Jump to content

Wikipedia:Ìtọrọ láti di alámòjútó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àkékúrús:
WP:ILDA
WP:Ìtọrọ láti di alámòjútó
Wọ́n máa ń fi irinṣẹ́ ìṣàmójútó Wikipedia wé ìnulẹ̀, èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣàpèjúwe ìtọrọ ìṣàmójútó pé "fun ní ìnulẹ̀".

Ìtọrọ láti di alámòjútó jẹ́ ìlànà tí àwùjọ Wikipedia ń gbà yan àwọn tí ó máa jẹ́ alámòjútó (tí a tún mọ̀ sí admin tàbí sysops), tí wọ́n jẹ́ àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ní ànfàní sí àwọn ẹ̀yà àti irinṣẹ́ fún ìṣàmójútó. Oníṣẹ́ lè fa ara rẹ̀ sílẹ̀ lati di alámòjútó (ìfara ẹni sílẹ̀) tàbí fa oníṣẹ́ míràn sílẹ̀. {{faramọ́}} {{Wà láàrín}} {{lòdìsí}}

Nípa ìtọrọ láti di alámòjútó[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwùjọ máa ń yan oníṣẹ́ tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé sí ipò alámòjútó. Fún ìdí èyí, àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n bá máa yàn ti gbọ́dọ̀ ti jẹ́ oníṣẹ́ tí ó ti pẹ́ dáradára kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ bóyá wọ́n ṣeé gbẹ́kẹ̀lé. Alámòjútó gbọ́dọ lóye tó pé pẹ̀lú ìwà tó dára nítorí àwọn olóòtú tókù máa ń wá bá wọn fún ìrànlọ́wọ́ àti ìmọràn.

Àwọn ìwọ̀n tí à ń wò fún yíyàn[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kò sí àwọn àbùdá fún yiyan alámòjútó, ju kí ó jẹ́ oníṣẹ́ tí àwọn olóòtù tókù lè gbẹ́kẹ̀lé. Àwùjọ máa ń wo oríṣirísi nkan lára ẹni tí ó bá máa jẹ́ alámòjútó, gbogbo ènìyàn ní ó sì ní èrò tiwọn. Fụ́n àpẹrẹ oun tí àwùjọ ń wá, wo àwọn ìtọrọ láti di alámòjútó tí ó yọrí àti àwọn tí kò yọrí.

Kò sí oníṣẹ́ tí kò lè fa oníṣẹ́ míràn sílẹ̀. Ojú ewé ìfanisílẹ̀ gbọ́dọ wá ní ṣíṣí sílẹ̀ fún ọjọ́ meje gbáko, lati ọjọ́ tí wọ́n tí fi orú́kọ sílẹ̀. Ní àwọn àkókò yìí, àwọn oníṣẹ́ máa sọ èrò wọn, bèrè ìbéérè, tí wọn á sì dá sí ọ̀rọ̀. Ìjìròrò yìí kìí ṣe ìbò (nígbàmíràn, wọ́n máa ń pèé ní !ìbò, wọ́n máa ń lo àmì ẹ̀rọ computer). Ní ìparí, oníṣẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní bureaucrat yìó yẹ ìjíròrò yìí wò lati ri bóyá wọ́n gbà lati fi oníṣẹ́ tí ó fẹ́ si alámòjútó sí ìpò alámòjútó. Nígbàmíràn ó máa ń ṣòro wọ̀n àti pé kìí ṣe ìwọ̀n oǹkà, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlànà, tí bíi ~80% bá ti faramọ, ó yege nìyẹn; tí ó bá kéré sí bíi ~70%, kìí sábà yọrí, bureaucratic sì máa fòye gbée.

Bureaucrats tún lè lo òye wọn lati tètè pa ojú ewé ìforúkọsílẹ̀ dé, tí ó bá fẹ́ rí bi pé oníṣẹ́ tí ó forúkọsílẹ̀ kò ní yọrí, tí kò sì rí ìdì kan lati jẹ́ kí ojú ewé yìí wà ní ṣíṣí. Àwọn bureaucrat nnìkan ló lè pa ojú ewé dé tí ó bá yọrí, ṣùgbọ́n oníṣẹ́ tó dúró dédé lè pa ojú ewé dé tí ó ba ri wípe kò lè yọri rárá; jọ̀wọ́ má ṣe pa ojú ewé ìtọrọ dé tí o bá kópa nínú ìtọrọ náà tàbí ìtọrọ tí kò sí àrídájú pé kò níí yọrí. Tí ó bá jẹ́ ìbojú ewé jẹ́, àìṣètò ojú ewé dáradára tàbí àìgbà tàbí ìforúkọsílẹ̀ tí oníṣẹ́ kọ̀, oníṣẹ́ tí kìí ṣe bureaucrat lè ma ṣakójọ ìforúkọsílẹ̀ náa, ṣùgbọ́n kí wọ́n ri dájú wípé wọ́n pe àkíyèsí oníṣẹ́ tó ń tọrọ alámòjútó si, tí ó bá ṣe kọ́kọ́, kí ó fí ìtọrọ náà sí àyè àwọn ìtọrọ tí kò yọrí

Ní àwọn àyè kan, àwọn bureaucrat lè ṣí ojú ewé sílẹ̀ ju ojọ́ meje tàbí tún ìforúkọsílẹ̀ náà ṣí kí wọ́n lè rí àrídájú. Tí ìtọrọ alábòjúto rẹ kò bá yọrí, jọ̀wọ́ dúró fún ìgbà díẹ̀ kí o tó tún fi orúkọ sílẹ̀ tàbí gba ìforúkọsílẹ̀ míràn. Àwọn olùdíje ti gbìyànjú lẹ́yìn oṣù kan tí ó sì yọrí, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ olóòtú máa ń fẹ́ oṣù tí ó pọ̀ díẹ̀ kí olùdíje tó tún bèèrè.

A gba ìforúkọ ara ẹni sílẹ̀. Tí kò bá dá ẹ lójú nípa fífi orúkọ rẹ sílẹ̀ fún alámòjútó, o lè kọ́kọ́ kàn sí alámòjúto fún ẹ̀kọ́, kí o lè mọ oun tí àwùjọ máa rò nípa ìforúkọsílẹ̀ rẹ. O sì tún lè bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ lọ́dọ olóòtú tó ní ìmọ̀ púpọ̀ kí o lè ní ìmọ̀ sìí.

Sọ àwọn èrò ọkàn rẹ[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gbogbo ará Wikipedia tí ó jẹ́ oníṣẹ́ ní ó lè sọ̀rọ ní àyè Faramọ́, Lòdìsí àti wà láàrín, Ṣùgbọ́n ẹni tí kò bá ti fi orúkọ sílẹ̀ kò le dìbò (#) "ìbò". Ẹ́ni tí ó ń tọrọ alámòjúto lè dásí ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn bá sọ. A lè má ka àwọn ọ̀rọ̀ kan sí tí a bá ri wípé jìbìtì wà níbẹ̀; pàápàá jùlọ tí a bá ri wípé àfikún àwọn oníṣé tuntun, àwọn tí ó ń lo oníṣẹ́ púpọ̀ lọ́nọ̀ àìtọ́, àti àwọn tí wọ́n dí oníṣẹ́ lati gbárùkù ti ọ̀rẹ́ wọn. Jọ̀wọ́ ṣe àlàyé èrò rẹ dáradára. Àfikún rẹ (ní dárádára tàbí ní ìdàkejì) máa lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí ẹ̀rí àrídájú bá wà. Àlayé tó péye máa ń lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ju kí èèyàn kàn sọpé "bẹ́ẹ̀ni", "kò sọ́nòn ńbẹ̀" "gẹ́gẹ́ bíi".

Ìforúkọsílẹ̀[àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kí o tó forúkọsílẹ̀ tàbí fi orúkọ oníṣẹ́ míràn sílẹ̀ fún alábójútó, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹ̀da ojú ewé fún ìforúkọsílẹ̀ oníṣẹ́ náà. Fún ìforúkọsílẹ̀, wọlé sí ibí. Ó dára kí ó kọ́kọ́ wá oníṣẹ́ tí o fẹ́ fà kalẹ̀ kí o tó ṣẹ̀dá ojú ewé yìí, tí oníṣẹ́ náà bá fẹ́ dúró tàbí tí kò bá fẹ́ di alábójútó, ìṣẹ̀dá ojú ewé yìí lè jẹ́ ohun tí kò dára lójú wọn, fún ìdí èyí, kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò. Eleyí kò ní jẹ́ kí oníṣẹ́ náà kọ ìforúkọ rẹ̀ sílẹ̀