Tẹlifóònù

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ẹ̀rọ tẹlifóònù

Tẹlifóònù ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀-jíjìnnà kan tó úngba àwọn olùṣeúnkan méjì tàbí púpọ̀ ní àyè láti sọ̀rọ̀ sí ara wọn tààrà nígbà tí wọ́n bá jìnnà sí ara wọn. Tẹlifóònù únsiṣẹ́ nípa yíyí ohùn, àgàgà ohùn ènìyàn, sí àwọn àmì ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ-oníná tí wọ́n ṣe é gbé pẹ̀lú wáyà, àti àwọn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ míràn, lọ sí orí tẹlifóònù míràn tí yíò ṣe àtúngbéjáde ohùn náà fún ẹni tó úngbọ́ọ nìbòmíràn. Ìtumọ̀ tẹlifóònù jáde láti Gíríkì: τῆλε (tẹli, ọ̀ọ́kán) àti φωνή (fóònù, ohùn), lápapọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí ohùn ọ̀ọ́kán (distant voice). A tún le pèé lásán ní fóònù.

Ní ọdún 1876, Alexander Graham Bell ló kọ́kọ́ gba ìwé àṣẹ ìdọ́gbọ́nAmẹ́ríkà fún ẹ̀rọ kan tó gbé ohùn ènìyàn jáde kedere. Ẹ̀rọ yìí gba àtúnṣe lọ́wọ́ àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn míràn, nítorí bẹ́ẹ̀ ó di ohun ìlò dandan fún ìkòwò, ìjọba, àti àwọn agbolé.

Ẹ̀rọ tẹlifóònù ní gbohùngbohùn kan (ẹ̀rọ ìfiránṣẹ́', transmitter) láti fi sọ̀rọ̀ àti ẹ̀rọ ìgbọ́ràn (ẹ̀rọ olùgbà, receiver) láti fi gbé ohùn jáde.[1] Bákannáà, tẹlifóònù tún ní ago tó ún polongo ìpè tẹlifóònù tó únbọ̀, ó tún ní ẹ̀rọ ayíwọ́ tàbí bọ́tìnì láti fi tẹ nọ́mbà tẹlifóònù fún ìpè tẹlifóònù míràn. Ẹ̀rọ ìgbọ́ràn àti ẹ̀rọ ìfiránṣẹ́ wà papọ̀ nínú tẹlifóònù kannáà tí a gbé sí etí àti ẹnu nígbà tí a bá ún sọ̀rọ̀. Ẹ̀rọ ìfiránṣẹ́ ún yí ohùnàmi ẹ̀rọ-oníná tó únjẹ́ fífi ránṣẹ́ látorí ìsopọ̀mọ́ra tẹlifóònù sí tẹlifóònù tó úngba ìpè, níbi tó ti únyí àmì náà sí ohùn tó ṣe é gbọ́ létí pẹ̀lu ẹ̀rọ ìgbọ́ràn tàbí nígbà míràn pẹ̀lú ẹ̀rọ asọ̀rọ̀pariwo. Àwọn tẹlifóònù jẹ́ àwọn ẹ̀rọ duplex, tó túmọ́si pé wọ́n ún gba ìgbéránṣẹ́ lọ àti bọ̀ ní ẹ̀kannáà.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "United States Coast Guard Sound-Powered Telephone Talkers Manual, 1979, p. 1" (PDF). Archived from the original (PDF) on 2018-05-14. Retrieved 2020-06-25.