Àjẹsára Rubella

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Arábìrin tó ń gba Àjẹsára Rubella

Àjẹsára rubella jẹ́ àjẹsára tí a fi ń dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí ti o n fa àìsàn kan tí à ń pè ní rubella.[1] Iṣẹ́ tó múná dóko rẹ̀ ma ń bẹ̀ẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ọsẹ̀ méjì tí a bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí, àti pe ́ bíi aarundinlogorun (95%) máa ní ìí, jẹsára yìí. Orílẹ̀ èdè tí ó ní àjẹsára yìí púpọ̀ kìí ń sábà rí ìṣẹ̀lẹ̀ arun rubella tàbí ti congenital rubella syndrome. Nígbà tí àjẹsára yìí kò bá péye fún àwọn ọmọdé ní ọ̀pọ̀ ìgba, ó ṣeéṣe kí àìsàn cogenital rubella pọ̀ síi, pàápàá jùlọ bí àwọn obìrin bá ṣe ń bímọ síi láì jẹ́ wípé wọ́n gba àjẹsára tàbí kó àrùn náà. Fún ìdí èyí, ó ṣe pàtàkì kí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ju bíi 80% gba abẹ́rẹ́ àjẹsára.[1]

Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gbani nímọ̀ràn pé kí àjẹsára rubella jẹ́ ara àwọn àjẹsára tí à ń gbà lórèkóòrè. Bí gbogbo ènìyàn kò bá gba àjẹsára, ó kéré jù àwọn obìrin tí wọ́n tóó bímọ gbọ́dọ̀ gba àjẹsára yìi. Wọn kò gbọ́dọ̀ gba àjẹsára yìi fún àwọn tó lóyún tí wọn kò ní adínà àìsàn púpọ̀. Bí ó ti lé̀ jẹ́ wípé ìdá kan péré ni a nílò fún ààbó, ìdá méjì ni wón máa ń fún ènìyàn. Ìpanilára rẹ̀ ìwọnba. Wọ́n lè jẹ́ ibà, ara susú, ìrora àti pípọ́n ní ojú abẹ́rẹ́. Bí obirin ba rí ìrora, lẹ́yin gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára lẹ́yin òsẹ̀ kan tàbí méjì, kí wọ́n jẹ́ kó di mímọ̀. Àìbánilára mu rẹ̀ kọ̀ wọ́pọ̀. Àjẹsára  rubella dáwà tàbí pẹ̀lú awọn àjẹsára míràn. Àwọn àlòpọ̀ rẹ̀ pẹ̀lu àjẹsára ọ̀fìnkì ̀àti àjẹsára mumps (àjẹsára MMR) àti àjẹsára ọ̀fìnkì, àjẹsára mumps àti àjẹsára varicella (àjẹsára MMRV).[1]

Wọ́n kọkọ gba lílò àjẹsára rubella láàyè ní ọdún 1969. Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[2] Ní bíi 2009, orílẹ̀ èdè tó fi gbígba àjẹsára yíi lóòrèkóòrè sí ètò wọn jú 130.[1] Iye owó  àjẹsára MMR lójú pálí jẹ́ 0.24 USD fún ìda ́ kan ní bí ọdún 2014. Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ bíi 50 sí 100 USD.[3]

Lílò fún ìlera[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Arákùnrin tó ń gba Àjẹsára Rubella

Kí wọ́n gba àjẹsára rubella fún obìrin tí kò lóyún tàbí tí kò ní adínàn àìsàn yíi tàbí tí ó ní táítà rubella tó kéré sí 1:10. Rubella máa ń fa àìsàn tó ń dínà èémí tí ó máa ń fa ìnira ààrùn ẹ̀dọ̀fóró, àjẹsára rubella wúlò fún ìkáwọ́kò chronic obstructive pulmonary disease (COPD) àti ikọ́ efée.

Ìṣètò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ònàn méjì ni wọ́n ń gbà fún ni ní abẹ́ẹ́rẹ́ àjẹsára rubella.[1] Àkọ́kọ́ ni kí wọ́n gbàá fún gbogbo ènìyàn ti wọn kò tíì pé ogójì ọdún, ní gbígba ìdá àkọ́kọ́ kan láàrin oṣù mesaán àti méjìlá.[1] Láìjẹ́ bẹ́ kí wọ́n gbàá fún àwọn obìrin tí wọn tí tó ọjọ orí tó lè bímọ.[1]

Bí ó ti lé̀ jẹ́ wípé ìdá kan péré ni a nílò fún ààbó, ìdá méjì ni wón máa ń fún ènìyàn nígbà ti ó jẹ́pé ó máa ń wá pẹ̀lú Àjẹsára ọ̀fìnkì.[1]

Oyún[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kòyẹ kí wọ́n máa fún olóyún.[1] Síḅ̀e, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni wọ́n ti fún láìmọ wípé wọ́n wà nínú oyún tí nkan burúkú kò ṣẹlẹ̀ sí wọn.[1] Àyẹ̀wò oyún kò pọn dandan kí wọ́n tó gba àjẹsára yìi[1] Bí iye táít̀à tí a bá rí bá kéré  nígbà oyún, kí woṇ́n gba àjẹsása lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ.  O jẹ́ ìmọràn dáadáa kí obirin lọ́ra fún oyún níní lẹ́yìn ọsè merin tí wọ́n bá gba àjẹsàra.[4]

Àwùjọ àti àṣà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[2]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 1.10 "Rubella vaccines: WHO position paper.". Releve epidemiologique hebdomadaire / Section d'hygiene du Secretariat de la Societe des Nations = Weekly epidemiological record / Health Section of the Secretariat of the League of Nations 86 (29): 301–16. 15 July 2011. PMID 21766537. http://www.who.int/wer/2011/wer8629.pdf?ua=1. 
  2. 2.0 2.1 "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF). World Health Organization. October 2013. Retrieved 22 April 2014. 
  3. Hamilton, Richart (2015). Tarascon Pocket Pharmacopoeia 2015 Deluxe Lab-Coat Edition. Jones & Bartlett Learning. p. 315. ISBN 9781284057560. 
  4. Marin, M; Güris, D; Chaves, SS; Schmid, S; Seward, JF; Advisory Committee on Immunization Practices, Centers for Disease Control and Prevention, (CDC) (22 June 2007). "Prevention of varicella: recommendations of the Advisory Committee on Immunization Practices (ACIP).". MMWR. Recommendations and reports : Morbidity and mortality weekly report. Recommendations and reports / Centers for Disease Control 56 (RR-4): 1–40. PMID 17585291. http://www.cdc.gov/mmwr/preview/mmwrhtml/rr6204a1.htm.