Ìgè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Opadotun

Olátúnjí Ọ̀pádọ̀tun

Ewì Fún Àwọn Ògo Wẹẹrẹ Ìwé Kejì

Ige

Ìgè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìgé Adùbí ìsa

Àdùbí oníkẹ̀ẹ́yẹ

Ẹni ti kò màdùbí

A lóníkẹ̀ẹ́yẹ̀ ṣánpọ́nná

Iké ṣeé yẹ̀ lẹ́yìn ẹni

Ìgè Àdùbí asaare

Èèyàn tó bẹ Ìgè Àdùbí níṣẹ́

Ojo


Òjó[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Òjó olúkù-lóyè

Igbe kíké níṣẹ́ ẹyẹ

Òjó Àdìó alájòóòsinmi

Tóo jó láruru

Tóo sì jó ní kọ̀bì

Ajayi

Àjàyí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àjàyí Ògídí olú

Oníkánga àjípọn

Ò bomi òsùùrù wẹdà

Ẹni Àjàyí gbà gbà tí ò le gbà tán

Aríléwọ́lá, ikú ní í gbolúwarẹ

Irele

Àwọn ewí àkàkọ́gbọ́n: Ìrẹ̀lẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Títí tí n ó fi kú

N ò ní yéé hùwà ìrẹ̀lẹ̀

N ò ní rágbà fún

N ò ní lanu mi bú ajunilọ

Oríkì Iṣẹ́ àárọ̀ Yorùbá: Ọdẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Onígbérí kíjìpá

Alákò à ń kàdá bọ̀

Anílàsà láàrin ìbọn

Alájá tí í lagogo kagbó

Ikú tí í pàmọ̀tẹ́kun

Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ fún kìnnìhún

Eléṣù lẹ́yìn erin

Ìdágìrì àwọn ìmàdò

Olójú-iná à á sìnkú àgbọ̀nrín

Abàtàn íṣorọ́rí ẹfọ̀n


Àwọn oríkì orúkọ àmútọ̀runwá: Ìbejì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Táyélolú, Kẹ́yìndé

Ẹélà Ọba ọmọ

Gbàbílà a-rinkinkin-lọ́ṣọ̀ọ́

Olúwaà mi

Góńgó lórí ìgbágó

Tì-ẹ̀mì lórí ìyeyè

Ò-gbórí-ìyeyè nawọ́ sáboyún

Àlubọ́sà ẹgàn, agẹmọ eréwé

A-jí-folú-kẹ́


Iwe ti a yewo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olátúnjí Ọ̀pádọ̀tun (2001) Ewì Fún Àwọn Ògo Wẹẹrẹ Ìwé Kejì Rasmed Publications LTD. Ibadan, oju-iwe 1-12.

Olatunji Opadotun