Nassima Saifi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Nassima Saifi (ọjọ́ ọ̀kàndínlọ́gbọ̀n Oṣù Kẹ́wá ọdún 1988) jẹ́ eléré ìdárayá àwọ́n tí kò lẹ́sẹ̀ láti orílẹ̀ èdè Algeria tí ó díjé ní ìpele júju irin F58. Ó maa ń sába ju irin ti ọlọ́nàn jínjìn àti ti kúkurú, Saifi ti gba àmì ẹ̀yẹ wúrà ti Paralympic lẹ́ẹ̀méjì àti àmì ẹ̀yẹ wúrà gbogbo àgbáyé lẹ́ẹ̀mẹ́ta

Ìgbésíayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí saifi ní ìlu Mila ní orílẹ̀ èdè Algeria ní ọdún 1988.[1] Wọ́n bíi pẹ̀lú ara pípé, ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1998 ni ó sọ ọ́ di alábọ̀ ara tí wọ́n fi gé ẹsẹ̀ rẹ̀ .[2] Bàbá rẹ̀ ṣe àkíyèsí wípé ó lè fẹ́ ṣeré ní ìgbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá dilẹ̀, ó sí gbàá ní ìyànjú wípé kí ó mú eré ìdárayá gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ àṣelà. Ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eré ìdárayá àwọn tí kò lẹ́sẹ́ ní Mila.[3]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Saifi, Nassima". Paralympic.org. Retrieved 4 September 2016. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  2. "Saifi, Nassima". IPC. Retrieved 4 September 2016. 
  3. "Nassima Saifi, championne du monde du lancer de disque" (in French). DjaZairess. Retrieved 19 February 2017.