Jump to content

Bacterial vaginosis

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Bacterial vaginosis
Bacterial vaginosisÀwòrán bacterial vaginosis — àwọn sẹ́ẹ̀lì inú cervix tí bacteria tó dàbí igi tẹ́ẹ́rẹ́ bò, Gardnerella vaginalis (ìtọ́sọnà).
Bacterial vaginosisÀwòrán bacterial vaginosis — àwọn sẹ́ẹ̀lì inú cervix tí bacteria tó dàbí igi tẹ́ẹ́rẹ́ bò, Gardnerella vaginalis (ìtọ́sọnà).
Àwòrán bacterial vaginosis — àwọn sẹ́ẹ̀lì inú cervix tí bacteria tó dàbí igi tẹ́ẹ́rẹ́ bò, Gardnerella vaginalis (ìtọ́sọnà).
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B96., N76. B96., N76.
ICD/CIM-9616.1 616.1

Bacterial vaginosis (BV) jẹ́ àrùn òbò tí ó maa ń wáyé tí ìdàgbàsókè kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn tí à ń pè ní bacteria bá ti pọ̀jù ní ojú ara obìnrin.[1][2] Àwọn ààmì àrùn yìí tí a maa ń sábà rí ní kí omi maa jáde ní ojú òbò tí ó sì maa ń rùn bí ẹja. Omi tí ó maa ń jáde yìí maa ń funfun tàbí kí ó ní àwọ̀ eérún. Ojú abẹ́ titani lè wáyé.[3] Yúnyún kò wọ́pọ̀.[1][3] Ní ìgbà kàn-aǹ kàn a lè maa rí àmì.[3] Àǹfàní àti ní àwọn àrùn ìbálòpọ̀ míràn bíi HIV/AIDS  maa ń pọ̀ bí ènìyàn bá ní àrùn BV.[4][5] Ó tún maa ń jẹ́ kí obìrin tí ó bá lóyún bímọ̀ lọ́jọ́ àìpé.[6][7]

Àìdúródéédé kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn tí à ń pè ní bacteria lára ni ó ń fa BV.[8][9] Ìyàtọ̀ maa ń wà ní àwọn bacterial tí ó wọ́pọ̀, tí ó sì maa ń pọ̀sí tó bí ọgọ́rún sí ẹgbẹ̀rún ni ojú ara.[1] Bacteria tí ó yàtọ̀ sí Lactobacilli maa ń wọ́pọ̀.[10] Àwọn okùnfà lè jẹ́ lílo irinṣẹ́ tí wọ́n fi ńgbomisára gbomisára, kí obìrin maa bá ọkùnrin tó pọ̀ lòpọ̀, lílo egbògi, lílo ohun tí wọ́n ń pè ní intrauterine device lára àwọn nkan míràn.[9] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò kaá sí àrùn ìbálòpọ̀.[11] Ìwádí àrùn yìí dá lórí àmi àwọn àrùn àti ṣíṣe àyẹ̀wò omi tí ó jáde láti ojú ara,  láti ri bóyá pH rẹ̀ pọ̀ ju bóṣeyẹ lọ.[1] A maa ń gbé BV àti àkóràn vaginal tàbí àkóràn Trichomonas síra wọn láìmọ.[12]

Ìtọ́jú pẹ̀lú egbògi clindamycin tàbi metronidazole. Àtún lè lo oògùn yìí  ní ìpele kẹta oyún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́pé o tún maa ń wáyé lẹ́yìn ìtọ́jú. Líló kòkòrò tí a gbà pé ó ń ṣe ìwòsàn lè ṣe ìrànlọ́wọ́. Àkò mọ̀ dájú bóyá lílo kòkòrò tí a gbà pé ó ń ṣe ìwòsàn tàbí oògun apa àkòran kòkòrò àtùnwáyé rẹ̀ wáyé ní ìpalára fún olóyún.[1][13]

BV jẹ́ àkóràn tí ó wọ́pọ̀ jùlọ ní àwọn obìrin tí o tí tó ọjọ orí àtilèbímọ.[9] Ìpín ọgọ́rún àwọn tí àkóràn yìí ń kóbá ní ìgbàkugbà yàtọ̀ láàrín 5% àti 70%.[4] BV jẹ́ àrùn tó wọ́pọ̀ ní  Africa pẹ̀lú díẹ̀ ní  Asia àti Europe.[4] Ní  United States ó maa ń ṣàkóbá fún bíi ìdá ọgbọ̀n nínú ìpín ọgọ́rún àwọn obìrin tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàrin mẹ́rìndínlógún àti ọ̀kàndínláàdọ́ta.[14] Ìwọn yàtọ̀ láàrín àwọn ẹ̀yà sí ẹ̀yà ní orílẹ̀ èdè.[4] Wọ́n ti ṣàpèjúwe àwọn àmì tí ó jọ BV nínú ìtàn, àkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ wáyé ní ọdún 1894.[15]

Àwọn àmì àti àpẹẹrẹ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ààmì àrùn yìí tí a maa ń sábà rí ní kí omi maa jáde ní ojú òbò tí ó sì maa ń rùn bí ẹja. Omi tí ó maa ń jáde yìí maa ń funfun tàbí kí ó ní àwọ̀ eérún. Ojú abẹ́ titani lè wáyé. Ní ìgbà kàn-aǹ kàn a lè maa rí àmì.[3]

Omi ojú ara yìí maa ń eti òbò ká tí kò sì ń ni ènìyàn lára tàbí kí ó pọ̀n ròdòròdò, bí ó tilẹ̀ jẹ́pé yúnyún lè wáyé. Ní ìdàkejì, omi ojú ara tòótọ́ maa ń yàtọ ní ìgbà nkan oṣù—Ọ̀sẹ̀ méjì kí nkan oṣù tó bẹ̀ẹfẹ. Àwọn onímò kan sọ wípé a lè maa rí àmì ní ìdajì àwọn obìrin tí ó bá ràn,[16]  àwọn míràn jìyàn wípé àìṣè ìwádí tónítóní ni èyí.[17]

Microbiota ojú ara tí kò lárùn ní àwọn ẹ̀yà tí kò kìí ṣe okùnfà àmì, àkóràn tàbí àkóbá fún oyún. Àwọn ẹ̀yà Lactobacillus ni ó gba ìlẹ̀ ká.[10][18]  À ń ṣàpèjúwe BV pẹ̀lú àìdúródéédé microbiota òbò pẹ̀lú díndínkù iye lactobacilli. Àkóràn nị́e pẹ̀lú iye bacteria, a sì gbàgbọ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkóràn  maa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Gardnerella vaginalis tí ó maa ń fa biofilm tí ó maa ń jẹ́ kí opportunistic bacteria dàgbà.[2][19]

Ìkan lára okùnfà ìdàgbàsókè ni lílo irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń gbomisára, tí à ń pè ní douching, tí ó maa ń fa àìdúródéédé kòkòrò tí ó ń ṣe ara lánfànì lè fa ìdàgbàsókè BV.[20] U.S Department of Health and Human Services kò fi taratara gba lílo irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń gbomisára, tí à ń pè ní douching wọlé, àti fún ìdí èyí àti òmíràn.[20]


BV maa ń ṣe okùnfà àrùn abẹ́ inú, HIV, àwọn àrùn ìbálòpọ̀ àti àwọn tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí àti oyún. O ṣeéṣe kí àwọn ẹni tí kò lé ṣe àṣepọ̀ ní àrùn bacterial vaginosis.[2]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 Donders, GG; Zodzika, J; Rezeberga, D (April 2014).
  2. 2.0 2.1 2.2 Clark, Natalie; Tal, Reshef; Sharma, Harsha; Segars, James (2014).
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 "What are the symptoms of bacterial vaginosis?". 2013-05-21.
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 Kenyon, C; Colebunders, R; Crucitti, T (December 2013).
  5. Bradshaw, CS; Brotman, RM (July 2015).
  6. Queena, John T. .; Spong, Catherine Y; Lockwood, Charles J., editors (2012).
  7. "What are the treatments for bacterial vaginosis (BV)?"
  8. Bennett, John (2015).
  9. 9.0 9.1 9.2 "Bacterial Vaginosis (BV): Condition Information".
  10. 10.0 10.1 Nardis, C.; Mastromarino, P.; Mosca, L. (September–October 2013).
  11. "Bacterial Vaginosis – CDC Fact Sheet".
  12. Mashburn, J (2006).
  13. Othman, M; Neilson, JP; Alfirevic, Z (24 January 2007).
  14. "Bacterial Vaginosis (BV) Statistics Prevalence". cdc.gov.
  15. Borchardt, Kenneth A. (1997).
  16. Schwebke JR (2000).
  17. Forney LJ, Foster JA, Ledger W (2006).
  18. Petrova, Mariya I.; Lievens, Elke; Malik, Shweta; Imholz, Nicole; Lebeer, Sarah (2015).
  19. Patterson, J. L.; Stull-Lane, A.; Girerd, P. H.; Jefferson, K. K. (12 November 2009).
  20. 20.0 20.1 Cottrell BH (2010).