Jump to content

Peter King

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Peter King (afrobeat))

Peter King Adéyoyin Osubu tí a mọ̀ sí Peter King jẹ́ gbajú-gbajà olorin tó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Nàìjíríà, tí ó mọ̀ nípa ìlò onírúurú irinṣẹ́ èlò orin.

Lọ́pọ̀ ìgbà, ó fẹ́ràn láti máa fọn fèrè, tí a mọ̀ sí Saxphone, tí ó sì ma fi ń gbé orin jáde àti ìlù Jáàsì fún ìgbádùn àwọn tó ní ìfẹ́ sí irúfẹ́ orin rẹ̀. Peter King gbàjúmọ̀ púpọ̀ láàrín àwọn àrá ilẹ̀ Europe àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ju Ilẹ̀ wa Nàìjíríà lọ pẹ̀lú orin Mìlíkì tó ń kọ fáwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

Wọ́n bí Peter King ní ọdún 1938 ní ìlú Enugu, ní ìwọ̀-oòrùn gúúsù, ilẹ̀ Nàìjíríà, ó dàgbà sí Ìlú Lọ́kọ́ja, ìlú Èkó àti Port Harcourt. Ní ọdún 1957, Peter King, darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ olórin Roy Chicago ní Ìlú Ìbàdàn, nibi tó ti ń lu àwọn onírúurú Ìlú àti éròjà orin tó dárà fún ìgbádùn àwọn to m'ayé jẹ.

Ní ọdún 1961, ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Orin ní ìlú London àti Ilé Ẹ̀kọ́ Trinity. Ní ìlú London yìí ni King ti darapọ̀ mọ́ Báyọ̀ Martins ẹni tó yan ìlù láàyò àti ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Mike Fálànà tó jẹ́ afun-fèrè. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yí wá dá ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí African Messangers.

Ẹgbẹ́ African Messengers yí máa ń kọrin ní àwọn ibi àkànṣe ayẹyẹ àti ibi ìgbafẹ́. Wọ́n sì tún ń ṣe ègbè fún àwọn gbajúgbajà àti ìlú mọ̀ọ́ká olórin bíi, The Four Tops, The Temptations àti Diana Ross.

Ẹgbẹ́ African Messengers ṣe àwo orin tó tó bíi máàrún-dín-láàdọ́ta. King, tún da ẹgbẹ́ míràn sílẹ̀ tí ó pè ní The Blues Builders, tí wọ́n sì rin ìrìn àjò káàkiri Ilẹ̀ Europe àti apá Ìlá-oòrùn adúláwọ̀.

Peter King àti ẹgbẹ́ olórin rẹ̀ padà sí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1969 tí wọ́n sì kọrin láàrín ìjà ogun abẹ́lé tó bẹ́sílẹ̀ lákòókò náà ní ìlú Nàìjíríà.

Ní ọdún 1971, King padà sí ìlú London, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí Ìlú Europe, Amẹ́ríkà àti Japan pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó pè ní Shango. Ó tún ṣe agbátẹrù àwọn elégbè orin fún Boney M, nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n lọ kọrin níbi ìrìn àjò káàkiri sí orílẹ̀-èdè Europe ní ọdún 1977. Bẹ́ẹ̀ náà ló tún ṣe àwo orin mẹ́sàn-án míràn láàrín ọdún 1975 àti 1978. Ó kọ̀wé orin ìgbà ló dé fún àwọn òṣèré àti ilé iṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀nu.

Ní ọdún 1979, ẹ̀wẹ̀, King padà si orílè-èdè Nàìjíríà o sì dá ẹgbẹ́ P. K silẹ̀. Ó ń ṣe àkójọpọ̀ orin fún èrè Orí ìtàgé, ó wá tún ṣe àwo orin mẹ́ta kún àwọn àwo orin rẹ̀.