Àjẹsára dídáranjẹ̀ ọpọlọ ti Japaníìsì
Àjẹsára dídáranjẹ̀ ọpọlọ ti Japaníìsì jẹ́ àjẹsára tí ń dáàbò bo ni lọ́wọ́ dídáranjẹ̀ ọpọlọ ti Japaníìsì.[1] Ìwọ̀n agbára àwọn àjẹsára náà láti ṣiṣẹ́ ju bíi 90% lọ. Iye àsìkò tí ààbò egbògi náà fi ń wà lára kò tíì fi bẹ́ẹ̀ ye ni dáradára, ṣùgbọ́n agbára iṣẹ́ rẹ̀ dàbí èyí tó má a ń dínkù bí àsìkò tí ń lọ síi. A má a ń fúnni yálà bí abẹ́rẹ́ tí a gún sínú ẹran ara ẹni tàbí sábẹ́ awọ ara ẹni.[1]
A gbani nímọ̀ràn láti fifúnni gẹ́gẹ́ bí ara àwọn àjẹsára tí à ń gbà lóòrèkóòrè ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àrùn náà ti jẹ́ ohun tí ń dà wọ́n láàmú. A má a ń fúnni ní ìwọ̀n egbògi náà kan tàbí méjì, èyí sí dá lé irú àjẹsára náà tí a fúnni. A kìí sábà nílò àfikún ìwọ̀n egbògi náà ní àwọn agbègbè ibi tí àrùn náà ti wọ́pọ̀. Láàárín àwọn ènìyàn tó ní àrùn kògbóògùn HIV/AIDS tàbí àwọn tó lóyún, oríṣi tí a fi kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí tí a ti pa ṣe ni a gbọ́dọ̀ lò. A gba ni nímọ̀ràn láti fún àwọn arìnrìnàjò tó ń gbèrò láti lọ káàkiri ìta-gbangba agbègbè ibi tí àrùn náà ti wọ́pọ̀ ní àjẹsára náà.[1]
Àwọn àjẹsára náà kò léwu láti lò. Ìnira àti rírẹ̀-dòdò lè wáyé ní ojú ibi abẹ́rẹ́ náà. Títí di ọdún 2015, oríṣi àjẹsára náà 15 ni ó wà. A ṣe àgbéjáde àwọn kan nípasẹ̀ ìlànà DNA aláàtùnkójọpọ̀, àwọn mìíràn nípasẹ̀ kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí tí a ti sọ di aláìlágbára, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mìíràn jẹ́ nípasẹ̀ kòkòrò afàìsàn àìlèfojúrí tí a ti pa.[1]
Àjẹsára dídáranjẹ̀ ọpọlọ ti Japaníìsì di ohun tó wà fún lílò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní àwọn ọdún 1930.[2] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé, àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[3] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ jẹ́ bíi 100 sí 200 USD fún ètò ìṣàmúlò egbògi náà lẹ́sẹẹsẹ kanṣoṣo.[4]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 "Japanese Encephalitis Vaccines: WHO position paper – February 2015.". Wkly Epidemiol Rec 90 (9): 69-87. 2015 Feb 27. PMID 25726573. http://www.who.int/wer/2015/wer9009.pdf.
- ↑ Paulke-Korinek, M; Kollaritsch, H (2008). "Japanese encephalitis and vaccines: past and future prospects.". Wiener klinische Wochenschrift 120 (19-20 Suppl 4): 15-9. PMID 19066766.
- ↑ "19th WHO Model List of Essential Medicines (April 2015)" (PDF). WHO. April 2015. Retrieved May 10, 2015.
- ↑ Hamilton, Richart (2015). Tarascon Pocket Pharmacopoeia 2015 Deluxe Lab-Coat Edition. Jones & Bartlett Learning. p. 315. ISBN 9781284057560.