Ọlátúbọ̀sún Ọládàpọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ọlátúbọ̀sún Oládàpọ̀
Ọjọ́ìbíỌlátúbọ̀sún Ọládàpọ̀
Ọjọ́ kọkàndínlógún, Oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún 1943
Ibadan, Oyo State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèỌmọ Orílẹ̀èdè Nàìjíríà
Orúkọ mírànTúbọ̀sún Ọládàpọ̀ , Ọlátúbọ̀sún Oládàpọ̀
Iléẹ̀kọ́ gígaIlé - Ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ìjọba Àpapọ̀ tí ìlú Èkó
Iṣẹ́Akéwì, Òǹkọ̀wé, Olótùú
Parent(s)Daniel Àkànjí Oládàpọ̀ , Sẹ̀gilọlá Ọládàpọ̀


Ọlátúbọ̀sún Oládàpọ̀ tí a mọ̀ sí Túbọ̀sún Ọládàpọ̀, tàbí Odídẹrẹ́ Ayékòótọ́ - Odídẹrẹ́ Asọ̀rọ̀-sọ-bótò (wọ́n bí ni ọjọ́ kọkàndínlógún Òṣu Ọ̀wẹwẹ̀,Akéwì-alohùn jẹ́ Akéwì-alohùn Yorùbá, òǹkọ̀wé, olótùú orin, atọ́kùn lórí rédíò, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, àti olùwádìí láti orílẹ̀èdè Nàìjíríà tí púpọ̀ nínú àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ń sọ Yorùbá ti wọ́n sì ń gbé ní Ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà

,[1][2]

Ìgbésí-ayé ati iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó lọ kọ́ṣẹ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ṣẹ́ àwọn olùkọ́ni Luke, Ìbàdàn níbi tí ó ti kọ́kọ́ ké ewì ní ilé ẹ̀kọ́ ní Ọdún iṣẹ́ onà 1965 (Festival of Arts), ó sun ìjálá ewì alohùn. Ó parí ẹ̀kọ́ yìí ni 1967, wọ́n sì gbé lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ St. David, Kúdẹtì, Ìbàdàn. Ó sọ pé: "St Luke ni mo ti ṣe àwárí ẹ̀bùn eré ṣiṣẹ́ mi, èyí sì ni wọ́n fi rán mi lọ sí Ilé ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ìjọba Àpapọ̀ tí Ìlú Èkó láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ dípúlómà Yorùbá lọ́fẹ̀ẹ́. Mo peregedé nínú ètò náà pẹ̀lú àmì ìpele tí ó gajù lọ.

Ní ọdún 1969, ó darapọ̀ mọ́" The Sketch newspaper", GbounGboun, ìwé - ìròyìn Yorùbá níbi tí ó ti ṣiṣé ọdún kan kí ó tó lọ sí Tẹlifíṣàn Iwọ̀-oòrùn Nàìjíríà Western Nigerian Television (WNTV), Ètò Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Iwọ̀-Oòrùn Nàìjíríà Western Nigerian Broadcasting Service (WNBS). Ó ṣe alábàpáàdé Adébáyọ̀ Fálétí, tí ó kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí-ayé rẹ̀  àti Ọmọba Adébáyọ̀ Sanda, atọ́kùn Káàárọ̀ Oòjíire àti Tiwa N'tiwa. Oládàpọ̀ fi iṣẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1977, ó sì dá iléeṣẹ́ tó ń gbé orin jáde, láti wá, ṣe Ìgbélárugẹ àti gbé àwọn olórin àti akéwì tí wọ́n lo èdè abínibí jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá

Ó ti gbé orin tó lé mọ́kànléláàdọ́ta àti igba olórin jáde. Lára wọn ni Olóògbé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ògúndáre Fọ́yánmu láti Ògbómọ̀ṣọ́, Odòlayé Àrẹ̀mú láti Kwara, Àyányẹmí Atoko wá gbowó nílé - afilù-dárà, Àlàbí Ògúndépò àti Dúró Ládiípọ̀. Àwọn àwo ewì tirẹ jẹmọ́ àwọn ewì àkọ́sọ́rí tí ó di ewì alohùn. K-12 Voices wà lára àwọn wọn akọrin ègbè Oládàpọ̀ tí olóògbé Diípọ̀ Sodiipo ṣe adarí orin .[3]

.[4]


Àwọn iṣẹ́ àpilẹ̀kọ rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọládàpò ti gbé ìwé tí kò dín ní mọ́kàndínlọ́gbọ̀n jáde, lára wọn ni àwọn ìwé tí wọ́n dábàá fún àwọn ọmọ Iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ àti sẹ́kọ́ndírì títí dé yunifásítì ní Nàìjíríà àti òkè-òkun . Òun ni òǹkọ̀wé Àròyé Akéwì Apá kìn-ìn-ín àti èkejì àti Àròfọ̀ Àwọn Ọmọdé. Àwọn eré onítàn/oníṣẹ́ rẹ̀ Ògún Lákáayé àti Ẹ̀gbádé gba ẹbùn olúborí papọ̀ ni Ìdíje èré-oníṣẹ́ Oxford University Press ni 1970.

Àwọn òye Ìbílẹ̀ tí wọ́n fi dá a lọ́la[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olóyè ni ní Ìlú Ìbàdàn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ire-Èkìtì ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì.


Àwọn ẹbí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọlátúbọ̀sún bí àwọn ọmọ tí àwọn náà jẹ́ akéwì àti onímọ̀ ẹ̀dá-èdè pàápàá jùlọ Kọ́lá Túbọ̀sún àti Yẹmí Adésànyà tí òun náà jẹ́ onímọ̀ ìṣirò àti òǹkọ̀wé.

Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Washington, Teresa N. (2005). Our mothers, our powers, our texts: manifestations of Àjé in Africana literature. Indiana University Press. pp. 276–. ISBN 978-0-253-34545-5. https://books.google.com/books?id=q_WoU41r8I4C&pg=PA276. Retrieved 29 April 2011. 
  2. Abiodun, Taiwo (2015). "Sycophants are Taking the Shine Off Ewi". The Nation. 
  3. Taiwo Abiodun, "‘Sycophants are taking the shine off Ewi poetry’", The Nation, 26 July 2015.
  4. "Abraham Olatubosun Oladapo". Dawn Commission. 25 February 2016. Archived from the original on 9 October 2016. Retrieved 9 May 2018.