Jump to content

Ẹ̀yà ara ifọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti ÀWỌN Ẹ̀YÀ ARA IFỌ̀)

Ẹ̀yà ara ifọ̀ ni àwọn ẹ̀yà ara tí a máa ń lò fún gbígbé ìró ifọ̀ jáde. Bí a bá sọ pé "Mo fẹ́ jeun", àwọn ẹ̀yà ara kan wà láti orí dé ikùn wa tí wọ́n jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́ papọ̀ láti gbé ìró yìí jáde ní ẹnu. Àwọn ẹ̀yà ara bẹ́ẹ̀ ni à ń pè ní ẹ̀yà ara wọn ifọ̀. Ìró tí àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí gbé jáde ni à ń pè ní ìró ifọ̀.

Ẹ̀yà ara ifọ̀ tí a le fojú rí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ara tí a le fi ojú rí nípa lílo dígí tàbí nǹkan mìíràn. Àwọn ni:

  • Ètè òkè
  • Ètè ìsàlè
  • Eyín òkè
  • Eyín ìsàlẹ̀
  • Èrìgì
  • Àjà ẹnu
  • Ahọ́n
  • Àfàsé
  • Àjà ẹnu, abbl.

Ẹ̀yà ara ifọ̀ tí a kò le fojú rí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ tí wọ́n wà láti inú ikùn sí ọ̀fun wa tí a kò le fojú rí. Àwọn:

  • Ẹ̀dọ̀ fóóró
  • Kòmóòkun
  • Ẹ̀ka kòmóòkun
  • Gògóńgò
  • Káà ọ̀fun
  • Tán-án-ná, abbl.

Àpèjúwe ìrísí àti ipa àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ kọ̀ọ̀kan

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1. Ẹ̀dọ̀-fóóró: Inú ẹ̀dọ̀-fóóró ni èémí tí à ń lò fún ìró ifọ̀ ti ń tú jáde.

2. Ẹ̀ka kòmóòkun: Ẹ̀ka kòmóòkun ni ẹ̀ka méjì tí wọ́n wọ inú ẹ̀dọ̀-fóóró láti ara kòmóòkun. Wọ́n jẹ́ ọ̀nà fún èémí láti gbà kọjá wọ́ inú gògóńgò.

3. Gògóńgò: Orí kòmóòkun téńté ni gògóńgò dábùú lé ní ọ̀fun. A le rí ìta gògóńgò ní ọ̀fun wa.

4. Tán-án-ná: Inú gògóńgò ni tán-án-ná wà. Inú rẹ̀ ni ìdíwọ́ ti ń ṣẹlẹ̀ sí èémí tó ń bọ̀ láti inú ẹ̀dọ̀ fóóró.

5. Àlàfo Tán-án-ná: Ó jẹ́ ààyè tó wà láàrin Tán-án-ná tí èémí àmísóde ti ń yí padà di ìró, tí yóò sì gbà jáde sí ọ̀nà ọ̀fun. Ipò méjì ni àlàfo Tán-án-ná le wà tí a bá gbé ìró jáde; ipò ìmí àti ìkùn.

7. Ahọ̀n: Ahọ̀n jẹ́ ẹ̀yà ara tí ó ṣe pàtàkì púpò nínú gbígbé ìró ohùn jáde, ọ̀nà mẹ́ta pàtàkì ni a le pín ahọ́n sí; iwájú, àárín, àti ẹ̀yìn. Ìró ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni à ń gbé jáde tí a bá lo ọ̀kọ̀ọ̀kan apá yìí.

ÀFIPÈ

Èyí ni àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ tí wọ́n ń kópa nínú pípé ìró èdè jáde. Àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ àfipè bẹ̀rẹ̀ láti òkè àlàfo tán-án-ná dé ihò ẹnu àti imú. Ọ̀gangan ibí wọ̀nyí ni à ń pè ní òpópónà ajẹmọ́hùn. A le pín Àfipè sí ọ̀nà méjì:

1. Àfipè Àsúnsí: Àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ tí wọ́n wà ní àgbọndò ìsàlẹ̀ ẹnu, tí wọ́n máa ń sún sókè sódò nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀. Àwọn ni: Ètè ìsàlẹ̀, eyín ìsàlẹ̀, èrìgì, àti ahọ́n.

2. Àfipè Àkànmọ́lẹ̀: Àwọn ẹ̀yà ara ifọ̀ tí wọ́n wà ní òkè ẹnu wa, tí wọ́n dúró gbári sí ojú kan nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀. Àwọn ni: ètè òkè, èrìgì, àjà-ẹnu, àfàsé.

Àfipè àsúnsí ni ó máa ń sún lọ bá àfipè àkànmọ́lẹ̀.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]