Lawrence Anini

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Lawrence Nomanyagbon Anini (c. 1960 – March 29, 1987) [1] Jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàjíríà tí ó jẹ́ adigun-jalè aṣèrùbàlú ilẹ̀ Ìbìní (Benin) ní ọdún 1980s, òun pẹlú abẹ́sinkáwọ́ rẹ̀ Moday Osunbor. Ìjọba mú Lawrence Aníní látàrí àwọn ìwà ìbàj̣ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì paá.

Ìgbésí Ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Lawrence Aníní ní abúlé kan tí kò ju ǹkan bí ogún ibùsò lọ láti Ìlú Bìní (Benin) tí ó jẹ́ olú ìpínlẹ̀  Ẹdó (Edo State). Aníní, ni gbogbo ènìyàn tún pè ní 'The Law' tàbí 'Obvigbo'. Ó ṣe àtìpo  wá sí ilè Ìbìní nígbà kékeré rẹ̀, tí ó sì ḳọ́ bí wọ́n ṣe ń wa ọkọ̀ lẹyìn èyí ni ó di awakọ̀ Agbérò (Taxi Driver) tó yanrantí. Ó di gbajú-gbajà ní ibùdókọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó lè darí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ gànfẹ̀ ọlọ́kọ̀ náà. lẹ́yìn-ò-rèyìn, ó bèrè iṣẹ́ tí ó lodì sí òfin, tì ́ó sì di ọ̀daràn nípa bíbá àwọn ọdaràn ènniyàn bi: àwon ikọ̀ bàbá ìsàlẹ̀ àti àwọn adigun-jalè kó ẹrù òfin. Kò pẹ́, ló pinnu láti dá dúró gégé bíi ọ̀gá láyè ara rẹ̀ tí ó sì fa àwọn ènìyàn bíi : Monday Osunbor, Friday Ofege, Henry Ekponwan, Eweka and Alhaji zed zed tàbí Zegezege mọ́ra láti bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀. Wọ́n kọ́kọ́ bèrè níbi jíja ọkọ̀ gbà, alọ́ni-lọ́wọ́gba ińú ọkọ̀-èrò. lẹ́yìn èyí ni ó pẹ̀ka rẹ̀ dé abúlé àti ìletò pẹ̀lú gú́sù àti àríwá ilẹ̀ Ìbìní.

ìkúnlápá tí àwọn Ọlọ́pàá ń ṣe fún ọ̀gbẹ́ni Aníní ni a gbàgbọ́ wípé ó jẹ́ kí ìwà ìdún-kokò àti ìṣẹ̀rùbàlú rẹ̀ ó peléke sí nị́ 1986, nígbà tí ọwọ́ tẹ méjì lára àwọn abẹ́ṣin-káwọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì fojú balé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ sì fì ìyà tó tọ́ jẹ wọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá nípa fí fìdí òkodoro ẹjọ́ múlẹ̀ nílé ẹjọ́ láì wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí Aníní ti fún wọn. Látàrí ìwà àgbẹ̀yìn-bẹbọ-jẹ́ tí àwọn ọlọ́pàá hù sí yìí ló jẹ́ kí ó fa ìbínú yọ ní oṣú August 1986 nípa ṣíṣàkọlù sí ilé ìfowó-pamọ́ ní èyị́ tí ọlọ́pàá kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ (Nathaniel Egharevba)  àti àwọn mélòó kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú àkọlù náà ní fọná-fọnṣu. Nínú oṣù yí kan náà ni àwọn ọlọ́pàá méjì kan náà tún tókú lá lọ́wọ́ ìbọn Aníní nígbà tí wón ń gbìyànjú láti da ọkọ́ rẹ̀ dúró ní ojú pópó. láàrín oṣù mẹ́ta, Aníní ti gbẹ̀mí lẹ́nu ọlọ́pàá mẹ́sàán.

Ìlọ́nilọ́wọ́-gbà Aníní[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínú àkọlù tí ó wáyé ní August 1986,  Aníní àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kolu ilé ìfowó-pamọ́ First bank, Sabongida-Ora, níbi tí wọ́n ti kó ẹgbẹ̀rún méjì #2,000. ṣùgbọ́n bí owó tí wọn jíkó yìí kò ṣe tó mutí fún wọn nà́́à ni wọ́n pa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn nínú àkólu náà pèlú. Nígbà tí ó di oṣù September 6 ọdún yìí kan náà ikọ̀ Aníní já ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Pijó 504 (Peugeot 504) kan gbà lọ́wọ́ ọ̀gbẹ́ni Albert Otoe tí wọ́n sì ṣekú paá tí wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ pamọ́ síbìkán, ẹni tí ó jẹ́ awakọ̀ igbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá pátápátá (Assistant Inspector of Police), Christopher Omeben. lẹ́yìn  ǹkan bí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ikú awakọ̀ yìí ni wọ́n tó rí òkú rẹ̀ ní ibùsò méèdógún ní òpópónà márosẹ̀ Benin sí Agbo.  Ní ọjọ́ kejì tí Aníní àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ gba ọkọ̀ ọgá ọlọ́pàá yìí ni ó tún fi ọkọ̀ Pàsáàtì tí ó jẹ́ wípé ó já gbà ló tún fi já ọkọ̀ Pijó 504 mìíràn gbà nítòsí ilé àjọ FEDECO, ní Bìní.

Ọjọ́ meji lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yí, àwọn ikọ̀ Aníní pa ọlọ́pàá méjì ní ìjọba ìbílẹ̀ Orhiowon ní ìpínlẹ̀ náà. Nínú oṣù yí bákan náà, àkọlù mẹ́ta ó̀tọ̀ọ̀tọ̀ tún wáyé ní eyi tí ó ń tọ́ka sí iṣẹ́ ọwọ́ Aníní, lára àwọn tí wón gbẹ́mìí mì  nínu akolú náà ni Frank Unoarmi, ẹni tí ó ṣíṣẹ́ pẹ̀lú ìwé ìròyìn Nigerian Observer, Ìyáfin Rèmí Ṣóbánjọ, onímọ ìjìnlẹ̀ Ìṣirò, àti bí wọ́n ṣe tún já ọkọ̀ Mèsí-Olóyè (Mercedes Benz kan tí ó jẹ́ tí Ọba Ovie tí ìlú Ugheli. Ṣáájú kí oṣù Sepetember 1986 ó tó tẹnú-bepo, Aníní ya wọ ilé epo kan ní òpópónà Wire Road, Bìní níbi tí ó gba owó ọjà tí wọ́n tà lọ́jọ́ náà, tí ó sì yìnbọn fún ọ̀kàn lára àwọn òṣìṣé ibẹ̀, lẹ́yìn èyí ni ó bèrè sí ní fọ́n owó fún àwọn ènìyàn kí won lè jẹ́ kó rọ́nà lo.Àkọlù Aníní tí ó paba-n-barì jùlọ ni èyí tí ó wáyé ní àyájọ́ ọ̀jọ̀ Òmìnira Ilẹ̀ Nàìjííríà (October 1,1986) nígbà tí Kọmíṣánà àwọn Ọlọ́pàá fún ìpínlẹ̀ Ìbìní Casmir Igbokwe nígbà tí ikọ̀ Aníní dènà dèé tí ó sì kù gín-ń-gín kí wọ́n fi ọta ìbọn já imú kọmíṣánà náà dànù. Ṣùgbọ́n ewú  hu ọ̀gá ọlọ́pàá náà pẹ̀lú egbò oríṣiríṣi lára rè.Bákan náà, ṣáájú àkọlù sí ọ̀gá ọlọ́pàá yìí ni àwọn ọmọlẹ́yìn  Aníní ti fìbọn gbẹ̀mí ọlọ́pàá kan láàrín ìgboro Bìní.

"Òfin" gẹ́gẹ́ bí ìnagijé rẹ̀, ó gbìyànjú láti sá mọ́ àwọn ọlọ́pàa ́lọ́wọ́ pẹ̀lú bí ó ṣe fi ọkọ̀ rẹ̀ sí àwà-sẹ́yiǹ láti Agbo (Delta State) títí dé ìgboro Ìbìní (Edo State). Bákan náà ní oṣù October 21 ọdún 1986, Aníní àti àwọn ẹ̀gbẹ́ adigunjalè rè gba ẹ̀mí akọ́ṣé-mọṣé oníṣègùn òyìnbó kan ọ̀gbẹ́ni A.O Emojeve nígbà tí ẃn yinbọn fun nị agbègbè Textile Mill ní ìgboro Ìbìní. Síwájú síi, wón digun-jalé ní ilé ìfowó-pamọ́ African Continental Bank tí wọ́n sì kó ǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdín-láàdọ́ta náírà #46,000. Ní ọjọ́ kejì ̀akọlù yìí, Aníní sọ ara rẹ̀ di bàbá kérésì pèlú bí́ ó ṣe ń fọ́n owó fún ọ̀pọ̀ àwọn bàbá-lójà àti ìyá-lọ́jà ní abúlé kan tí ó wà ní ìtòsí́ Ìbìní. Báyìí ni òkìkí Aníní bère sí ń tàn ká bí ìràwọ̀ ọjọ́ kẹrìnlá, tí ó sì fẹ́rẹ̀ tẹ̀wọ̀n ju ti Ishola Oyènúsì ìgárá ọlọ́ṣà tí ń kólé ọba lójú-mọmọ, tí ò lògbà ní 1970s àti ti ìgárá ọlọ́ṣà Youpelle Dakuro, tí ó jẹ́ arógun sá ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjííríà kan tí ó wà nídìí ìdigun-jalè ọ̀sán gan-gan kan tó wáyé ní ìgboro Èkó ní 1978, nínú àkọlù-kọgbà tí ọlọ́pàá méjì ti sọ èmị́ wọn nù. Bákan náà ni a tún gbọ́ wípé Aníní kọ oríṣiríṣi lẹ́tà sí àwọn ilé-iṣé ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ tí ó sì ń dínbọ́n gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú lạ́ti ṣàfihàn ìwà ìdigun-jalè rẹ̀ gbogbo.

Olórí orílẹ̀-èdè ìgbà náà láyé ológun Ọ̀gágun Ibrahim Babangida wá ń kọminú púpọ̀ lórí bí adigun-jalè afẹ̀mí ṣòfò Aníní ṣe ń da ìlú rú, ló bá pàṣe pé kí àwọn ọmọ ogun ilè ó ṣe àwárí rè tòun tàwọn ìsọmọgbè rè ní eye-ò-sọkà. Báyìí ni àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣe ìwádìí ọ̀tẹlèmúyẹ́ lóríṣiríṣi ní ìpínlẹ̀ Bende tí àwọn afurasí náà ń gbé lásìkò náà. Lásìkò yìi gan ni gbogbo Nàìjííríà wá wà ní ìbẹ̀rù tí wọ́n sì ń kọminú lórí àwọn adigun-jalè náà pẹ̀lú iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

pẹ̀lú gbogbo ìdààmú-dàabo àwọn ọlọ́pàá lórí mímú àwọn ìgárá ọlọ́s̀à náà ló já sí pàbó. Ẹ̀wẹ̀, ń ṣe ni wọ́n tún gbèrú si. Sị ìyàlẹ́nu, ń ṣe ni àwọn ará agbègbè Bẹ́ndẹ̀ ṇ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìgárá ọlọ́ṣà náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí apá ìjọba kò lé ká, nígbà tí Olórí orílẹ̀-èdè Ọgágun Ibrahim Babangida kọjú sí Ọ̀gá àgbà àwọn ọ́lọ́pàá yán-yán  Etim Inyang lẹ́yìn ìpàdé àpéjọpọ̀ àwọn ológun ìyẹn Armed Forces Ruling Council pé ọ̀gbẹ́ni, Aníní tí mo ní kí o mú fún mi ń kọ́?

Lásìkò yìí gan ni àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé àtèjáde ojoojumọ́ ilẹ̀ Nàìjííríà bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé àwọn ìròyìn ọ̀lọ́kan-ò-jọ̀kan nípa Aníní tí wọ́n sì ń pèé ní oríṣiríṣi orúkọ kànkà-kànkà gẹ́gẹ́ bí: 'Ìpèníjà Aníní', 'Ìròyìn Aníní', 'Òkodoro Aníní', 'Ọ̀gbẹ́ni náà-Lawrence Aníní', 'Aníní Ìbẹ̀rù' 'Aníní Jack the Ripper' àti 'Ọ̀gbẹ́ni Aníní: Robin Hood ti Bendel', àti bẹ́ẹ̀ bẹ́è lo. Kódà, ìwé ìròyìn The Guardian bèrè wípé : Ǹjẹ́ wọ́́n ha lè rí ọ̀gbẹ́ni Òfin tí ń jẹ́ Aníní mú bí?

BÍ wọ́n ṣe mú Aníní[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn ò rẹ̣yìn Superintendent Káyọ̀dé Uanreroro ló ṣakin, ó sì fi wa egbò dẹ́kun sí ìwà ìṣẹ̀rùbàlú Aníní àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ọ̀gá ọlọ́pàá yì mú ògbóntagì ọlọ́ṣ̀a yìí ní December 3, 1986, ní ojúlé kẹrìndínlógún òpópónà Oyemwosa, tí ó dojú kọ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀r̀ẹ Iguodala, Bìní. Anini ni o wa pelu awon obinrin mefa. Awon olopaa ya wo inu ile ti Anini fi se ibuba naa latari ofofo ti awon aladuugbo se fun awon olopaa. Oga olopaa naa lo mu Anini pelu iko awon olopaa mewa pere. Oga olopaa naa lo kan ilekun iyara ti Anini wa ti oun naa si si lekun woorowo leni ti o wo pata nikan. Won mu Anini sikun ti oun naa ko si bawon janpata pupo, sugbon ohun ti a gbo ni wipe ore-binrin re kan lowo si bi awon olopaa se ri mu. Obinrin naa ti ba awon ogun ati awon nkan agbara re kan je saaju ki awon olopaa to de. N se ni oro naa dabi ti Samsoni inu bibeli ni. Iyalenu lo je fun Anini fun ra re bi won se ba lojiji, ti oun naa si fe da bi ogbon nigba ti won beere lowo re ibi ti Anini wa, oni: "Ahh, o ti sa pamo si abe ibusun ni iyara keji"  bi o se so bayi tan o gbiyanju lati koja lara oga olopaa naa, sugbon iyen da lowo ko nigba ti o kan oga olopaa naa ni igbo, amo asise nla gbaa ni fun. Uanrenroro sare fi ese te atanpako ese re mole, o fa ibon yo o si ro bajinatu si ni koko-se. Anini gbiyanju lati bo mo won lowo sgbon awon olopaa toku mu so bi eran ti won si n yin ibon fun ni kose-kose debi wipe kokose re ohun fere ja kuro lara re latari ojo ibon ti o baa nibe. Anini kee tirora tirora, awon olopaa tun wa beere lowo re wipe : " Se iwo ni Anini?" oun naa wa fesi wipe : "Wo omo iya mi, mi o ni tan e, mi o si ni paro fun e,emi ni Anini.

Lati ibi ni won ti mu lo si ile agbara awon olopaa ni bi ti apase awon olopaa pata pata ti n duro lati fidi ododo re mule pe looto ni won ri Anini mu. fu asiko ti Anini fi wa ni ahamo awon olopaa, ede adamodi geesi ni o fi n soro tori ko lo si ile-iwe kankan. Bayii ni o bere si ni tu awon asiri kan fun awon olopaa nipa awon ise laabi ti oun ati awon iko re ti seyin, o tun fidi re mule wipe igbakeji re Osunbo lo yinbon fun Oga awon olopaa ipinle naa tele iyen Akagbosu

Won gbe Anini lo si ogba itoju awon ologun latari ojo ibon ti won ro si ni koko-se, leyi to sokunfa ki wo bi won se ge ese naa kuro. won ri igbakeji re Osunbof naa m ni ojo aje ose keji nigba ti won tu gbogbo ibuba awon olosa naa. Won ri nkan ogun to lagbara orisirise ko paa pa julo eyi ti Anini ma n wo sidi re nigba ti o ba digun-jale lowo. O seni laanu wipe Anini Iberu to n ko jini-jini oun iberu ba gbogbo ilu wa deni ti o sunkun bi omo owo nigba ti won fi si ahamo ti ko si ni anfani lati tawo si awon ohun ija oloro re, ti o si n jewo awon ese re bi oponu. O ya opo eniyan lenu wipe Anini le di ko tonkan loju muju-muwa.

Bí àṣírí Ìyámù àti àwọn mìíràn ṣe tú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Laipe ti owo te Anini ati awon isongbe re, n se ni won bere si ni tu awon asiri ikoko to wa laarin awon ati awon olopaa to je agbode-gba fun won bi won se n tu awon asiri ise abenu olopaa fun awon ni ipinle naa ti won si tun n gba awon ni imoran ona ti awon le gbe ise laabi awon gba ti owo ko fi ni ba won rara. Anini daruko oga olopaa Iyamu gege bi eni ti olopaa to ma n ko ibon ati awon ohun ija oloro miiran fun awon lasiko ise buburu won.

Anini ko sai menu baa wipe Iyamu ma n dara po mo won lati pin ninu gbogbo ohun ti won ba ri ko bo lati ibise won. O te siwaju nipa bi Iyamu se gbimo lati pa Igbakeji alamojuto agba awon olopaa iyen Christopher Omeben, ni eyi ti o je pe awako re Otue ni won ri pa. Sergent Iyamu ti Anini ati awon omoleyin re ma n saba pe ni 'Baba' ni o ti ko ile alaruru si igboro Benin pelu orisirisi ohun to ti ri pin ninu gbogbo ohun ti awon olosa naa ti n ri ko lateyinwa.

Ìgbẹ́jọ́ àti ìdájọ́ iḱú Aníní[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n gbe Anini dé ilé ẹjọ́ lórí aga arọ látàrí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti wọ́n ba gé kúrò títí wọ́n fi parí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Iyamu ní tirẹ̀ jiyàn wípé òun kò mọ Anini rí débi wípé òun yóò ba dòwò pọ̀, ṣùgbọ́n Anini kọ̀ jálẹ̀ wipe iró ni Iyamu ń pá, ó sìn bú Iyamu wipe: 'òpùrọ́ aláìlójúgì. Ṣùgbọ́iẹ́ígbà Bíe ọ́n ṣrììdájọ́ò ìí, íwájọ́niwájọ́ adajìdíamẹ̀s úlẹ̀-Aípéeẹjọ́leóeóò tùlọa í álegbàgbéebí nọ́nigáońo ọ̀rọ̀iìwàtọ̀daràtiọí ̣pílẹ̀l- èdèàáìí, Adájọ́ wípé òóòá ẹ́íìrántí júburú-án aọrỌjọ́reọkàndínlógúA ninṣùyoẹ diọdúi male gbagbe ti won ba n sọ́no iwẹ̀yìnarọn ni àgbá ede yii, sugbon yoo je iranti to buru julo. Mo si mo wipe perete tabi ki a ma ri eni ti yoo fun omo re ni iru Anini yii. Ojo kokandinlogbon, osu keta odun 1987 (March 29,1987) ni won fi eyin won ti agba.

Àwọn Ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. P E Igbinovia (Spring 1988). "Wound Ballistics, Reasonable Force and Anini's Incapacitation". International Journal of Comparative and Applied Criminal Justice 12 (1): 131–135. doi:10.1080/01924036.1988.9688886. https://www.ncjrs.gov/App/publications/Abstract.aspx?id=116195.