Wikipedia:SPAM
Àyọkà tí a bá kẹ́fin wípé ó ṣe ìpolówó tàbí gbóòórùn ìpòlongo fún ènìyàn, olóṣèlú, ilé-iṣẹ́ ni a lè sàmì sí gẹ́gẹ́ bí píparẹ́ kíá kíá nípa lílo ìparẹ́ kíákíá pẹ̀lú irinṣẹ́ {{db-spam}}. Òfin yí kan náà ni ó de ìpolówó tàbí ìpolongo tí a bá rí lórí ojú-ìwé oníṣẹ́ aláfikún sí Wikipedia èdè Yorùbá.̀ A ó lo irinṣẹ́ ojú-ìwé oníṣẹ́, tí a ó sì lo draft namespace, tàbí irinṣẹ́ mìíràn. Èyíkéyìí ìpolówò ọjà tàbí ìpolongo òwò tí wọ́n bá fi sí orí Wikipedia ni a ó yọ dànù pẹ̀lú ìsàmìsí fún píparẹ́ tàbí kí a kó wọn jọ sí abẹ́ Wikipedia:Àwọn àyọkà tí a dárúkọ fún píparẹ́. Ẹ̀wẹ̀, a lè yọ àwọn irúfẹ́ àyọkà bẹ́ẹ̀ kúrò ná nítorí àṣìlò òfin àmúlò, látàrí wípé wọ́n ṣe àdàkọ àwọn ọ̀rọ̀ láti orí ayélujára sí orì Wíkì. Àmọ ṣá, kí a tó pa irúfẹ́ àyọkà bẹ́ẹ̀ rẹ́ dànù lórí Wikipedia, a ní láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìtàn irúfẹ́ àyọkà bẹ́ẹ̀ dáa dáa kí a tó pa á rẹ́ bóyá wọ́n ti gbà á wọlé tẹ́lẹ̀. Bí ó ba rí bẹ́ẹ̀, àtúnṣe tuntun tí wọ́n ṣe ni kí o ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀. Bí a bá sì kẹ́fín wípé aláfikún kan lo ohùn ìpolówó ọjà nínú àyọkà kan, ohun tí a lè ṣe ni kí a ṣe àtunṣé irúfẹ́ àyọkà bẹ́ẹ̀ nìpa kíkọ àyọkà bẹ́ẹ̀ lÀìṣojúṣájú.