Sẹ́ríkí ń góómà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Seriki n gooma

Sẹ́ríkí ń Góómà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọba mẹ́wàá ìgbà mẹ́wàá,

Ìgbà kan ò lolé ayé gbó

Sẹ́ríkí ń góómà, sànmọ́nì góómà

Ìgbà ti lọ ńlẹ̀ yìí

Ohun gbogbo ti yí padà ni wàràwàra.

Ejò ìgbà ti wọ́ kúò níbi tàná,

Ìgbà tó dé làwá ń lò ẹ̀bi wa kọ́ rárá,

Ọ̀pọ̀ èèyàn tí ò bá fẹ́ bágbà yí ló le máa jàgbùrín èṣí lọ́bẹ̀

Mo rántí lákòókò kan nílẹ̀ yí

Mo kúkú ti gbọ́njú, ń ò tí ì bàlágà ni.

Pẹ́bẹ́ lọ, pẹ́bẹ́ bọ̀ àtẹ́lẹsẹ̀ ni láti Èkó títí dé ‘Bàdàn,

Kò sí mọ́tò bẹ́ẹ̀ ni kò sí bàtà lẹ́sẹ̀

Bóòrùn ti ń pawọ ori, ...


Akinwumi feyin ti

Akinwùmi Fẹ̀yìn tì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Òréré ilé ayé rèé,

Kò sóhun tó nibẹ̀rẹ̀ tí ò ní í lópin jọjọ

Bóòrùn ti lágbára to,

Tiná ọmọ ọrara ń pa tẹru-tọmọ

Bó pẹ́ bó yá ojú ọjọ́ a rọ̀ wọ̀ọ̀,

Òòrùn a sì wọ̀ọ̀kùn, ààjin dùndùn.

Òṣúpá jèréjèré, a-mọ́-láwọ̀ bí ọ̀kinkin,

Nǹkan rìbìtì tó ń tànmọ́lẹ̀ lálẹ́.

Tí gbogbo wá fí ń tànmọ́lẹ̀ lálẹ́.

Ti gbogbo wá fi ń gbáfẹ́ orí,

Ìgbà tòṣù bá sì dàràn-mọ́jú,

Ara kálukú a sì rọ̀ wọ̀ọ̀,

A sì di wọ̀mù lórí ibùsùn.

Bó ti wù kọ́mọdé gbádùn eréṣùpá tó.


Bóṣú bá paná, eré a sì dìkàsìn,...


Ori mi ape

Ori mi àpé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orí mi àpé,

Àyà mi àkóbì-bọ

Nígbà tórí ń gbeni

Kín lòòṣà ń wò?

Orí lẹja fi í labú já,

Orí lọ̀kàsà fi í ṣe rere lálẹ̀ odò

Orí la fi í mẹ́ran láwo

Tá à kì í fì í méyìí tó léegun

Orí lobìnrin fí í yan ọkọọre ńlé ayé,

Orí lobìnrin fí í jókòó nílé ọkọ rẹ̀

Kó tóó dòpìtàn.

Orí ló ṣọba tó fi dádé owò,

Orí ló ṣèjòyè tó fi tẹ̀pá ilẹ̀kẹ̀. ...

Bi mo ba lowo

Bí mo bá lówó[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Onígbèsè mọ ọbẹ̀ẹ́ sè owó ni ò sí lọ́wọ́

Tálákà náà lè jẹ̀dọ̀ ẹran,

Ó le jẹ Ṣàkì, jabọ́dìí, jẹ ibi iké inú ẹran.

Ẹrú le ṣe bí Ọba, kò tún tẹ̀páàlẹ̀kẹ̀.

Ẹni bá ń ṣe fújà láìlówó lọ́wọ́,

Ṣe ló fẹ́ gbéra rẹ̀ sí kòtò

Èèyàn ò lówó lọ́wọ́.

Ó ní pẹ́tẹpẹ̀tẹ́ lè jábọ́

Bá a bá bẹ̀dí ọ̀rọ̀ wò,

Onitọ̀hún fẹ́ ṣu bára ni.

‘N ò nigbá, ń ò láwo’

Ẹni náà ò tí ì sọ ǹkan tí kò ní. ...


Débọ̀ Awẹ́ (2004), Ẹkún Elédùmarè Elyon Publishers, ISBN 978 2148 17 2, oju-iwe 1-20.