọ̀ ti bọ́ọ̀lù ẹlẹ́sẹ̀ Nàìjíríà, Nigerian Premier League. Ibi-eré ilé wọn ni Sharks Stadium, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣeré àwọn ìdíje ńlá wọn kan ní Liberation Stadium, èyí tí ó lè gba àwọn olùwo tí ó tó ìlọ́po mẹ́ta ju Sharks Stadium lọ. Ní ọdún 2016, wọ́n dá ẹgbẹ́ náà pọ̀ ní ìṣirò-ìjọba pẹ̀lú abánidíje wọn ní ìlú kan náà, Dolphin, àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì sì di mímọ̀ papọ̀ gẹ́gẹ́ bí Rivers United.

Ó kú dí è kí wọ́n kó Sharks lọ sí Abeokuta ní ọdún 1998 nítorí ìṣòro tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń wo ìdíje. Lójúnà àti fi èrò-inú hàn bí àtakò, wọ́n kò láti kópa nínú ìdíje mẹ́fà tí ó kẹ́yìn nínú Professional League ọdún 1998, tí sì wọ́n parí ní owó èyìn ninu àkójọ ìdíje pẹ̀lú ojú-ìwọ̀n 32, a sì dá wọn dúró fún ọdún méjì.[1]

Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbà eré ìdíje tí ọdún 2009–10, pẹ̀lú ọwọ́ èrò gẹgẹbi wọ́n sé dúró sí ìsàlẹ̀ àkójọ, wọ́n sì kọjá àwọn olùdarí mẹ́ta nígbà tí Kadiri Ikhana fi ipò sílẹ̀ lẹ́yìn ìdíje mẹ́jọ. Ní ọjọ̀ kẹtàdínlógbòn oṣù Kejì ọdún 2010, ẹgbẹ́ olùdarí ìdíje náà fún wọn ní ìdádúró àìlójó nítorí "àìtẹ̀lé àwọn òfin ẹgbẹ́" lẹ́yìn ìyípadà àwọn òṣìṣẹ́ olùdarí wọn. Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́ṣà kọlu ẹgbẹ́ náà ní Edo State bí wọ́n ṣe ń padà wá láti ibùdó kékeré kan ní Abuja. Wọ́n ṣàṣeyọrí láti parí ní ipò kẹrìndínlógún pẹ̀lú ojú-ìwọ̀n 48, wọ́n sì yẹ̀ fún ìsọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ojú-ìwọ̀n kan péré.

Ìdàpò Shark FC pẹ̀lú Dolphins Fc

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn tí wọ́n ja wálẹ̀ ní ọdún 2016, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Rivers dá Sharks F.C pọ̀ pẹ̀lú abánidíje wọn Dolphins láti dá Rivers United sílẹ̀, èyí tí ó gba ààyè Dolphins nínú Premier League.[2]

Àwọn Àṣeyọrí won

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. ↑ "Nigeria 1998". RSSSF.
  2. ↑ "Dolphins renamed Rivers United Football Club | Goal.com". www.goal.com.