Tìràkómà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Tìràkómà
TìràkómàIn-turned eyelid and eyelashes as a result of trachoma
TìràkómàIn-turned eyelid and eyelashes as a result of trachoma
In-turned eyelid and eyelashes as a result of trachoma
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10A71. A71.
ICD/CIM-9076 076
DiseasesDB29100
MedlinePlus001486

Àìsàn-ojú Tìràkómà, tí a tún lè pè ní àìsàn-ojú granular conjunctivitis, àìsàn-ojú Egyptian ophthalmia,[1] àti Tìràkómà afọ́nilójú jẹ́ àìsàn àjàkálẹ̀ kan tí Kókóró-àrùn Chlamydia Trachomatis máa n ṣokùnfà rẹ̀.[2] Àjàkálẹ̀ àrùn náà máa n fa ẹran-yíyi lábẹ́ awọ ipéǹpéjú. Yíyi yìí lè mú kí ojú máa dùn ènìyàn, kí òde ẹyinjú máa yinjẹ díẹ̀díẹ̀, tó sì ṣeéṣe kó yọrí sí ìfọ́jú.[2]

Okùnfà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kòkòrò-àrùn tó n fa àìsàn náà lè tan kiri nípa fífi ara kan ojú tàbí imú ẹni tí ó ní àìsàn yìí tààrà tàbí kí ara mà kàn án tààrà.[2] Àìfi ara kàn aláìsàn tààrà lè jẹ́ nípasẹ̀ aṣọ tó ti kàn ojú tàbí imú ẹni tí ó ní àìsàn náà tàbí eṣinṣin tó ti bà lé ibẹ̀.[2] Ọ̀pọ̀ kíkó àìsàn náà yoo ti wà fún bí ọdún díẹ̀ kí ó tó di pé àpá tó dá sí ìpéǹpéjú náà yoo pọ̀ débi pé irun-ìpéǹpéjú yoo bẹ̀rẹ̀ sí ní pa ẹyinjú lára.[2] Àwọn ọmọdé ní í máa n sáábà tan àìsàn náà kálẹ̀ ju àwọn àgbà lọ.[2] Àìní ìmọ́tótó, kí èrò pọ̀jù ní ibi gbígbé, àti àìtó omi tó mọ́ gaara pẹ̀lú àwọn ilé-ìgbọ̀nsẹ̀ tó dọ̀tí tún máa n tètè tan àìsàn náà kiri.[2]

Dídènà àti Títọjú Àìsàn náà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lára awọn akitiyan lati dènà àìsàn naa ni kí àǹfààní sí omi mímọ́ gaara gbèrù sí i, kí wọn sì dín iye awọn tó ní àìsàn naa kú nípa títọ́jú wọn pẹlu àwọn òògùn-apakòkòrò.[2] Èyí lè la ṣíṣe ìtọ́jú gbogbo wọn lẹ́ẹ̀kan naa lọ, àní àpapọ̀ awọn ènìyan tì a mọ̀ pé àìsàn náà wọ́pọ́ lára wọn jùlọ.[3] Wìwẹ̀ àti fífọ ara nìkan kò tó lati dènà àrùn náà sugbọn ó lè wúlò fún àwọn ọ̀nà àtidènà rẹm íràn.[4] Lára awọn onírúurú ọ̀nà-ìtọ́jú ni mími òògùn azithromycin tàbí kíkán òògùn tetracycline[3] siÒ ojuò. gùn Azithromycin ní ó dára jùlọ nítorí ó ṣe e lò gẹ́gẹ́ bí àgbémí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.[5] Lẹyin tí àpá bá ti wà lára ìpéǹpéjú, ó máa nílò kí wọn fi iṣẹ́-abẹ ṣe àtúnṣe ipò tí awọn irun-ìpéǹpéjú wà lati dènà ìfọ́jú.[2]

Bí Àìsàn náà Ṣe Ń Tàn Kiri[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Káàkiri àgbáyé, ó tó 80 miliọnu àwọn eniyan tó ní àìsàn náà lára.[6] Ní awọn ibikan, ìtànkálẹ̀ lè wà láàrin awọn ọgọta sí aadọrun un ninu ọgọrun un awọn ọmọde, tí ó sì maa n wọ́pọ̀ laarin awọn obinrin ju ọkunrin lọ nitori awọn ni wọn n fara kan awọn ọmọde jù.[2] Àìsàn naa ló n fa àìlèríran daadaa awọn eniyan tó lé diẹ ní miliọnu 2.2 tí miliọnu 1.2 lára wọn sì ti fọ́jú patapata.[2] Ó máa n saaba ṣẹlẹ ní awọn orilẹ-ede 53 lati ìhà Afirika, Aṣia, Ààrin-gbùngbùn àti Gúúsù Amẹrika pẹlu awọn eniyan bí i miliọnu 230 tó wà ninu ewu àìsàn náà.[2] Ó máa n yọrí sí pípàdánù biliọnu 8 owó ilẹ̀ Amẹrika lọ́dọọdún.[2] Ọ̀kan lára awọn àìsàn kan tí a mọ̀ sí àwọn àrùn tí a kò kàsí ní ilẹ̀-olóoruní í ṣe.[6]

Àwọn Àtọ́kasì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Swanner, Yann A. Meunier ; with contributions from Michael Hole, Takudzwa Shumba & B.J. (2014). Tropical diseases : a practical guide for medical practitioners and students. Oxford: Oxford University Press, USA. p. 199. ISBN 9780199997909. http://books.google.ca/books?id=ZWcGAQAAQBAJ&pg=PT222. 
  2. 2.00 2.01 2.02 2.03 2.04 2.05 2.06 2.07 2.08 2.09 2.10 2.11 2.12 "Blinding Trachoma Fact sheet N°382". World Health Organization. November 2013. Retrieved 14 March 2014. 
  3. 3.0 3.1 Evans JR1, Solomon AW (March 2011). "Antibiotics for trachoma". Cochrane Database Syst Rev 16 (3): CD001860. doi:10.1002/14651858.CD001860.pub3. PMID 21412875. 
  4. Ejere, HO; Alhassan, MB; Rabiu, M (Apr 18, 2012). "Face washing promotion for preventing active trachoma.". The Cochrane database of systematic reviews 4: CD003659. doi:10.1002/14651858.CD003659.pub3. PMID 22513915. 
  5. Mariotti SP (November 2004). "New steps toward eliminating blinding trachoma". N. Engl. J. Med. 351 (19): 2004–7. doi:10.1056/NEJMe048205. PMID 15525727. http://content.nejm.org/cgi/pmidlookup?view=short&pmid=15525727&promo=ONFLNS19. 
  6. 6.0 6.1 Fenwick, A (Mar 2012). "The global burden of neglected tropical diseases.". Public health 126 (3): 233–6. doi:10.1016/j.puhe.2011.11.015. PMID 22325616.