Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): SH

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Atumo-Ede (Yoruba-English): ₦


Ṣá, Adj. faded, stale, fallow. Aṣọ yìí sá (This cloth faded)

Ṣá, Ṣá lọ́gbẹ́, v.t. to wound with catlass sword, etc. Ó sá a lọ́gbẹ́ (He wounded him with cutlass)

Ṣà, v.t. to pick up one by one. Ó ṣà wọ́n nílẹ̀ (He picked them up one by one from the ground)

Ṣá, adv. merely, only. Mo fèsì kan sá (I made merely one reply)

Sábá, n. chain bracelet.

Ṣábaṣàba, adv. clumsily, messy, badly. Ó ń ṣe ṣábaṣàba. (He is behaving badly)

Ṣá bolẹ̀ v.t. to strike to the ground wounded. Ó ṣá a bolẹ̀ (He struck him to the ground wounded)

Ṣàbùkù, adj. disgraceful, to disgrace. Ó ṣàbùkù ara rẹ̀ (He disgraced himself)

Ṣàbùkù sí, v.t. to disgrace, to despise, to disrespect, to disparage. Ó ṣàbùkù sí araa rẹ̀ (He disgraced himself)

Ṣàbùlà, Sàdàlù, v.t. to adulterate, to dilute. Ó ṣàbùlà ọtí náà (He diluted the liquor)

Ṣàdéhùn, v.t. to make an agreement. Wọ́n ṣàdéhùn (They made an agreement)

Ṣàfarawé v.t. to imitate. Ó ṣàfarawé rẹ̀ (He imitated him)

Ṣafẹ́, Gbafẹ́, v.i. to be foppish, to look stylish. Ó gbafẹ́ (He looks stylish)

Ṣàfẹnusí, v.t. to have voice in a matter, to vote for. Ó ṣàfẹnusí sí ọ̀rọ̀ náà (He has a voice in the matter)

Ṣàfẹ́rí v.t. to seek, to enguire after, to be longing for. Ó ń ṣàfẹ́rí rẹ (He is longing for you)

Ṣàfiyèsí. Ṣàkíyèsí, v.t. to observe, to take notice of. Ó ṣàkíyèsí rẹ̀ (He took notice of him)

ṣàfojúdi, Ṣàfojúdi sí, v.t. to be insolent to, to be impudent, to be impertinent to. Ó ṣòfojúdi sí mi (He was impertinent to me)

Ṣàfọwọ́rá, v.i. to steal, to pilfer. Ó ṣàfọwọrá ìwé mi (He stole my book)

Ṣàgàbàgebè, v.i. to play the hypocrite. Ó ṣàgàbàgebè (He played the hypocrite)

Ṣàgálámàṣa, v.i. to play underhand trickes. Ó ń ṣàgálámàṣà (He is playing the underhand tricks)

Ṣagídí, v.i to be obstinate, to be self-willed, to behave stubbornly. Ó ń ṣagídí (He is behaving stubbornly)

Ṣágo, n. demijohn

Ṣàgunlá, v.i. to be indifferent to, not to care about. Ó ṣàgunlá sí ni (He did not care about me)

Ṣàgbà, v.i. to play the part of older person in anything, to be older them.. Ó ṣàgbà mi (He is older than me)

Ṣàgbàfọ̀, v.t. to send clothes to the laundry, to be a washerman. Ó ń ṣàgbàfọ̀ (He is a washerman)

Ṣàgbàgún, v.t. to pund grains as a job. Ó ń ṣàgbàgún (He pounds grains as a job)

Ṣàgbàkà, v.t. to be engaged in counting (cowries) as a job. Ó ń ṣàgbàka (He is engaged in counting cowvied as a job)

Ṣàgbákò, v.t. to meet by chance, to come across as a misfortune or an unfortunate circumstance, to be befallen by ill fortune, to be unlucky. Ó ṣàgbákò (Ill-fortune befell him)

Ṣàgbàkọ, v.t. to till another’s farm for him on hive. Ó ṣàgbàkọ oko mi (He tilled my farm for me on hire)

Ṣàgbàlọ̀, v.t. to grind (corn) for pay. Ó ṣàgbàlọ̀ àgbàdo fún mi (He ground corn for me for a fee)

Ṣàgbàlu, v.t. to give cloth to be beaten and made smooth, to beat and make cloth smooth for a fee. Ó ń ṣàgbàlù (He beats and makes cloth smooth for a fee)

Ṣàgbàmọ, v.t. to take contract for building mud-houses. Ó ń ṣàgbàmọ (He takes contract for building mud-house)

Ṣàgbàro, v.t. to take contract for tilling another’s farm. Ó ń ṣàgbàro. (He takes contract for tilling another person’s farm)

Ṣàgbàsọ, v.t. to interprete. Ó ń ṣàgbàsọ (He is an interpreter)

Ṣàgbàṣọ́, v.t. to act as a watch-man. Ó ń ṣàgbàṣọ́ (He is a watch-man)

Ṣàgbàtà, v.t. to hawk goods about for another. Ó ń ṣàgbàtà (He is hawking goods about for another person)

Ṣàgbàtọ́ v.t. to act as a nurse for another. Ó ń ṣàgbàtọ́ (He is acting as a nurse for another person)

Ṣagbáwo, v.i. to be a steward. Ó ń ṣagbáwo (He is a steward)

Ṣàgbàwò, v.t. to put a sick person in the hands of a doctor, to accept to take as a patient. Oníṣèègùn náà ṣàgbàwò rẹ̀ (The doctor accepted to take him as his patient)

Ṣàgbàwọ̀, v.i. to lodge about, not to have one’s own abode, to be in the act of hiring clothing. Ó ń ṣàgbàwọ̀ (He is in the habit of hiring clothing)

Ṣagbe, v.i. to beg for alms. Ó ń ṣagbe (He is begging for alms)

Ṣàgbèrè, v.i. to commit fornication or adultery, to be a fornicator or adulterer. Ó ṣàgbèrè (He commited adultery)

Ṣàgbéré, v.i. to go to excess either in saying or doing something, to insult. Ó ṣàgbéré sí mi (He insulted me)

Ṣàgbẹ̀dẹ, v.i. to take to the blacksmith’s trade. Ó ń ṣàgbẹ̀dẹ (He is a blacksmith)

Ṣahun, Láhun, v.i. to be close-fisted, to be miserly, to behave in a miserly way. Ó ṣahun (He behaved in a miserly way)

Ṣái, interj. an expression of defiance.

Ṣàì, adv. not, having the same force in Yorùbá as the English prefix, ‘un’, mostly used with ‘Ma’= not. Ó ṣàìkọrin (He did not sing)

Ṣàìbọláfún, Ṣàìbọ̀wọ̀fún, v.t. to disrespect, to dishonour. Má ṣàìbọ̀wọ̀ fún un (Don’t disrespect him)

Ṣàìdọ́gba, adj. unequal. Wọn kò ṣàìdọ́gba (They are not unequal)

Ṣàìfà, v.t. not to draw or pull. Kò ṣàìfà á (He did not fail to pull it.)

Ṣàìfẹ́, v.t. to have, to be unwilling. Kò ṣàìfẹ́ ẹ (He did not hate him)

Ṣàìgbàgbọ́, v.i. to be credulous, to disbelieve. N kò ṣàìgbà á gbọ́ (I did not disbelieve him)

Ṣàìgbèfún, v.i. to be unfavourable, to be unpropitious. Àwọn òfin náà kò ṣàìgbèfún iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣíṣe (The regulations are not unfavourable for agricultural production)

Ṣàìgbẹ́kẹ̀lé, v.t. to distrust. N kò ṣàìgbẹ́kẹ̀lé e (I did not distrust him)

Ṣàìgbọràn, v.i. to be disobedient. Kì í ṣọmọ tó ń ṣàìgbọràn (He is not a disobedient chind)

Ṣàìjẹ́wọ́ v.i. to refuse to confess. Kò le ṣàìjẹ́wọ́ (He can not refuse to confess)

Ṣàìkíyèsí, v.t. not to heed or observe. Ó ṣàìkíyèsí i (He did not observe it)

Ṣàìkúnná, adj. coarse, rough. Kò ṣàìkúnná (It is not coarse)

Ṣàìlera, adj. sick, ill, weak. Ó ṣàìlera fún ara (The sody is weak)

Ṣàìléso, Sàìsèso unfruitful, barren. Kò ṣàìléso (She is not barren)

Ṣàìlẹ́gbẹ́, adj. of its own kind, singular, sui generic. Kò ṣàìlẹ́gbẹ́ (It is not the only one of its own kind)

Ṣàìlẹ́wà, adj. ugly, uncouth. Kò ṣàìlẹ́wà. (He is not ugly)

Ṣàìlọ́lá, adj. dishonourable, disreputable, without honour. Kò ṣàìlọ́lá (He is not without honour)

Ṣàìlọ́ra, adj. quick, smart. Wọ́n ṣàìlọ́ra láti kọ́wèé (They were quick to learn)

Ṣàìmọ́, adj. unclean. Àwọn bàtà náà kò ṣàìmọ́ (The shoes are not unclean)

Ṣàìmọ̀, adj. ignorant of, unaware of. Kò ṣàìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà. (He is not unaware of the matter)

Ṣàìmú, v.t. not to take. Kò ṣàìmú un dání lọ sílé (He did not fail to take it along whicle going home)

Ṣàìní, v.i. to be destitute of. Wọ́n kò ṣàìní ìfẹ́ ènìyàn lọ́kàn (They are not destitute of human feelings)

Ṣàìgbàgbọ́, v.t. not to have confidence in, to disbelieve, to discredit. Kò ṣàìgbà á gbọ́ (He does not disbelieve him)

Ṣàìpẹ́, adj. quick, punctual, soon, before long. Ó lè ṣàìpẹ́ wá mú un (He may come and take it before long)

Ṣàìpò, adj. unmingled, unmixed. Wọn kò ṣàìpò ó (It was not unmixed)

Ṣàìpọ̀, adj. few, Kò lè ṣàìpọ̀ (It can not be few)

Ṣàìrẹ̀, v.i. unwearied, not tired, Ko lè ṣàìrẹ̀ ẹ́ (He cannot be unwearied)

Ṣàìsàn, v.i to be ill, to be sick. Ó ṣàìsàn (He is ill)

Ṣàìsùn, v.i. to keep awake, to pass a sleepless night. Ó ṣàìsùn lánàá (He passed a sleepless night yesterday)

Ṣàìṣe déédéé, adj. unequal. Àwọn igi méjèèjì kò ṣàìṣe déédéé ara won. (The two sticks are not unequal)

Ṣàìsóòótọ́, adj. unture. Kò lè ṣàìsóòótọ́ nínú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. (All his accusations against him cannot all be untrue)

Ṣàìsòótọ́, v.i. to be unfair, to be unjust. Kò lè ṣàìsòótọ́ nínú ẹ̀sùn tí ó fi kàn án (He cannot be unfair in his accusation against him)

Ṣàìtà, adj. unsold. Wọn kò lè ṣàìta àwọn ilé yẹn (The houses cannot remain unsold)

Ṣàìtàsé, v.i. not to miss the mark. Ọfà rẹ̀ kò lè ṣàìtàsé ẹranko náà (His arrow cannot but miss the animal)

Ṣàìtẹ́rùn, adj unsatisfactory. Kò lè ṣàìté ẹ lọ́rùn (It cannot be unsatisfactory to him)

Ṣàìtó, adj. not enough. Kò lè ṣàìtí (It can not but be enough)

Ṣàìtọ́, v.i. to behave ill towards one. Ó ṣàìtọ́ sí i (He behaved ill towards him)

Ṣàìtọ́, adj. not straight, crooked. Igi tí o máa gé kò gbọdọ̀ ṣàìtọ́ o (Do not cut a crooked tree)

Ṣàìwá, Ṣàìsí, v.i to be absent. Kò ṣàìwá sí ìpàdé náà (He was not absent from the meeting)

Ṣàìwẹ̀, adj. unwashed. Má ṣàìwẹ̀ fún àwọn ọmọ yẹn láàárọ̀ yí o (Don’t leave the children unwashed this morning)

Ṣàìwí, v.i. not to speak. O kò gbọdọ ṣàìwí fún un nípa ọ̀rọ̀ náà (You should not but speak to him about the matter)

Ṣàìwò, v.i. not to look, Kò lè ṣàìwò ó (He can not but look at it)

Ṣàìwọ̀, adj. disagreeable. Bí owó ojà yẹn bá ṣàìwọ̀ fún ọ, fi sílẹ̀ (If the price of the good is bdisagreeable to you, leave it)

Ṣàìwọ̀, v.i. not to enter. Máà jẹ́ kó ṣàìwọ ilé (Don’t allow him not to enter the house)

Ṣayé, v.i. to manage the affairs of a country or the world. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣayé sí? (How are they managing the affairs of the world?)

Ṣàìyẹ, adj. unworthy, unfit, unsuitable. Ko gbọdọ̀ ṣàìyẹ fún iṣẹ́ náà (He should not be unsuitable for the job)

Ṣàjàpá, v.i. to hawk goods about for sale. Ó ń ṣàjàpá (She is hawking goods about for sale)

Ṣàjèjì, adj. strange, new, uncommon. Ohun tí ó ṣàjèjì kan ṣẹlẹ̀ láàárọ̀ yìí (A strange thing happened this morning)

Ṣàjẹ́, v.i. to practice witchery. Ó ń ṣàjẹ́ (He is practicing witchery)

Ṣájẹ, v.t. to cut to pieces for the purpose of eating, to give a good handshake. Ó ṣá a jẹ (He gave him a good handshake)

Ṣaájò, v.t. to be concerned about the safely of some one, to take care of, to be solicitous. Ó ṣaájò ọmọ náà (She took care of the child)

Ṣàjọ, v.t. to collect, to gather together, to hold a council. Ó ṣà wọ́n jọ (He gathered them together)

Ṣàjọmọ, v.t. to have a mutual understanding of any matter, to agree together. Wọ́n ṣàjọmọ̀ ọ̀rọ̀ náà (They have a mutual understanding of the matter)

Ṣáájú, prep. before, in front of, ahead of. Ó ṣáájú wa (He is ahead of us)

Ṣáká, adv. quite. Ó mọ́ ṣáká (It is quite cleam)

Ṣàkàjúwe, v.t. to describe. Ó ṣàkàjúwe rẹ̀ (He described it)

Ṣákálá, adj. profane, commonplace. Má sọ̀rọ̀ ṣákálá ní ilé Ọlọ́run (Don’t use a profance language in the church)

Ṣákálá, adv. merely, in vain. Ó ṣàlàyé rẹ̀ ṣákálá (He merely explained it)

Ṣàkàṣàkà, adv. clearly, plainly. Ó ń sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà (He is talking plainly)

Ṣákaṣàka, adv. messy, rough. Ó rí ṣákaṣàka. (It is rough)

Ṣakaṣìkì, n. iron fetters. Wọ́n fi ṣakasìkì sí i lẹ́sẹ̀ (They put iron fetters round his feet)

Ṣàkàwé, v.t. to compare, to illustrate. Ṣàkàwé àwọn ilé méjèèjì (Compare the two houses)

Ṣálìí, v.i. to prove abortive or disappointing, to miscarry, to refuse to five. Ìbọn yìí ṣákìí (They gun refused to fire)

Ṣákiṣàki, adj. rough, regged, shaggy. Ó rí ṣákiṣàki (It is rough)

Ṣàkíyèsí, v.t. to notice, to observe. Ó ṣàkíyèsí mi (He noticed me)

Ṣ’’ako, v.i. to stray, to wander. Ọmọ náà ṣáko lọ (The child wandered away)

Ṣáàkókò, v.i. to be opportune. Ó bọ́ ṣáàkókò (It came at an opportune moment)

Ṣáko lọ, v.i. the same as ‘Ṣáko’.

Ṣàkóso, v.t. to govern, to rule, to control. Wọ́n ń ṣàkóso wa (They govern us)

Ṣaláàápàdé, v.t. to meet bychance. Ó ṣaláàápàdé rè (He met him by chance)

Ṣaládásí, v.i. to be officious

Ṣaládúgbò, v.i. to be a neigbour. Ó fẹ́ ṣaládúgbò wa. (He wants to be out neighbour)

Ṣalágbàfọ̀, v.i. to act as a laundres. Ó fẹ́ ṣalágbàfọ̀ (He wants to act as a laundress)

Ṣalágbàsọ, v.i. to be an advocate. Ẹgbẹ́ náà kò ṣalágbàsọ fún ìlò ipá (The group does not advocate the use of violence)

Ṣaláìmọ́, adj. unclean. Omi náà kò lè ṣaláìmọ́ (The water can not be unclean)

Ṣaláìmọ̀, adj. ignorant. Kò lè ṣaláìmọ àwọn nǹ̀̀kan ìgbàlódé (He cannot be ignorant technology)

Ṣaláìyíhùn, v.i. to be positive, to be insistent, not to go back on promise. Máà ṣsláìyíhùn pade lórí owó ọja náà (Don’t be insistent on the price of the good)

Ṣaláìlágbára, adj. weak. Kò lè ṣaláìlágbára. (He cannot be weak)

Ṣaláìlera, adj. weak, ill. Kò lè ṣaláìlera (He cannot be ill)

Ṣaláìlówó, adj. poor. Kò lè ṣaláìlówó (He cannot be poor)

Ṣaláìlọ́kàn, adj. timid, coward. Ọmọ-ọba kò lè ṣláìlọkan (A prince cannot be a coward)

Ṣaláìlọ́mọ, adj. childless. Àdúrà wa nip é kí a má ṣaláìlọmọ. Our prayer is that we should not be childless)

Ṣaláìyìn, v.t. not to praise. Aláìmoore lè ṣaláìyin Ọlọ́run (An ungrateful person may not praise God)

Ṣálaporẹ́, n. a kind of small fish.

Ṣálọ́gbẹ́, v.t. to waund with knife, sword, cutlass, etc. Ó ṣá a lọ́gbẹ́ (He wounded him with a cutlass)

Ṣamí, v.t. to spy, to be a spy. Ó ṣamí fún wọn (He spied for them)

Ṣamọ̀nà, v.t. to lead, to guide. Òun ló ń ṣamọ̀nà wa (He leads us)

Ṣán, v.t. to eat àgìdí or any kindred food without sauce, to plaster, to cut down bush or forest. Ó ṣán igbó náà (He cut the bust)

Ṣàn, v.i. to flow (as a river) to be watery (as soup), to be too thin, to rinse (Clothes, etc.) Wọ́n ṣan àwọn aṣọ náà (They rinse the clothes)

Ṣáná, v.t. to ignite a match. Ó ṣáná (He ignited the match)

Ṣàna, v.i. to pay respect to any member of the family of one’s wife, to give dowry, to perform the customary duties to the members of the family of one’s wife. Ó ṣàna. (He performed the customary duties to the members of the family of his wife)

Ṣàn bò, v.t. overflow. Omi náà ṣàn bo bèbè rẹ̀ (The river overflowed its bank)

Ṣanbọnna, adv. straight, upright. Máa lọ ṣanbọnna fún máìlì kan (Keep straight on for one mile)

Ṣàǹfààní, adj. advantageous, useful profitable. Ó ṣàǹfààní fún àwa méjèèjì. (It was advantageous to the two of us)

Ṣánjà, v.t. to make a mud ceiling. Ó ṣánjà. (He made a mud ceiling)

Ṣánkú, v.t. to die prematurely. Ó ṣánkú (He died prematurely)

Ṣánkùúta, fisánkùúta, v.t. to dash against the stone. Ó fi orí ṣánkùúta (He dashed his head against the stone)

Ṣánlé, Rẹ́lẹ́, v.t. to plaster a house. Ó ṣánlé rẹ̀ (He plastered his house)

Ṣánlẹ̀, v.t. to cut overgrown grass, to clean a bush or forest for planting. Ó ṣánlè (He cut the overgrown grass)

Ṣánpá, v.i. to swing the arm. Ó ṣánpá rẹ̀ (He swung his arm(

Ṣansẹ̀, v.i. to wash the feet. Ó ṣansẹ̀ rẹ̀ (He washed his feet)

Ṣanṣan, adv. straight. Ó dúró ṣánṣán (He stood straight)

Ṣàánú, v.t. to be merciful towards, to have mercy or pity on. Ṣàánú mi (Have mercy on me)

Ṣanúrò, v.i. to think. Ó ń ṣanúrò nípa rẹ̀ (He is thinking about it)

Ṣánwọ́, v.i. to be empty-handed, to swing the hand. Ó ṣánwọ́ rẹ̀ (He swung his hand)

Ṣápa, v.t. to hack to death. Ó ṣa a pa (He hacked him to death)

Ṣapá kan, v.t. to do a portion of a thing.. Ó ṣapá kan iṣẹ́ náà. (He did a portion of the work).

Ṣápaṣàpa, adv. roughly, filthily. Ògiri tí wọ́n ṣán ṣápaṣàpa ni (It was a roughly plastered wall)

Ṣápẹ́, Ṣátẹ́, v.i. to clap hands together, to applaud. Ó ṣápẹ́ (He clapped his hands together)

Ṣàpẹẹrẹ, v.i. to illustrate, to signify, to signify, to maek a sign. Ó fi àwòrán ṣàpẹẹrẹ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ (His lecture was illustrated with diagrams)

Ṣápọn, v.i. to be diligent, to be industrious. Akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣaápọn in (He is a diligent student)

Ṣàrà, v.i. to be singular, to be strange.

Ṣárán, v.i. to speak incoherently (through old age) to be a dotard. Ó ń ṣárán (He is speaking incoherently)

Ṣàrékérekè, v.i. to be treacherous, to be adouble dealer. Ó ń ṣàrékérekè (He is treacherous)

Ṣàárẹ̀, v.i. to be weary. Ó ń ṣàárẹ̀ (He felt weary)

Ṣàrò, v.t. to think upon, to meditate upon, thing over. Wọ́n ṣ ọ̀rọ̀ náà rò (They thought over the matter)

Ṣàròyé, v.i. to be talkative, to quarrel, to talk at great length. Wọ́n ń ṣàròyé lórí ọ̀rọ̀ náà (They talked at great length on the matter)

Ṣáṣá, adv. clearly, completely, thoroughly. Ó ń sọ̀rọ̀ ṣáṣá (He is speaking clearly)

Ṣàṣá, n. small-pox marks. Ṣàṣá ṣá a lójú (He has small-pox marks on his face)

Ṣàṣà, adj. few, not many. Ṣàṣà ènìyàn níí fẹ́ ni lẹ́yìn: tájá tẹran níí fẹ́ni loju ẹni (Few speak well of a person behing his back-all praise him in his presence

Ṣaṣara-ọwọ̀, n. a worn-out broom, tip of a broom. Ó fi ṣaṣara-ọwọ̀ tọ́ mi (He tounched me with the tip of a broom)

Ṣááṣààṣá, adv. here bad there, at various point. Ó tá ṣáásààṣá (He touched various points)

Ṣàṣàrò, v.i. to meditate, to give much thought to. Wọ́n ń ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ náà (They are giving much thought to the matter)

Ṣàṣegba, v.t. to do in turn, to take turns to do something. Wọ́n ń ṣàṣegbà (They are taking turns to do it)

Ṣàṣejù, v.t. to overdo a thing. Ó ṣàṣejù (He overdid it)

Ṣàṣelékè, Ṣàṣerégèé, v.t. to go to extremes in anything. Ó ṣàṣerégèé lórí ọ̀rọ̀ náà (He went to the extremes on the matter)

Ṣàṣeṣá, v.t. Same with ‘Ṣàṣejù.’

Ṣáátá, v.t. to slander, to disparage, to malign. Ó ṣáátá mi (He disparaged me)

Ṣà tán, v.t. to pick up entirely. Ó ṣà wọ́n tán (He picked them up entirely)

Ṣàtìpó, v.i. to sojourn in a place, to dwell temporarily in a place. Ó Ṣàtìpó ní ìbàdàn (He sojourned at Ìbàdàn)

Ṣàtúnṣe, v.t. to mediate. Ó to ṣàtúnṣe láàrin ẹgbẹ́ méjèèjì tí wọ́n ń ṣe ìpórógan (He ha mediated between the two groups who were in dispute)

Ṣáwá, n. a kind of small fishes

Ṣàwàdà, v.i. to jest, to indulge in jesting, to mock. Ó fi i ṣàwàdà (He mocked him)

ṣàwárí, v.t. to search and find out. Wọ́n fi i ṣàwárí (They searched for it and found it out)

ṣàwáwí, v.t. to make excuses. Má ṣàwáwí kankan (Don’t make any excuse)

ṣawo v.i. to be initiated into a secret cult. Ó ti ń ṣawo (He has been initiated into a secret cult)

Ṣaworo, n. small brass bell, jingle

Ṣawòró, v.i. to be too close-fisted. Ó ń ṣawòró (He is too close-fisted)

Ṣàwòtán, v.t. to heal thoroughly, to effect a complete cure. Ó ṣàwòtán egbò náà (He healed the wound thoroughly)

Ṣawun, Ṣahun, Láhun, adj. niggarely, stingy. Máà ṣahun pẹ̀lú súgà yẹn (Don’t be stingy with the suger)

Ṣàyàn, v.t. to select, to choose. Ó ṣa ìwé náà yàn (He selected the book)

Ṣàyíká, v.t. to encircle, to surrounded. Wọ́n ṣàyíká wa (They surrounded us)

Ṣe, as a particle is often contracted to ‘Ṣ’ – e.g. ṣe àfiyèsí= Ṣàfiyèsí; Ṣe àìlera= Ṣàìlera; Ṣe àṣàrò = Ṣàṣàrò.

Ṣe, v.i. to do, to act, to make, to cause, to be. Ó ṣe é (He did it)

Ṣebí, v.i. to think, to suppose. Mo ṣebí o lọ síbẹ̀ (I thought you went there)

Ṣèdájọ́, v.t. to judge, to pass sentence, to decide a case. Ó ṣedájọ́ fún un (He judged his case)