Tonye Briggs-Oniyide
Tonye Briggs-Oniyide | |
---|---|
Rivers State Commissioner for Culture and Tourism | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 18 December 2015 | |
Gómìnà | Ezenwo Nyesom Wike |
Asíwájú | Nnabuihe Imegwu |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Port Harcourt, Rivers State, Nigeria |
Alma mater | University of Port Harcourt |
Tonye Briggs-Oniyide ni Kọmíṣọ́nà fún ọ̀rọ̀ àṣà àti ìrìn-àjò afẹ́, ti Ìpínlẹ̀ Rivers.[1] Gómìnà Ezenwo Nyesom Wike, ló yàn án sípò yìí ní ọdún 2015, tó ri rọ́pọ̀ Nnabuihe Imegwu.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìlú Port Harcourt ni wọ́n bí Briggs sí, sínú ìdílé kan ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Akuku-Toru, ní ìpínlẹ̀ Rivers. Ó lọ sí University of Port Harcourt fún ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì gboyè B.Sc. nínú ìmọ̀ Biochemistry.
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Federal Character Commission
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ìgbà kan rí, ìyẹn Goodluck Jonathan yan Briggs sípò ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ Federal Character Commission, ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Keje ọdún 2013.[2] Ó dé orí ipò yìí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Kẹjọ, tí ó sì jẹ́ aṣojú ìpínlẹ̀ Rivers.[3]
Culture and Tourism Ministry
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2015, wọ́n yàn án sípò ,láti fi rọ́pọ̀ Nnabuihe Imegwu. Ní oṣù Kẹrin ọdún 2016, ó ṣe ìmúwáyé àjọṣepọ̀ láàárín Africa Film Academy àti Ministry of Culture and Tourism láti pasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, èyí tó fi ìlú Port Harcourt sípò ńlá kan láti ṣètò 12th Africa Movie Academy Awards.[4] Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríwísí fún àìṣètó nínú ọ̀rọ̀ ìdárayá ti ìpínlẹ̀ Rivers lásìkò tó wà lórí ipò náà, èyí tó sì mú kí àwọn kan sọ pé kí ó fi ipọ̀ náà sílẹ̀. Gómínà náà yọ ọ́ kúró nípò yìí ní ọọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kẹjọ ọdún 2016.[5]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Rivers State revs for NAFEST 2018". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-09-30. Retrieved 2022-04-12.
- ↑ "Jonathan sends request for confirmation of 31 nominees to Senate". Legisreportsng. 9 July 2013. http://www.naija.io/blogs/p/531637/senate-news-jonathan-sends-request-for-confirmation-of-31-nominees-to-senate. Retrieved 16 February 2016.
- ↑ "FCC Inaugurates 14 New Commissioners". Nigerian Observer. 17 August 2013. http://nigerianobservernews.com/16082013/news/news22.html#.VsJ1TJG4bIU. Retrieved 16 February 2016.
- ↑ Benjamin Njoku (16 April 2016). "Wike set to reposition Rivers as AMAA 2016 berths in PH". Vanguard (Port Harcourt). http://www.vanguardngr.com/2016/04/wike-set-reposition-rivers-amaa-2016-berths-ph/. Retrieved 1 September 2016.
- ↑ DOLLY, MINA (31 August 2016). "Wike suspends 4 commissioners, Head of Service". premiumtimesng.com. Retrieved 22 June 2022.