Shizzi
Shizzi | |
---|---|
Shizzi in 2017 | |
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Oluwaseyi Akerele |
Ọjọ́ìbí | 3 Oṣù Kejìlá 1984 Ibadan, Oyo State, Nigeria |
Irú orin | |
Occupation(s) |
|
Instruments | |
Years active | 2009–present |
Labels |
|
Oluwaseyi Akerele, tí orúkọ gbajúgbajà rẹ̀ jé Shizzi, jé olùṣàgbéjáde orin àti òǹkọ orin ní ilẹ̀ Nàìjíríà.[1]
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]2009–2015: Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Shizzi bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí onílù ní ìjọ rẹ̀. Ó di gbajúmọ̀ lẹ́yìn tí ó sisẹ́ lórí orin Davido ní ọdún 2011 tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Dami Duro", bẹ́ẹ̀ sì ni ó ṣe àgbéjáde orin mẹ́fà mìíràn tí Davido kọ nínú Omo Baba Olowo (2012). Ó ṣe àgbéjáde orin Wizkid, ìyẹn "Love My Baby", àti orin Superstar (2011). Ó gba ìgbóríyìn fún ṣiṣe àgbéjáde orin "Skelewu" àti "Gobe". Òun náà ni ó wà lẹ́yìn àgbéjáde orin Wande Coal, ìyẹn "Baby Face" àti "Go Low". Shizzi ti ṣiṣẹ́ rẹpẹtẹ pẹ̀lú Sasha, Harrysong, OD Woods, Naeto C, Sauce Kid, Wande Coal, Wizkid, D'Prince, May D, Danagog, Emmy Gee, Skuki, DaBaby, Chris Brown, àti Fireboy DML.
Ní ọdún 2013, ó jìjọ ṣe àgbéjáde orin "Tchelete" pẹ̀lú Davido, pẹ̀lú Uhuru/dj maphorisa tí wọ́n sì ṣàfihàn Mafikizolo. Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹfà ọdún 2014, Shizzi ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Davido, Tiwa Savage, Lola Rae, Sarkodie, Diamond Platnumz àti Mi Casa láti ṣàgbéjáde orin ìyìn MultiChoice fún ìkéde Africa Rising.
2016–2019: Sony Publishing, Magic Fingers and The Lion King: The Gift documentary
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2016, ó tọwọ́bọ̀wé pẹ̀lú[2] Sony/ATV Music Publishing gẹ́gẹ́ bí i olùṣàgbéjáde orin àti òǹkọ orin. Ní òpin ọdún 2016, Shizzi ṣàfihàn ilé-iṣẹ́ ìgbórinjáde tirẹ̀, tí ó sọ ní Magic Fingers, tí olórin àkọ́kọ́ tí ó tọwọ́bọ̀wé pẹ̀lú rẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù Kejìlá ọdún 2019 jẹ́ Teni.[3] Ní ọdún 2019, ó farahàn nínú ìwé ìtàn fún àwo-orin Beyonce, ìyẹn The Lion King: The Gift.[4] Ìwé-ìtàn náà jáde ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kẹsàn-án ní orí ABC; níbi tí ó ti sọ̀rọ̀ nípa gbígbé orin jáde fún olórin náà.[5]
2020–lọ́wọ́lọ́wọ́: Òpin ìtọwọ́bọ̀wé rẹ̀ pẹ̀lú Sony publishing
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2020, ó darapọ̀ mọ́ ọ̀wọ́ Sarz fún àgbéjáde oníwákàtí méjì tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Battle of Hits, ní orí Instagram. Àwọn òǹwòran tí ó gbajúmọ̀ níbi àgbéjáde náà ni: Timbaland, Swizz Beatz, Wizkid, Don Jazzy, Davido, Spinall, Kel-P, àti Tiwa Savage.[6] Ní ọdún 2021, Shizzi ṣe ìdáhùn sí ọ̀rọ̀ Teni, lórí bí ó ṣe kúrò lábẹ́ ìṣàkóso tirẹ̀ léyìn tí ó di gbajúmọ̀ olórin nípasẹ̀ rẹ̀, tí ó sì gbóríyìn kankan fún un.[7]
Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹrin ọdún 2022, ó ṣe ìkéde òpin ìtọwọ́bọ̀wé ọlọ́dún mẹ́fà rẹ̀ pẹ̀lú Sony/ATV Music Publishing, àmọ́ ó kọ ìwẹ́ pẹ́, “Ní òpin ọdún tó kọjá, SonyATV fi ìdí rẹ̀ múlè pé wọ́n máa jẹ́ kí òun lọ tí Efe Ogbeni bá faramọ́ àwọn àdéhùn wọn”, ní èyí tí Efe Ogbeni ò faramọ́.[8] Shizzi tún ṣe àfikún pé, “ìtọwọ́bọ̀wẹ́ òun pẹ̀lú Sony ATV ò ṣe òun ní àǹfààní nítorí Ogbeni ò fún òun ní ààyè láti yan agbẹjọ́rò tó máa yẹ ìwé àdéhùn náà wò fínnífínní.[8] Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó ń ṣiṣ́ẹ pèlú Concord Music Publishing,[9] èyí tó jẹ́ ẹ̀yà American entertainment company, ìyẹn Concord.
Àwọn orin rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gẹ́gẹ́ bí olóri akọrin
| |||
Ọdún | Àkọ́lé | Olórin | Àwo-orin |
---|---|---|---|
2017 | "Maria" (featuring Jay Moore and L.A.X) | Shizzi | Non-album single |
2018 | "Wasted" (with. Ceeza Milli) | ||
2019 | "Aye Kan" (with. Teni & Mayorkun) | ||
"All Over You" (with. Wale Kwame, Davido and Kwesi Arthur) | TBA | ||
Gẹ́gẹ́ bí olórin tí wọ́n ṣàfihàn
| |||
Ọdún | Àkọ́lé | Olórin | Àwo-orin |
2016 | "Show You Off" (featuring Shizzi and Walshy Fire) |
WurlD | Love Is Contagious |
Àwọn ìgbóríyìnfún
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọdún | Ayẹyẹ ìgbà àmi-ẹ̀yẹ | Àpejúwe àmi-ẹ̀yẹ | Èsì |
---|---|---|---|
2012 | The Headies | Producer of the Year | Wọ́n pèé |
Nigeria Entertainment Awards | Music Producer of the Year | Wọ́n pèé | |
2013 | Nigeria Entertainment Awards | Music Producer of the Year | Wọ́n pèé |
2015 | Nigeria Entertainment Awards | Music Producer of the Year | Gbàá |
The Beatz Awards | Best Afro Hip Hop Producer | Wọ́n pèé | |
Best Afro Dancehall Producer | Wọ́n pèé | ||
2016 | The Beatz Awards | Best Afro Hip Hop Producer | Wọ́n pèé |
2019 | The Beatz Awards | Afro Pop Producer of the Year | Wọ́n pèé |
Producer of the Year | Wọ́n pèé | ||
2021 | African Entertainment Awards USA | Producer of the Year | Wọ́n pèé |
2023 | All Africa Music Awards | Producer of the Year | Gbàá |
ASCAP Rhythm & Soul Music Awards | R&B/Hip-Hop & Rap Songs for "Peru"[10] | Gbàá |
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Producer Shizzi explains why he worked with Wande Coal on 'Baby Face'". Nigeria Entertainment Today. Retrieved 8 August 2014.
- ↑ "Singer's producer lands record deal with Sony Music". Pulse Nigeria. 6 October 2016. Retrieved 3 April 2020.
- ↑ "Teni - 'Amen'". Pulse Nigeria. 24 December 2016. Archived from the original on 7 August 2020. Retrieved 4 April 2020.
- ↑ "Watch "Beyoncé Presents: Making The Gift" | ABC Updates". ABC (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 3 April 2020.
- ↑ ""Beyoncé Making The Gift - Documentary 2019"". YouTube. Retrieved 3 April 2020.
- ↑ "COVID-19: Sarz, Shizzi entertain fans on Instagram". Vanguard. 4 April 2020. Retrieved 4 April 2020.
- ↑ Alake, Motolani (21 December 2021). "How Teni and Shizzi went from family to sworn enemies [Pulse Exclusive]". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 25 August 2022.
- ↑ 8.0 8.1 Akinyode, Peace (30 April 2022). "Producer Shizzi ends publishing deal with Sony Music". Punch Newspapers. Retrieved 25 August 2022.
- ↑ "Shizzi". Concord Music Publishing. Retrieved 22 November 2024.
- ↑ "2023 ASCAP Rhythm & Soul Celebration | Dr. Dre awards, songwriters, hip-hop, gospel, rnb, music, celebration,". ASCAP. 5 August 2023. Archived from the original on 5 August 2023. Retrieved 13 August 2023.