Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): Ba

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Atumo-Ede (Yoruba-English) ()

Yoruba-English

B

1. Ba: v. ‘to hide’ Mo ba sí abẹ́ igi; I hid under the tree.

2. Bà: v. (i) to ferment: Kòkó náà ti bà; The cocoa has fermented (ii) to perch: Ẹyẹ náà bà; The bird perched (iii) to foment: Mo ba egbò rẹ̀; I fomented his ulcer (iv) to hit: Òkúta tí ó sọ bà mí; The stone he threw hit me. (v) to be afraid: Ẹ̀rù bà mí; I was afraid. (vi) settle: Ẹyẹ náà bá sórí ẹ̀ka igi ka; The bird settled on a branch.

3. Bẹ́: v. (i) to burst: Ó bẹ́ pẹ̀ẹ́; It bursts (ii) to cut: Ó bẹ́ ẹ ní orí; He cut his head off (iii) to jump: Ọmọ náà bẹ́; The child jumped (iv) to buy a little quantity of a commodity: Ó bẹ́ tábà; He bought a little quantity of tobacco (vi) to crack: Orógbó náà bẹ́; The bitter cola cracked when it was eaten (vii) to start: Òràn ti bẹ́; Trouble has started (viii) to puncture: Táyà náà bẹ́; The tyre punctured (iv) to spat: Ó bẹ́ itọ́; He Spat.

4. Bẹ: v. (i) to be bright: Ó bẹ; It is bright (ii) to peel: Ó bẹ iṣu náà; He peeled the yam (iii) to speak cheekily: Ó bẹ si mi; He spoke cheekily to me (iv) to exist: Ó ń bẹ; It exists (v) to be forward/to be screwed: Ọmọkùnrin yẹn bẹ; That boy is too forward.

5. Bẹ̀: v. ‘beg’: Ó bẹ̀ mí; He begged me (ii) apologize: O ti ṣẹ Olú. Bẹ́ ẹ̀ ‘You have offended Olú. Apologize to him. (iii) implore: Ó bẹ olè náà kí ó máà kó gbogbo owó wọn lọ; He implored the robber not to take all their money (iv) ask: Ó bẹ̀ wà lọ́wẹ̀; He asked us for communal help.

6. Bí: v. (i) to give birth to: Ó bímọ; She gave birth to a baby (ii) to be annoyed: Ó ń bínú; He is annoyed (iii) If: Bí o lù mi n ó lù ọ́; If you hit me I will hit you. (iv) Question marker: Ó lọ bí?; Did he go? (v) how: Ó kọ́ mi bí mo ti máa se é; He taught me how to do it (vi) that: Ó ní àfi bí òun pa á; He says there is nothing but that he will kill him (vii) When/after: Bí ó ti rí mi, inú rè dùn; When he saw me, he was happy (viii) like: Ó rí bí Olú; He is like Olú (ix) as: Ṣe bí mo ti wí; Do as I say (x) bear: Obìnrin yẹn ti bí ọmọ mẹ́wàá; That woman has borne ten children (xi) born: Ọdún tí ó kọjá ni wọ́n bí Olú; Olú was born last year (xii) just: Adé wole bí mo se jádé; Adè entered just as I left (xiii) more: Ènìyàn bí ogbọ̀n ló wà nílé rẹ̀; There were thirty people in his house, more or less (xiv) reproduce: Ológbò máa ń bí ní ẹ̀ẹ̀méjì lọ́dún; Cats reproduce twice a year (xv) such: Wọ́n ń fẹ́ èso tí ó kún fún omi bí i osàn; They want some juicy fruit such as orange (xvi) whether: Nò mọ̀ bí ó máa wá tàbí kò níí wá; I don’t know whether he will come or not’.

7. Bi: v. to ask: Ó bi í ní ìbéèrè; He asked him questions.

8. Bì: v.(i) to vomit: Ó bì; He vomited (ii) Ó bì mí; He pushed me (iii) to change colour: Aṣọ náà máa ń bì; The cloth always changes its colour(s) (iv) sick: Olú bì nígbà tí ó jẹ iyán ní àjẹjù; Olú was sick when he ate too much pounded yam.

9. Bo: v. to hide: Ó bo sí abẹ́ igi; He hid under the tree.

Bò: v. (i) to cover: Ó bo abọ́ náà; He covered the plate (ii) to roof: A bo ilé wa; We roofed our house (iii) to have plenty of leaves: Igi ìrókò náà bò; The ìrókò tree is dense with leaves (iv) smoother: Eruku bò mí ‘I was smothered in dust.

10. Bọ: v. to worship: Ó bọ òrìṣà; He worshipped the deity.


D

1. Dán: v. to be smooth: Ó dán; It is smooth (ii) glitter: Òrùka náà ń dán ní ìka ọwọ́ rẹ̀; The ring glittered on her finger (iii) sparkle: Dáyámọ́ǹdì náà ń dán bí iná tí ó mọ́lẹ̀ náà ṣe tàn sí i; The diamond sparkled in the bright light.

2. Dẹ: v.to hunt: Ó dẹ ìgbẹ́; He hunted for animals in the bush (ii) to incite: Mo dẹ wọ́n sí i; I incited them against him.

3. Dí: v. (i) to block: Ó dí ihò; He blocked the hole (ii) stuff up: Imú mi dí; My nose is stuffed up (iii) bar: Wọ́n dí ònà tí ó lọ sí ilé-ìwé náà; They barred the way to the school.

4. Di: v. for: Ó múra sílẹ̀ di ọjọ́ náà; He made himself ready for the day (ii) to be deaf: Etí rẹ̀ di; He is deaf (iii) run: Omi náà ti di gbígbẹ; The river has run dry (iv) bandage: Dótítà di ọwọ́ tí Olú fi pa; The doctor bandaged Olú’s cut hand.

5. Dín: v. (i) to fry: Ó dín ẹran; he fried meat (ii) to reduce: Ó dín owó ọjà; He reduced the price of the good (iii) discount: A ó dín ọ ní náírà mẹ́wàá; We shall give you a discount of ten naira. (iv) decline: Iye ọmọ ilé-ìwé tí ó wà níbí ti dín; There had been a decline in the number of students here.

6. Dó: v. (i) to settle: Ó dó sí Ìbàdàn; He settled at Ìbàdàn (ii) a vulgar language for to have sexual intercourse with: Ó dó o; He had sexual intercourse with her.

7. Dú: v. to slaughter: Ó dú u; He slaughtered it (ii) to darken/to blacken: Ó rẹ ẹ́ dú; he dyed it to a dark colour.

8. Du: v. to run: Ó du lọ; He rushed away.

9. dù: v. (i) to compete for/to scramble for: Wọ́n du ipò náà; They compete for the post (ii) to deny: Ó fi ipò mi dù mí; He denied me of my post (iii) vie: Wọ́n ń du ẹ̀bùn ipò kìíní; They were vying for first prize.

10. Dún: v. (i) to give forth a sound: Ó dún bí ìbọn; It sounds like a gun; Ìbọn náà dún; The report of the gun was audible (ii) squeak: Ilẹ̀kùn náà dún nígbà tí mo ṣí i; The door squeaked when I opened it. (iii) ring: Fóònù ń dún; The telephone is ringing.

F

1. Fá: v. to shave: Ó fá irun rẹ̀; He shaved his hair, Ó fá ọbẹ̀ dànù; He scrapped out the remaining of the soup and threw it away.

2. Fẹ̀: v. (i) to expand/to enlarge: Ó ń fẹ̀; It is expanding, Ó fẹ ihò náà; he enlarged the hole (ii) to be extensive: Ó fẹ̀; It is extensive (iii) to sit relaxedly: Ó fẹ̀; He sat relaxedly (iv) broad: Èjìká rẹ̀ fẹ̀; He has a broad shoulder (v) deep: Ohùn rẹ̀ fẹ̀; He has a deep voice.

3. Fi: v. (i) to whirl something round: Mo fi apa mi; I swung my arm round and round (ii) to dangle: Ó ń fi dorodoro; he is dangling and oscillation to and fro (iii) to be too much: Náírà kan fi í lọ́wọ́ láti ná fún mi; Even a naira is irksome to him to spend for me (iv) wave: Ó fi agboòrùn rẹ̀; He waved his umbrella.

4. Fín: v. (i) Ó fi Sheltox fin yàrá ná; He sprays the room with Sheltox (ii) to blow: Ó fin iná; He blew the fire to make it burn up (iii) to be acceptable. Ẹbọ á fin; The sacrifice would be accepted by the deities, e.g. good-luck (iv) to cut patterns on something: Ó fín igbá; He carved patterns on the calabash.

5. Fó: v. (i) to be clear: Ilẹ̀ ti fó; The ground is clear (ii) to float: Ó fó lórí omi; It floated on the river.

6. Fun: v.(i) to blow: Ó fun fèrè; He blows the whistle (ii) to play: Wọ́n fun fèrè; They played a wood wind.


G

1. Gá: v. to be tired: Ó gá mi (slang); I am tired/I give up.

2. Gàn: v. to despise: Ó gàn án; He despised him (ii) sneer: Ó gàn mí; He sneered at me.

3. Gẹ̀: v. (i) to cut: Ó gẹ irun; He cut his hair (ii) to pet: Ó gẹ̀ mí; He petted me (iii) to put something on in a jaunty way: Ó gẹ gèlè’ She puts on her head-kerchief in a jaunty way.

4. Gọ́: v. to be tired (slang): Ó gọ́ mi; I am tired.

5. Gọ: v.to lurk in hiding: Ó gọ; he lurked in hiding