Jump to content

Zainab Ibrahim Kuchi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Zainab Ibrahim Kuchi
Ministry of Niger Delta Affairs
In office
2011–2012
Arọ́pòDarius Dickson Ishaku
Minister of State for Power
In office
2011–2013
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Occupationlawyer, entrepreneur

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Goodluck Jonathan yan Hajiya Zainab Ibrahim Kuchi gẹ́gẹ́ bí i Minister of Statefor power and Minister ti ìlú u Niger ní oṣù kéje ọdún 2011. Ó tún jẹ́ oníṣòwò, olùdásílẹ̀ àti Alákóso Gbogbogbò (CEO) ilé-iṣẹ́ Daralkuchi.

Zainab tún jẹ́ agbẹjọ́rò àti oníṣòwò tó ní irírí ju ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lọ nípa òfin àti ìṣàkóso. Ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1981, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé àṣòfin (Judiciary headquaters). Lẹ́yìn agùn bánirọ rẹ̀ (NYSC), Zainab ṢIṣẹ́ pẹ̀lú Ministry of Justice ní Minna, ó sì ṣiṣẹ́ níbẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ àti ìdámẹ́ta. Lẹ́yìn náà, Zainab ṣiṣẹ́ ní Central Bank of Nigeria láti Oṣù Karùn-ún ọdún 1989 títí di Oṣù Kejìlá ọdún 2004. Lẹ́yìn tí ó yáyà, ó dá ilé iṣẹ́ ìmọ̀ran òfin tirẹ̀ sílẹ̀. Ó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ àti Alákóso Gbogbogbò (CEO) ilé-iṣẹ́ Daralkuchi Group. [1]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i olóṣèlú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ààrẹ ṣáájú, Jonathan, yàn án sípò minisita nínú ìgbìmọ̀ rẹ̀ láti ṣojú ìpínlẹ̀ Niger. wọ́n tún yàn án gẹ́gẹ́ bí i Minister of state for power. Ní oṣù kokànlá ọdún 2011, Ó kede pé wọ́n ti fọwọ́ sí ìpèjọpọ̀ àdéhùn pẹ̀lú Sinohydro Corporation. Ilé-iṣẹ́ tí orílẹ̀-èdè Ṣáínà ni yóò kọ ilé amúnágbára omi tó ní agbára megawatt 3,050 ní Mambilla, pẹ̀lú àgbègbè Plateau ní ìpínlẹ̀ Taraba. Ní oṣù Kẹwàá ọjọ́ 30, ọdún 2012, lẹ́yìn ìpàdé Federal Executive Council, Ààrẹ Jonathan paṣẹ pé kó yípò pẹ̀lú minisita ìpínlẹ̀ tó wà tẹ́lẹ̀ fún Ẹ̀ka Ọ̀rọ̀ Ilẹ̀ Níger Delta, Darius Ishaku. Ààrẹ Jonathan sọ pé àtúnṣètò kéékèèké yìí jẹ́ láti mú kí àwọn ẹ̀ka náà lagbara síi kí wọ́n lè péye àwọn ìrètí àwọn ará ilú Nàìjíríà.

Ní ọjọ́ Kẹtàlá, Oṣù Kẹsán, ọdún 2013, wọ́n yọ Zainab kúrò nípò Minister of power lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn minisita mìíràn méjọ, lẹ́yìn ìpàdé Ìgbìmọ̀ Àgbà Ilẹ̀ (FEC). [2][3][4]

Ní́ ọdún 2014, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí i alákóso fún ìpolongo ìbò ààrẹ fún ọ̀gbẹ́ni Goodluck Jonathan ní ìlú Niger[5][6][7]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "DARALKUCHI ECO FARMS AND FOOD LIMITED Nigeria company profile - address, contacts, owners". ng-check.com. Retrieved 2020-11-19. 
  2. "Jonathan shocks FEC, sacks 9 ministers". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2013-09-11. Retrieved 2020-11-19. 
  3. "Jonathan Sacks 9 Ministers". P.M. News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2013-09-11. Retrieved 2020-11-19. 
  4. "Nigeria's President Goodluck Jonathan sacks ministers" (in en-GB). BBC News. 2014-02-12. https://www.bbc.com/news/world-africa-26153637. 
  5. "Zainab Ibrahim Kuchi". www.africa-confidential.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-19. 
  6. Vanguard, (Lagos) (31 October 2012). "Nigeria: Jonathan Swaps Two Ministers". allAfrica. Retrieved 19 November 2020. 
  7. "Power generation to hit 10,000mw in Dec., says govt". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2013-01-10. Retrieved 2020-11-19. 
Wikiquote logo
Wikiquote logo
Nínú Wikiquote a ó rí ọ̀rọ̀ tójẹmọ́: