Zainab Gimba
Zainab Gimba (a bí i ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá, ọdún1972) jẹ́ olóṣèlú orílẹ̀-èdè Nàíjíríà. Wọ́n yàn án sí ilé ìgbìmọ̀ aṣojú orílẹ̀ èdè Nàíjíríà gẹ́gẹ́ bíi olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń ṣàkóso ní agbègbè àpapọ̀ Bama/Ngala/Kala Balge, ìpínlẹ̀ Borno. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ aṣòfin Commonwealth àti àwọn alátìlẹ́yìn fún aṣojú àti ìtọ́jú ìdọ́gba ọkùnrin àti obìnrin.[1][2]
Ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Zainab ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú Ìṣàkóso gbogbogbò. Ó tún tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì gba ìwé ẹ̀kọ́ gíga nínú Ìṣàkóso gbogbogbò. Ó ní ẹ̀kọ́ ọ̀mọ̀wé nínú Ìṣàkóso gbogbogbò àti Àtúpalẹ̀ ìlànà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ìpínlẹ̀ Maiduguri.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní àkókò ọdún 2011 sí 2014, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí kọmíṣọ́nà fún ilé-iṣẹ́ tí ó ń rísí ìpínyà òṣì àti ìrónilágbara fún àwọn ọ̀dọ́ ní ìpínlẹ̀ Borno. Ó tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kọmíṣọ́nà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ Àgbáyé ti ìpínlẹ̀ Borno( Universal Basic Education Board) láti ọdún 2014 sí 2015. Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí Kọmíṣọ́nà fún ilé-iṣẹ́ tí ó ń rísí ìlò omi ní Ìpínlẹ̀ Borno ní ọdún 2015, ó sì ṣiṣẹ́ títí di ọdún 2018.[3]
Lásìkò àpérò ìgbìmọ̀ aṣòfin Commonwealth ìkẹrìnlélọ́gọ́ta (64th CPC) ní ilé ìgbafẹ́ Speke Munyonyo, Kampala ní ọdún 2019, wọ́n yàn Zainab gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ ìgbìmọ̀ aṣòfin àwọn obìnrin Commonwealth ní ilé adúláwọ̀.[4]
Àmì ẹ̀yẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Certificate of Merit Award by National Youth Service Corps (NYSC) Yobe state in recognition of her excellent performance in CDS and primary assignment, 2000.
- Award of leadership excellence by Rotary club of Maiduguri city, April 2018
- Award of excellence by Ngala students association (NGALSA) for her humanitarian service. 29 April 2018.
- Award by West Africa Water Expo for her support to West Africa WAWE Expo 2018.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Reps raise alarm over plight of IDPs". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-07-18. Retrieved 2022-02-21.
- ↑ "Nigerian lawmaker elected vice-chairperson Commonwealth Women in Parliament" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 25 September 2019. Retrieved 7 November 2020.
- ↑ ian lawmaker elected vice-chairperson Commonwealth Women in Parliament"
- ↑ https://m.lindaikejisblog.com/2018/10/meet-dr-zainab-gimba-the-only-woman-who-reportedly-won-apc-ticket-in-the-whole-of-borno-state.html