Temuera Morrison
Temuera Morrison Àdàkọ:Post-nominals | |
---|---|
Morrison ní ọdún 2016 | |
Ọjọ́ìbí | Temuera Derek Morrison 26 Oṣù Kejìlá 1960 Rotorua, New Zealand |
Orúkọ míràn | Tem |
Iléẹ̀kọ́ gíga | |
Iṣẹ́ | Actor |
Ìgbà iṣẹ́ | 1972–present |
Alábàálòpọ̀ | Angela Dotchin (1997–2002) |
Àwọn ọmọ | 2 |
Àwọn olùbátan |
|
Temuera Derek Morrison Àdàkọ:Post-nominals (tí a bí ní ọjọ́ kẹríndínlógbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1960) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè New Zealand tí ó gbajúmọ̀ ní orílẹ̀ èdè fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Dr. Hone Ropata nínú eré Shortland Street. Ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Jake "The Muss" Heke nínú eré Once Were Warriors tí ó jáde ní ọdún 1994 àti What Becomes of the Broken Hearted? tí ó jáde ní ọdún 1999.
Ní àwọn orílẹ̀ èdè míràn Morrison gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ Jango Fett àti Boba nínú àwọn eré Star Wars. Òun ni ó kọ́kọ́ kó ipa Jango nínú eré Attack of the Clones tí ó jáde ní ọdún 2002. Àwọn eré míràn tí Morrison ti ṣeré ni The Empire Strikes Back, gẹ́gẹ́ bi Boba nínú The Mandalorian (2019–títí di ìsinsìnyí), The Book of Boba Fett (2021–2022), Echo 3, gẹ́gẹ́ bi Tom Curry nínú Aquaman (2018), The Flash àti Aquaman and the Lost Kingdom.