Opeyemi Ayeola
Ọpẹ́yẹmí Ayéọ̀la | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1977 |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Moshood Abiola Polytechnic Lagos State University |
Iṣẹ́ | òṣèré-bìnrin |
Ọpẹ́yẹmí Ayéọ̀la (tí a bí ní Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1977) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré-bìnrin sinimá-àgbéléwò ọmọ bíbí ìlú ṣàgámù ní ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ti kópa nínú oríṣiríṣi sinimá àgbéléwò. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà gẹ́gẹ́ bí gẹ́gẹ́ bí òṣèré nínú eré àgbéléwò nínú ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán tí wọ́n ń pè ní "Bàbá Ajasco and Company". [1] [2]
Ìgbé-ayé ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọpẹ́yẹmí Ayéọ̀la bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkà ní ilé-ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ni Our Lady of Apostles Private School, ní Yábàá nílùú Èkó. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní in Rẹ́mọ́ Schools. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ í gíga tí Moshood Abiola Polytechnic, Abẹ́òkúta, níbi tí ó ti kàwé gboyè Ordinary National Diploma (OND) nínú ìmọ̀ Ìṣirọ̀ Owó (Accountancy), bákan náà, ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ dé Ifáfitì ìpínlẹ̀ Èkó (Lagos State University), níbi tí ó ti kàwé gboyè dìgírì nínú ìmọ̀ ìṣirọ̀-owó bákan náà.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "7 Things You Should Know About Opeyemi Aiyeola As She Turns A Year Older". Nigerian Celebrity News + Latest Entertainment News. 2018-08-29. Archived from the original on 2019-11-28. Retrieved 2019-11-28.
- ↑ "Opeyemi Aiyeola marks birthday with cute photos". P.M. News. 2019-08-29. Retrieved 2019-11-28.
- ↑ "Nigerian Celebrity Biography: Opeyemi Aiyeola - Beautiful Nigeria". Beautiful Nigeria. 2017-01-05. Retrieved 2019-11-28.