West African Coalition Against Trafficking in Person And Smuggling of Migrant in Nigeria (WACTIPSOM)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

West African Coalition Against Trafficking in Person And Smuggling of Migrant in Nigeria (WACTIPSOM) jẹ́ ìsọ̀kan àwọn orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ láti gbógun ti gbígbé tàbí kíkó àwọn ènìyàn káàkiri ní ọ̀nà àìtọ́ àti rírin ìrìn àjò lọ́nà ẹ̀bùrú. Àjọ yìí múu gẹgé bíi àkòrí wọn láti mójútó kíkó àwọn ènìyàn lọ́nà àìtọ́ àti ìrìn àjò lọ́nà ẹ̀bùrú tí ó n gogò síi lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ tó sún mọ́ n. Bákanáà láti fòpin sí kíkó àwọn ọ̀dọ́ wẹẹrẹ kiri àti ọ̀dọ́ langba ọmọbìnrin fún òwò nàbì, kí ayé wọn gba ìgbàlà, àtúnse àti ìrànwọ́ nígbàtí wọ́n bá mú àwọn ọ̀daràn náà.[1]

Àwọn orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ mẹ́ẹ̀dógún ló ti jẹ́ orísun, ọ̀nà ìrékọjá tàbí òpin ìrìn àjò fún kíkó àwọn ènìyàn káàkiri lọ́nà àítọ́ àti rírin ìrìn àjo ọ̀nà ẹ̀bùrú látàrí ìdojúkọ ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè tó dàrú, ìpániláyà, ìdílọ́wọ́ àti ogun láàrin ìlú, aìṣedéédé òṣèlú àti aìrí iṣẹ́ ṣe. [2][3][4]Ìjíròrò láti dá àjọ náà sílẹ̀ wáyé ní osù kejì, ọdún 2020, ìpàdé ìgbìmọ̀ láti kó o jáde wáyé ní ọjọ́ kọkànlá, osù kẹta, ọdún 2020; ìkójáde lábẹ́lẹ̀ wáyé ní ọjọ́ kọkànlélógún, osù karùún, ọdún 2021 nígbàtí ó di kíkójáde gbangba ní ọjọ́ kẹtàdínlógún,osù kọkànlá, ọdún 2021 ní ilé ìtura Nicon Luxury, Àbújá olù-ìlú orílè èdè Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn asojú orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ tó fìmọ̀ sọ̀kan àti àwọn olóŕi A-TIPSOM,NACTAL ati WACSOF.

Àwọn àwùjọ orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ tó fìmọ̀ sọ̀kan láti jẹ́ WACTIPSOM jẹ́ mẹ́ẹ̀dógún: Benin, Burkina Faso, Cape Verde, The Gambia, Ghana, Guinea, Guinea-Bissau, Ivory Coast, Liberia, Mali, Niger, Nigeria, Senegal, Sierra Leone ati Togo.

Àjọ A-TIPSOM Nàìjíríà pẹ́lu ìrànlọ́wọ́ European Union àti FIIAPP ló ṣe agbátẹrù rẹ̀.[5]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]