Funmilayo Ransome-Kuti

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Oloye Funmilayo Ransome-Kuti, MON, ni a bí ni Frances Abigail Olufunmilayo Thomas; ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹwa ọdun1900 ó sì jade laye ni ọjọ́ kẹtala oṣu kẹrin ọdun1978); a tun mọ si Funmilayo Anikulapo-Kuti. Ó jẹ́ olukọni, oloṣelu, alagbọrandun ati a jà-f'ẹtọ awọn obinrin ni orilẹ-ede Naijiria.

Ìlú Abeokuta, ni ipinlẹ Ogun ni orilẹ-ede Naijiria ni a ti bi Fumilayo Ransome Kuti, òun sì ni akẹkọ obinrin akọkọ ti o lọ si ile-iwe girama ti ilu Abeokuta . Ní ìgbà tí Funmilayo Ransome Kuti wa ni ọ̀dọ́langba, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, oun ni o si kọ́kọ́ ṣe ètò ile ẹko ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni orilẹ-èdè Naijiria ti o si tun ṣe iranlọwọ eto ẹkọ àgbà fún àwọn obinrin ti eto ọrọ aje wọn ko gbe pẹẹli.