Luther Vandross
Luther Vandross | |
---|---|
Luther Vandross ní Madison Square Garden ti New York City ní October 5,1988. | |
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Luther Ronzoni Vandross |
Ọjọ́ìbí | New York, New York, United States | Oṣù Kẹrin 20, 1951
Aláìsí | July 1, 2005 Edison, New Jersey, United States | (ọmọ ọdún 54)
Irú orin | R&B, soul, adult contemporary, soft rock, soul jazz, quiet storm |
Occupation(s) | Singer-songwriter, Musician, record producer |
Instruments | Vocals, Keyboards |
Years active | 1968–2005 |
Labels | Cotillion, Epic, Virgin, J, Legacy |
Associated acts | Change, Chic, Dionne Warwick, Mariah Carey, Richard Marx, Whitney Houston |
Website | luthervandross.com |
Luther Ronzoni Vandross tí wọ́n bí ní ogúnjọ́ oṣù Kẹ́rin ọdún 1951, (April 20, 1951 – July 1, 2005) jẹ́ akọrin , olùgbé-orin jáde àti àkọsílẹ̀ ìgbàsílẹ̀ ará Amẹ́ríkà[1]. Nígbà ayé rẹ̀, Vandross ta àwon orin tó ju mílíọ́nù márùnlélógún lọ[2] bẹ́ẹ̀ sì ni ó gba Ẹ̀bùn Grammy mẹ́jọ[3] nínú wọn ní Best Male R&B Vocal Performance ni ẹ̀mẹrin. Ó gba ẹ̀bùn Grammy mẹ́rin ní ọdún 2004 nínú wọn ni Grammy Award for Song of the Year fún orin "Dance with My Father",[4] tó kọ pẹ̀lú Richard Marx.
Luther Vandross jẹ́ akọrin tó múná dóko nítorí náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọrin bíi tirẹ̀ tó dángájíyá fẹ́ kí ó bá wón ṣe àwo orin pọ̀[1] , lára wọn ni Diana Ross , David Bowie , Donna Summer àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.Luther Vandross ṣe aláìsí ní ọjọ́ July 1 2005 , látàrí àìsàn ọkàn.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 <ref name="Crumpton 2021">Crumpton, Jerome (2021-06-08). "CELEBRATING LUTHER VANDROSS FOR BLACK MUSIC MONTH". myv949.com. Retrieved 2021-06-29.
- ↑ "Luther Vandross". AskMen.com (UK Edition). Archived from the original on 2013-06-02. Retrieved 2006-12-02.
- ↑ "Vandross' Funeral Soulful and Powerful". Yahoo! News. July 8, 2005. Retrieved 2006-12-02.
- ↑ "Obituary: Luther Vandross". BBC News. July 1, 2005. Retrieved 2006-12-02.