Àgàdá ní Ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ìtàn bí Àgàdá ṣendé ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà
Ìtàn méjì ló rọ̀ mọ́ bi Àgàdá ṣe dé Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà.
Ìtàn kìíní
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]sọ fún wa pé ìlú Ìlayè ni wọ́n tí gbé e wá sí Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà. Ìlú Ìlayè yí ti wà lásìkò kan ní ayé àtijọ́ ṣùgbọ́n ìwádìí fi hàn wá pé kò sí i mọ́ lóde òní. Ìtàn sọ pé Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà jẹ́ jagunjagun didi tí ó lágbára púpọ̀. Ó jà títí ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kan dé ìlú Ìlayè, ṣùgọ́n kí ó tó dé ìlú yìí, àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti ránsẹ́ sí àwọn ènìyàn wọn ní ìlú tiwọn pé ki wọn wá pàdé wọn láti fi agbára kún agbára fún wọn nítorí pé ìdè ń ta wọ́n lápá. Báyìí ni àwọn ènìyàn ọ̀tá Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà gbéra láti wà gbèjà Ọba wọn. Ìlù Ìlayè yí ni wọ́n ti pàdé Ọba ọ̀tá Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà, ogún sì wá gbónà janjan. Nítorí pé agbára ti kún agbára Ọba ọ̀tá Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà yí, ó wá dàbí ọwọ́ fẹ́ tẹ Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun náà bá sá tọ Ọba Ìlú Ìlayè lọ fún ìrànlọ́wọ́. Lọ́gán ni onítọ̀hún náà fún Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ní òrìṣà kan nínú òrìṣà wọn tí ó lágbára gidi láti gbèjà Ọba Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà. Ó si sẹ́gun ọ̀tà rẹ̀. Bayìí ni Ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ṣe bèèrè fún òrìṣà yí ó sì tọrọ rẹ̀ láti gbé e wá sí ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nítorí pé ó ti ran án lọ́wọ́ lọ́pọ̀: ṣe òrìṣà tí ó bá san ni là ń sìn. Ṣùgbọ́n Ọba yìí kò gbé e fún un, Ìlú rẹ̀ tí ń jẹ́ ÀGÀDÁ ló gbé fún un láti máa gbé lọ ní rántí òrìṣà olùgbèjà yí. Ìgbà tí ọba Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà dé ìlú rẹ̀ ni ó bá kọ́lè kan fún ìránti òrìṣà yí ó sì fi Ọkùnrin kan tì í pé kí ó màa bá òun rántí òrìṣà náà pé òun yóò sì wá máa fún un ní ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún fún ìrántí oore tí ó ṣe fún wọn. Báyìí ni ó ṣe di ọdún Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà títí di òní, ìgbàkugbà tí wọ́n bá sì fẹ́ rántí rẹ̀ tàbí bọ ọ́, ìlú Àgàdá yìí ni wọ́n máa ń lù fún un, ilù ogun sì ni ìlù náà. Láti ọjọ́ náà tí ogun kan bá wọ ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ìlú náà ni wọ́n máa ń lù, tí wọ́n bá sì ti ń lù ú, gbogbo ọmọ -ogun ìlú ni yóò máa fi gbogbo agbára wọn jà nítorí pé orí wọn yóò máa yá, agbára sì túnbọ̀ máa kún agbára fún wọn.
Ìtàn kejì
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]sọ fún wa pé Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ni wọ́n bí i àti pé alágbára gidi ni, ó fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kà fim ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ṣùgbọ́n nígbẹ̀hìn ó kú gẹ́gẹ́ bí alágbára, wọ́n sì sin ín gẹ́gẹ́ bí akíkanjú ọkùnrin. Wọ́n sọ ọ́ di òrìṣà kan pàtàkì ní ìlú gẹ́gẹ́ bí àwọn alágbára ayé ọjọ́un tí wọ́n ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà fún àwọn ènìyàn wọn, tí wọ́n kú tán tí wọ́n sì ti ipa bẹ́ẹ̀ sọ wọ́n di òriṣà àti ẹn ìbọ lóníì àwọn òrìṣà bí ògún, ọ̀ṣun, ṣàngó, ọbàtálá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí a ń gbọ́ orúkọ wọn jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá lóde òní.
Nígbà tí ó wà láyé, ó fẹ́ràn ìlù Àgàdá púpọ̀. Tí ogun bá sì wà, tí wọ́n bá ti ń lu ìlù náà, kí ó máa jà lọ láìwo ẹ̀nìyàn ni. Kò sì sí ìgbà tí wọ́n bá ń lu ìlù yí tí ogun bá wà tí kò ní ṣẹ́gun. Ìgbà tí ó sí kú, ìlù yí náà ni àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà máa ń lú tí ogun bá wà, ó sì di dandan kí àwọn áà borí irú ogun bẹ́ẹ̀.
Orúkọ̀ míràn fún Àgàdá tún ni Dígunmọ́dò nítorí pé tí ogún bá ti ń bọ̀ láti wọ̀lú, ibi Ẹrẹ́jà ni ọkùnrin akíkanjú náà yóò ti lọ pàdé rẹ̀, kò sì ní jẹ́ kí ó wọ ìlú dé apá Ọ̀kèniṣà ti a ń pe ní orí ayé tí àwọn ènìyàn wà nígba náà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pè é ní DÍGUNMÓDÒ –DÍ OGUN MỌ́ ODÒ. Títí di oní yìí, Ẹrẹ́jà náà ni wọ́n ti ń bọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ojúbọ rẹ̀.
Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní “ẹjọ́ kì í ṣe tara ẹni ká má mọ̀ ọ́n dá” èyí ló jẹ́ kí n ronú dáadáa sí àwọn ìtàn méjì yí láti lè mọ eléyìí tí ó jẹ́ òótọ́ tí a sì lè fara mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìtán àtẹnudẹ́nu, àwọn olùsọ̀tàn ìtàn méjèèjì yí ló ń gbìyànjú láti sọ pé epó dun ẹ̀fọ́ wọn nítorí pé oníkálùkù ló ń gbé ìtàn tirẹ̀ lárugẹ. Ṣùgbọ́n ìgbà tí a wo ìsàlẹ̀ láti rí gùdùgbú ìgbá mo gba ìtàn tàkọ́kọ́ tí ó sọ pé ìlú Ilayè ni wọ́n ti mú un wá gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó jẹ́ òótọ́ jù lọ nítorí pé wọ́n máa ń ki òrìṣà náà bayìí pé
===Oríkì=== “Ògbúkù lérí esi
Jó jẹ̀gi Ìlayè”
Nínú orin rẹ̀ náà, ọ̀kan sọ pé:
Èlè: Oriṣà Òrìṣà
Ègbè: Jẹ kéèrín peyín ò
Èlé: Bàbá ulé Aláyè
Ègbè: Jẹ́ kéèrín pe yín ò
Èlé: Oriṣà òrìsà
Ègbè: Jẹ́ kéèrín peyín ò
Ṣùgbọ́n kì í ṣe òrìṣà yí nìkan ni ìtàn sọ fún wa pé ó ń
gbèjà Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà lákòókó ogun; ìrókò náà jẹ́ ọ̀kan. Akíkanjú ni òun náà tí kì í gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀ kó má tatí were” ni tirẹ̀. Nígbà kan rí, a gbọ́ wí pé òrìṣà ìlú Ejíkú3 ni ìrókò jẹ́ ṣùgbọ́n ìgbà gbogbo ni ogún máa ń yọ ìlú yìí lẹ́nu tí wọ́n sí máa ń kó wọn lọ́mọ lọ. Nígẹ̀hìn, wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ wá sí ọ̀dọ̀ Ọba Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ò sì ràn wọnm lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí Èkíjú rójú ráyè tán ni wọ́n bá kúkú kó wá sí ilú Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà láti sá fún ogun àti pé ẹni tí ó ran ni lọ́wọ́ yìí tó sá tọ̀ ìgbà tí ìlú méjì yí di ọ̀kan ni òrìṣà tí ó ti jẹ́ tí Èjíkú tẹ́lẹ̀ bá di ti Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà nítorí pé ìgbà tí Èjíkú ń bọ̀ wá sí Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà, wọ́n gbé òrìṣà wọn yìí lọ́wọ́. Gbogbo ìgbà tí ogun bá dìde sí Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà náà ni ìrókò yí máa ń dìde láti sa gbogbo ipá ọwọ́ rẹ̀ láti gbèjà ìlú náà. Ológun gidi ni ìtàn sì sọ fún wa pé òun náà jẹ́ látàárọ ọjọ́ wá. Ṣé ẹni tí ó ṣe fún ni là ń ṣe é fún; èyí ni ìrókò náà ṣe máa ń gbé ọ̀rọ̀ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà karí tí nǹkan bá dé sí i láti fi ìwà ìmoore hàn tún ìlú náà. Ìdílé kan pàtàkì ni Èjíkú tí a ń sòrọ̀ rẹ̀ yí jẹ́ nílùú Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí, àwọn sì ni ìran tí ń sin tàbí bọ òrìṣà ìrókò yí. Olórí tàbí Ọba Èjíkú sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìwàrẹ̀fà mẹfà ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí.
Àwọn tínqọ́n ń ṣe ọdún yìí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lẹ́hìn ìgbà tí òrìṣà yí tit i ìlú Ìlayè dé Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà tí Ọba sì ti gbé e kalẹ̀ sí Ẹrẹ́jà, ló ti fi olùtọ́jù tì í. Ọbalórìṣà ni orúkọ rẹ̀ tí ó jẹ́ agbátẹrù òrìṣà náà.
“Ẹni tí ó ṣe fú ni là ń ṣe é fún” “ẹni tí a sì ṣe lóore tí kò mọ̀ ón bí a ṣe é ní ibi kò búrú”kí àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà má bà a jẹ́ abara – í móore - jẹ ni gbogbo wọn ṣe gba òrìṣà yí bí Ọlọ́run wọn tí wọ́n sì ń bọ́ ọ́ lọ́dọọdún. Àwọn tó ń bọ́ ọ́ pín sí mẹ́rin. Olórí àwòrò òrìṣà àgàdá ni Ọbalórìṣà tí ó jẹ́ agbàtẹrù òrìṣà náà. Aṣojú ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ló jẹ́ fún òrìṣà náà “Omi ni a sì ń tẹ̀ ká tó tẹ iyanrìn” bí ọbá bá fẹ́ bọ Àgàdá, ọbalórìṣà ni yóò rìí. Bí àwọn ọmọ ìlú ló fẹ́ bọ ọ́, Ọbalòrìṣà náà ni wọn yóò rí pẹ̀lú.
Ìsọ̀ngbè ọbalórìṣà nínú bíbọ Àgàdá ni àwọn olórí ọmọ ìlú. Àwọn olórí-ọmọ yìí ló máa ń kó àwọn ọmọ ìlú lẹ́hìn lákòókó ọdún Àgàdá náà láti jó yí ìlú káákiri àti láti máa ṣàdúrà fún ìlọsíwájú ni gbobgo ìkóríta ìlú. Ọba ìlú náà ní ipa pàtàkì tirẹ̀ làti kó. Òun ló ń pèsè ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan lódọọdún láti fí bọ òrìṣà náà èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn rẹ̀ ní ìgbà tó gba òrìṣà náà òun yóò máa fún un ní ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún títí dòní ló sì ń ṣe ìràntí ìlérí rẹ̀ ọjọ́ kìíní.
Wàyí o, gbogbo ìlú ni wọ́n ka ọdún díde láti ṣe ọdún náà tọkùnrin tobìnrin, tọmọdé tàgbà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà tí ó wà ní ìdálẹ̀ ni yóò wálé fún ọdún náà. Gbogbo ìlú ló sì máa ń dùn yùngbà tí wọ́n bá ń ṣe ọdún náà lọ́wọ́.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |