Túndé Àlàbí-Hùndéyín

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Túndé Àlàbí-Hùndéyín tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Dúdú tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹfà oṣù kẹfà ọdún 1953 (6th June 1953)[1] jẹ́ gbajúmọ̀ a yàwòrán,[2] olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú Àgbádárìgì|Badagry ní ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, Túndé Àlàbí-Hùndéyín jẹ́ gbajúgbajà afẹ̀rọ-yawòrán. Bẹ́ẹ̀ náà ló ń ṣiṣẹ́ olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò. Dúdú tún jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn tí ó máa ń yà sinimá àwọn gbajúmọ̀ àwọn olórin. Bẹ́ẹ̀, ó ti ṣíṣe ní ilé iṣẹ́ tẹlifíṣàn tí ìpínlẹ̀ Ògùn rí ní Abẹ́òkúta. Gbajúmọ̀ rẹ̀ gbòde gẹ́gẹ́ bí olùdarí sinimá-àgbéléwò lọ́dún 1983 nígbà tí ó darí sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń Ìrèké Oníbùdó. Òun ni Aláṣẹ àti olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ "Dudu Productions" tí ó ṣe agbátẹrù sinimá-àgbéléwò tí àkọ́lé rẹ̀ ń "Ìyàwó Àlájì", èyí tí ó jẹ́ sinimá àgbéléwò àkọ́kọ́ tí ilé iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tí ó ń ṣe àyẹ̀wò àwọn sinimá-àgbéléwò, National Film and Video Censors Board, (NFVCB) yẹ̀wò, tí wọ́n sìn gbà á wọlé tó bójú mú láti ṣàfihàn lọ́dún 1994.[3]

Túndé Alabi-Hundeyin tí fìgbà kan jẹ́ Alága Ìjọba Ìbílẹ̀ Badagry, ní ìpínlẹ̀ Èkó.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Garlands for cineaste, Tunde Alabi-Hundeyin, at 66 - The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2019-06-08. Retrieved 2020-02-19. 
  2. Team, Web (2018-07-25). "Tunde Alabi Hundeyin II : Role Models: 12 Sussex Stories in Nigeria : ... : Study with us : University of Sussex". University of Sussex. Retrieved 2020-02-19. 
  3. "Nollywood". Google Books. Retrieved 2020-02-19. 
  4. "Tunde Alabi Hundeyin". Encomium Magazine. 2020-02-19. Retrieved 2020-02-19.