Sikiru Ayinde Barrister

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Sikiru Ayinde Barrister
AyindeBarrister.jpg
Background information
Birth name Sikiru Ayinde Ololade Balogun
Also known as Alhaji Agba, Sikiru Ayinde Barrister
Origin Ibadan, Ipinle Oyo, Naijiria
Genres Fuji
Occupations Olorin
Instruments Ohun
Years active 1966–2008
Labels Siky Oluyole Records, Lati Alagbada Records

Sikiru Ayinde Barrister [1] [2] [3]) je olorin fuji omo ile Naijiria. Ayinde Barrister bere si korin ta ni odun 1966- 2008, Barrister gbe awo orin to po to 127 jade. Ninu won ni Oke Agba (1980), Ijo Olomo (1983), Nigeria (1983), Military (1984), Barry Wonder (1987), Fuji Garbage (1988), Music Extravaganza (1990) ati Fuji Waves (1991).

Ìgbésí Ayé r̀ẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Síkírù Àyìndé Barrister nínú ẹb́i Sàláwù Balógun ní ìlú Ìb̀adàn, bàbá rẹ̀ Salawu Balógun jẹ́ Alápatà Ẹran, nígbà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ Oníṣòwò pẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Ó lọ Ilé-Ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Muslim Mission àti  Ilé-Ìwé Model ti Mushin tó wà nílù Èkó. Lẹ́yìn èyí ni ó lọ sí ilé-ìwé àkọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ ti Yaba Polytechnic láti kọ́ nípa ìmọ̀ òǹtẹ̀wé àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mìíràn. Àyìndé Barrister bẹ̀rẹ̀ iṣé orin kíkọ láti ìgbà kékeré rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí 'Ají-Sààrì' tàbí Ají-wérẹ lásìkò Àwẹ̀ àwọn Musulumi; bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ náà ló ń kọrin pẹ̀lú rẹ̀ . Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Atẹ̀wé fún Ilé-Iṣẹ́ tí ó pọn ọtí Nigerian Breweries, lẹ́yìn náà ni wọ́n gbà gẹ́gẹ́ bí òǹtẹ̀wé ránṣẹ́ ní Ilé-Iṣẹ́ Ológun Ilè Nàìjíríà Nigerian Armylát̀arí akitiyan rẹ̀́, lásìkò ogun abẹ́lé.</ref>[4] Ó ṣíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọmọ ogun ní Ẹ̀ka kẹwàá '10th Brigade' ti ìpín Kejì '2nd Division' ti Ilé-Iṣẹ́ Ológun Nàìjíríà lábẹ́ Ọ̀gágun 'Adéníran' ó sì jà fitafita ní Awka, Abagana àti Onitsha.

Ikú àti ìsìnkú rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Barrister ku ni ojo 16 osu kejila 2010 ni London nibi to ti lo gba iwosan fun arun ito-suga(diabetes). Isinku re waye ni ogbo ojo osu kejila odun 2010 ni ile re ti o wa ni Eko.[5]


Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Daniel Miller (1995). Worlds Apart: Modernity Through the Prism of the Local. Psychology Press. pp. 244–. ISBN 978-0-415-10789-1. https://books.google.com/books?id=ISq0p5SgGgIC&pg=PA244. 
  2. "Fuji Musician, Sikiru Ayinde "Barrister", Is Dead". SaharaReporters. 16-12-2010.  Check date values in: |date= (help)
  3. "Ayinde Barrister is dead". 234Next. 16-12-2010.  Check date values in: |date= (help)
  4. Paul Wale Ademowo (1996). The King of Fuji Music: Dr. Wasiu Ayinde Anifowoshe Marshal. Effective Publishers. ISBN 978-978-32208-9-8. https://books.google.com/books?id=YusTAQAAIAAJ. 
  5. Ishola Balogun. "Tears roll down as Ayinde Barrister sleeps". 

Ijapo Internet[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]