Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): R

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Atumo-Ede (Yoruba-English): R)
Jump to navigation Jump to search

Rà v.t. to buy, to purchase, to redeem, to the with rope, to rot, to furnish with laths. Ó ra ìwé (He bought a book)

Rà, adj. rotten, Ẹran náà ti n rà (The meat has started to go rotten)

Ra, v.i. to perish, to rub on, Ó fi epo ra ara (He rubbed oil on his body)

Rá, v.i. to crawl, to creep, ó rá sábẹ́ igi. (He crawled under the tree.

Rá bàbà, v.i. to flutter or hover over. Ẹyẹ náà rá bàbà lórí ilé (The bird hovered over the house)

Ràdí, v.i to replace, to buy back. Wọ́n ní kí ó ra gíláàsì mìíràn dí èyí tí ó fọ́ (He was asked to replace the glass he broke)

Ràdọ̀ bò, v.t. to shelter, to defend, to gather as a hen does to her brood, to protect. Ó ràdọ̀ bò mí (He protected me).

Ráhùn, v.i to murmur, to complain. Ó ń ráhùn (He is complaining)

Ràjò, v.i. to go on a journey, to be absent from home. Ó ti ràjò (He has gone on a journey)

Rákaràka, adv. widely spread. Ó rí rákaràka (It is widely spread)

Rákò, Rákòrò, v.i. to creep, to crawl, Ọmọ náà ń rákòrò. (The baby is crawling)

Rákórákó, Rẹ́kórẹ́kó. n. a disease of the penis. Rẹ́kórẹ́kó ń bá a jà. (He is being troubled by a disease of the penis)

Ràkọ̀ràkọ̀, adj. of a brownish red colour. Ó pọ́n ràkọ̀ràkọ̀ (It is of a brownish red colour)

Ràkunmí, ìbákasíẹ, n. camel.

Ramúramù, adv. loudly. Rìnìún náà bú ramúramù (The lion roared loudly)

Rámuràmu, adv. same as Rákaràka, which see).

Ran, v.t. to spin, to twist (as cord, etc.) Aláǹtakùn náà ń ran òwú (The spider is spinning a web)

Rán v.t. to send, to despatch, to sew cloth into dress, to be show in growing . Ó rán iyawo rẹ̀ sí mi (He sent his wife to me).

Ràn, v.i. to be infectious (as disease), to ignite (as fire) Igi náà ti ràn (The wood has ignited)

Rámdanràndan, adv. carelessly, confusedly. Ó ń rìn rándanràndan (He is walking carelessly)

Ràndánràndán, adj. pale, sallow, unhealthy. Ó rí ràndánràndán (He looks unhealthy)

Ràngàndà, adj. bright, protruding (as the eye). Ó nawọ́ sí àwọn ojú rẹ̀ ràngàndàn (He pointed to his protruding eyes)

Raníyè, v.t. to cause one to be forgetful, to infatuate. Ó ra á níyè (He made her to be forgetful)

Rán jáde, v.t. to send out, to order out. Ó ran an jáde láti lọ mú aja wọn wọlé (He sent him out to go and bring their dog inside)

Ranjú, v.t. to dilate one’s eyes. Ó ranjú (He dilated his eyes)

Ranjú mọ́ v.t. to stare at one, to fix the eyes staringly at one. Ó ranjú mọ́ mi (He stared at me)

Ránletí v.t. to remind, to cause to remember or recollect, to put in mind. Ó rán mi létí ojọ́ ìdìbò (He reminded me of the date of the election)

Ràn lẹ́rù v.t. to help one to carry one’s load, to assist. Ó ràn án lẹ́rù (He helped him to carry his load.

Rán lọ, v.t. see Rán

Ràn lọ́wọ́, v.t. to help, to aid, to assist, to succour. Ó ràn mí lọ́wọ́ (He helped me).

Ràn mọ́ v.t. to catch, to stick to, to attach, to hold fast. Iná ràn mọ́ ọn lẹ́wù. (He garment caught fire)

Rán pọ̀, v.t. to speak ironically to sew together. Ó rán àwọn àpò náà pọ̀ (He sew the bags together)

Ránṣẹ́ v.t. to send a message. O ránṣẹ́ sí i. (He sent a message to him)

Ránṣọ, v.i to sew cloth. Ó ránṣọ rẹ̀. (He sew his own clothes.

Rántí, v.i to remember, to call, to mind, to recollect. Rántí láti mú ìwé náà wá (Remember to bring the book)

Rán-unran-un, n. nonsense. Ó ń sọ rán-unràn-un. (He is talling nonsense)

Ràn-ùnràn-ùn, adv. wonderingly.

Rápálá v.i. to crawl with difficulty to wriggle along. Ọmọ náà ń rápálá. (The baby was crawling with difficulty)

Rárà n. song, elegy, culugy. Ó ń sun rárà. (He is sing a ecology)

Rara, adv. loudly, vociverously, bitterly. Ó ń ké rara. (He is shouting bitterly)

Ràrá, n. dwarf, piginy. Ràrá ni (He is a dwarf )

Rara, v.t. to redeem oneself. Ó san owó láti rara rẹ (He paid money to redeem himself).

Rárá, adv. at all. Kò lọ rárá (He didn’t go at all)

Ráre, v.i. to linger, to suffer a long and tedious illness without care or attention, to struggle between life and death. Wọ́n fi i sílẹ̀ kí ó máa ráre. (They left him to suffer the long illness without care)

Rárí fárí, v.i to shave the head. Ó rárí rẹ̀ (He shaved his head)

Raurau, adv. entirely, totally, altogether, comptely. Ilé náà jóná ráúráú. (The house burnt completely)

Rawọ́, v.i. to rub both hand together. O rawọ́ (He rubbed his hands together)

Re, v.i. to change or shed feathers, to moult, to fall off (as hairs or leaves) Àwọn ẹyẹ náà re ìyẹ́ wọn (The birds shed their feathers)

Ré, v.i. to go off, to spring (as a trap or snare), to skin, to snap shut. Pàkúté náà ré. (The trap snapped shut)

Re àjò, Ràjò, Rebi, v.i to go on a journey, to go abroad. Ó re àjò (He went on a journey)

Réderède, n. foolishness, to be redundant. Ó sọ mi dib réderède (He made me to be redundant)

Rèdí. V.i to move the tail upward (as a bird sitting on a tree). tp wag the tail, tp waggle the buttocks. Ó ń rèdí. (She is waggling her buttocks)

Régérégé, adv. evenly, exactly, perfectly. Ó gún régérégé. (It is perfectly straight)

Rékọjá, v.t. to pass over, to omit, to exceed. Ó ré odò náà kọjá (He passed over the river)

Rékọjá adv. beyond measure, exceedingly, extremely. Ó ga rékọjá àlà (He is extremenly tall)

Rékọjá àlà, adv. beyond bounds, exceedingly, extremely. Ó kúrú rékọjá àlà. (He is extremely short).

Rélọ, v.i to entice, to seduce

Ré mọ́ v.t. to be attracted to, to draw towards. Ó ré mọ́ olówó ọjà. (She was attracted to the rich man at the market)

Réré, adv. far, at a great distance. Ìlú náà wà ní ọ̀nà jínjìn réré sí ibí (The town is far from here)

Rere, adj. good, well. Ọmọ rere ni. (He is a good child)

Rere, adv. well. Ó perí mi ní rere (He wish me well)

Rere, Ire, n. good, welfare, good act. Rere gbè é (Good act benefited him)

Rérí, v.t. ó fẹ́ rérí rẹ̀ (He wants to shave the hairs of his head)

Rérí, v.i. to cease yielding fruits. Igi náà ti rérí (The tree has stopped yielding fruits)

Reta, v.t. to pick pepper from the stem with the hand. Ó ń reta (She is picking pepper from the stem with her hands)

Retí, v.t. to hope for, to expect, to wait for. Ó ń retí wa (He is expecting us)

Réúréú adj. short and stunted. Ó rí réúréú (He is short and stunted)

Rèyẹ́, v.i to shed feathers, to new (as a hawk) Àwọn ẹyẹ náà rèyẹ́ wọn (The birds shed their feathers)

Rẹ́, v.t. to cut, to shear, to nip, to plaster. Ó rẹ́ lé rẹ̀ (He plastered his house)

Rẹ́, v.i. to be friendly together. wọ́n rẹ́ (They are friendly together)

Rẹ, v.t. to dye, to steep in water, to soak (as clothes) in water. Ó rẹ aṣọ rẹ̀ ṣínú omi (He soaked his clothes in the water)

Rẹ̀ Possess. Pron. third pers. sing. his, her, its. MO rí ìwé rẹ̀. (I saw his books)

Rẹ̀ v.i to be tired, to increase. Ó rẹ̀ mí (I am tired)

Rẹgẹ, v.t. to set a trap for. Ó rẹgẹ dè é (He set a trap fro him)

Rẹgẹ, Rẹkẹ, v.i. to be on the gui vive, to be on the alert, to be on the watch, to await in angry impatient. Ó rẹgẹ dè é (He awaited him in angry impatient)

Rẹ́gí, Rẹ́gírẹ́gí, adv. evenly, equally, exactly. Agolo àti ìdérí rẹ̀ ṣe régí. (The tin and its lid fit one another exactly)

Rẹ̀yìn, v.i. to be behind, to decrease, to be flat, to go backward, to be backward. Ó rẹ̀yìn (He went backward)

Rẹ́jẹ, v.t. to cheat, to defraud. Ó rẹ́ mi jẹ (He cheated me)

Rẹ láró, v.t. to dye. Ó rẹ ẹ́ láró (He dyed it).

Rẹ́lé, v.t. to plaster house. Ó rẹ́lé rẹ̀ (He plastered his house)

Rẹlẹ̀, v.t. to go down, to humble oneself, to subside, to be low. Ó rẹlẹ̀ (It is low)

Rẹ̀ lẹ́kún, v.t. to comfort, to console. Ó rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún (He consoled him)


Rẹ́ lórí, v.t. to poll, to prune the branches off, to top. Ó rẹ́ igi náà lórí (He pruned the branches of the tree)

Rẹ́ lórùn, v.t. to cut the neck of. Ó rẹ́ ẹ lọ́rùn (He cut his neck)

Rẹ́ lulẹ̀, ké lulẹ̀, v.t. to cut down. Ó rẹ́ igi náà lulẹ̀. (He cut the tree down)

Rẹ́mú, Rẹ́múrẹ́mú, adv. exactly. Wọ́n ṣe rémú (The fit each other exactly)

Rẹ́pọ̀, Rẹ́pọ̀ mọ́, v.t. to cleave, to combine with, to become fused together. Wọ́n rẹ́pọ̀ (They became fused together)

Rẹrẹ, adv. closely (modifying verbs of pursuing or of motion towards) Ó gbá rẹrẹ tì í (He followed him closely)

Rẹ́rìn-ín, v.i to laugh. O rẹ́rìn-ín. (He laughed)

Rẹ́rìn-ín akọ, v.i to laugh coarsely. Ó rẹ́rìn-ín akọ (He laughed coarsely)

Rẹrù, v.i. to carry load, to bear burden, to bear responsibility. Ó rẹrù. (He was carrying a load)

Rẹ sílẹ̀, v.t. to lower, to degrade. Ó rẹ̀ é sílẹ̀ (He lowered it)

Rẹ̀tẹ́, v.t to lull to sleep (as a baby)

Rẹ́úrẹ́ú, adv. entirely, completely, altogether. Ó rẹ́ ẹ rẹ́úrẹ́ú (He cut it off completely)

Rẹ̀wẹ̀sì, v.i to be dejected, to be disheartened, to be downcast. Ọkàn rẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì (He felt dejected)

Rẹ́yin, v.t. to draw honey from the live. Ó réyin (He drew honey from the live)

Rẹ̀yìn, v.t. to diminish, to be behind. Ipa tí ó ní ti rẹ̀yìn lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́ (His influence has diminished over time)

Rì, v.i. to be drown, to sink. Ó rì sínú omi (He was drowned)

Rí, v.i to see, to find, to discover, to perceive. Mo rí i (I saw it)

Rí, adv. prior to this time, at any time before, never, at no time before. Kò tíì lọ sí ibẹ̀ rí (He has never been there before)


Rí bákan náà v.i. to be alike, to be similar, to be uniform. Wọ́ rí bákan náà (The were alike)

Ribiribi, adj. important, of much consequence. Ó ṣe iṣẹ́ ribiribi (He did an important task)

Ribiti, Rubutu, adj. round, circular. Ó rí ribiti. (It is round)

Ríborìbo, adv. hither and thither, aimlessly. Máà dà á rìbárìbo. (Don’t direct him aimlessly)

Rí dájú, v.i to be cure of, to be certain. Ó rí i dájú pé ó wà níbẹ̀ (He was certain that he was there)

Rídìí, v.i. to see the reason for a thing, to find out the secret about a thing, to see the end of. Ó ti rídìí ọ̀rọ̀ náà. (He has found out the secret about the matter)


Rífín, v.t. to have a contempt for to hold in contempt. Àwọn ọmọ náà rí wọn fin. (The children held them in contempt)

Rígbà, v.t. to receive, to obtain. Ó rí i gba (He was able to receive it)

Ríhe, v.t. to find, to find and pick up what is lost. Ó rí owó he. (He found and picked up the money that was lost)

Ríjẹ, adj. well off, well-to-do, rich. Ó ríjẹ (He is rich)

Rìkíṣí, n. conspiracy, plot, intrigue. Wọ́n ń di rìkíṣí mọ ọn (They are Plotting against him)

Rín, Rẹ́rìn-ín, v.t. lo laugh. Ó rín (He laughed)

Rin, adj. damp, moist, humid. Yàrá yìí ń rin (This room is damp)

Rìn, v.i to tickle, to walk, to travel. Ó rìn lọ sí ilé. (He walked home.)

Rin, v.i. to grate (cassava), to squeeze against. Wọ́n rin ẹ̀gẹ́ (The grate cassava)

Rìn gbẹ̀rẹ́, v.i. to walk slowly or lazily. Ó ń rìn gbẹ̀rẹ́ (He is walking slowly)

Rin gbindin, v.t. to soak, to be very wet. Ó ń rin gbindin. (It is very wet)

Rìn hẹ́bẹ́hẹ́bẹ́, v.i to waddle, to walk like the duch. Ó ń rìn hẹ́bẹ́hẹ́bẹ́ (He is walking like a duck)


Rìnká, Rìn káàkiri, v.i. to stroll about , to roam about, to walk about. Wọn ń rìnká (They were walking about)

Rìn kiri, v.i. to rove about, to wander about. Ó ń rìn kiri (He was wandering about)

Rìn lẹ́dọ̀, v.i. to nauseate. Òórùn ẹran náà ń rìn mí lẹ́dọ̀ (The smell of the meat nauseates me)

Rìn lọ, Rin wò, Rìn yíká, v.t. to go round the boundaries of. Ó rìn yíká oko rẹ̀ (He went round the boundaries of his farm)

Rinrin, adv. very (qualifying “Wúwo”, heavy) Òkúta náà wúwo rinrin (They stone is very heavy)

Rírà, adj purchasable, buying Iṣẹ́ ìwé rírà àti títà ni ó ń ṣe (He is buying and selling books)

Rírà, adj. putrid, rotten Ẹ̀fọ́ rírà ni ó rà (She bought rotten vegetables)

Ríran, v.i. to see, to have the power of seeing the future. Ó máa ń ríran (He bhas the power of seeing the future)

Ríràn, adj. infections. Àìsàn ríran ni. (It is an infectious disease)

Oju-iwe Keji[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ríraníyè, n. stupefaction, act of stupefying

Rírànlọ́wọ́n, n. help, assistance, act of helping

Rírántí, n. remembrance, memory.

Rírẹ́pọ̀, n. friendliness


Rírẹ́rìn-ín, n laughter. Ilé tí rírẹ́rìn-ín ti pọ ni. (It is a house full of laughter)

Rírẹ̀sílẹ̀, n. humiliation

Rírì, value, worth. Ó mọ rírì ìwé tí mo fún un. (He knows the worth of the book I give to him)

Rírídìí, n. discovery, solution

Rírìn, n. walking, manner of walking. Rírìn jẹ́ eré ìdárayá kan. (Walking is an exercise)

Rírìnkiri, n wandering about.

Rírìn síwájú, n. progress, outward movement.

Rírò, n. proposing, designing (Rírò ni ti ènìyàn, ṣíṣe Ọlọ́run. (Man proposes, God disposes)

Rírojú, n. sadness, melancholy

Rírọ, ìrọ, n. the act of manufacturing, the act of smithing

Rírọ́pò, n. succession, occupying of another’s place. Ní rírọ́pò sí orí oyè, òun ni ipò kẹ́ta. (In order of succession to the throne, he is the third)

Rírú, adj. muddy (as a river) Ó ń ṣeré nínú omi adágún rírú (He is playing in a muddy lake)

Rírù, adj. portable, act of carrying.

Rírù, n. thinness, paleness (especially after illness), becoming thin)

Rírúbọ, n. the act of sacrifice


Rírújú, n. puzzling intricacy, perplexity

Rírúmí ìrúmi, Ìrú omi, billows (as of the sea)

Rírun, n. destruction, extirpation, perishing

Rírùn, adj. stinking, smelling (e.g. palm oil) Ó wọ yàrá rerun (He entered a stinking roon

Rírún, adj crushed, broken. Ó tẹ gíláàsì rerun mọ́lẹ̀. (He stepped on pieces of broken glass)

Rì sílẹ̀, Rì tẹ́lẹ̀ v.t. to bury in the fround. Ó rì í sílẹ̀. (He buried it in the ground)

Rí tẹ́lẹ̀, Rí tẹ́lẹ̀ rí, v.t. to foresee. Kò lè rí bí ọjọ́ iwájú yóò ṣe rí tẹ́lẹ̀ (He could no foresee the future)

Ríwí sí, v.t. to find fault-with, to censure. Ó ríwí sí wọn (They were censured by him)

Rò, to relate, to mediate, to think. Wọ́n rò bẹ́ẹ̀ (They thought so)

Rò, v.t to imagine, to ceive, to rove about. Ilé náà rí bí ó ṣe rò ó. (The house was as she had imagined it)

Ró, v.i. to give sound. Aago náà ró fún ìparí kíláàsì. (The bell sounded for the end of the class)

Ro, v.t. to hoe, to till, to drill. Ó ń ro oko rẹ̀ (He is hoeing his farm)

Ro, v.i. to fall down in drops, to pain severely, to ache. Gbogbo ara ló ń ro mí (I am aching all over my body)

Rò bẹẹrẹ, v.i. to dilate, to expatiate upon, to talk too much. Ó bú u fún pé ó rò bẹẹrẹ (He rebuked him for talking too much)

Róbótó, Roboto, adj. round, circular. Òṣùpá rí roboto. (The moon is round)

Ródóródó, Rodorodo, adj. moulded in round form, to be spherical, to be globular. Ó ń rodorodo (It is spherical)

Rogodo, adj. round, circular. Ó rí rogodo (It is round)

Ró gooro, Ró wooro, v.i. to give a sharp shrill sound, to tingle, to be very painful. Ó ń ro mí gooro. (It is very painful)

Rogún, v.i to drain into a pond or pit. OmÍ rogún sínú ihò. (Water drained into the pit)

Ròyìn, v.t. to tell news, to report, to recount news. Ó ròyìn náà fún mi (He recounted the news to me)

Rojọ́, v.i to complain, to narrate the point. Ó rojọ́ fún mi nípa ìwà rẹ̀. (He complained to me about his behaviour)

Rojú v.i to look sad or displeased to be sulky, to frown. Ó rojú. (He frowned)

Rokà, v.t. to turn or stir yam-flour in boiling water. Ó ń rokà (He is turning yam-flour in boiling water)

Rò káàkiri, v.t. to spread abroad news about a person. Ó ń ro ẹjọ́ ọmọkùnrin náà káàkíri (He is spreading abroad news about the boy)

Rò kiri, v.t. same as ‘Rò káàkiri’

Rókírókí, adv. brilliantly (modifying the adj. ‘Pọ́n’ red) Ó pọ́n rókírókí (It is brilliantly red.)

Roko, v.i. to till the ground, to cultivate a farm. Ó ń roko (He is tilling the ground)

Rólé, v.t. to succeed one’s father as the head of the house to put on the roof of a house. A ti rólé wa. (We have put on the roofs of our house)

Rolẹ̀ v.t. the same as Roko.

Ròlù, v.t. to add together. Ó ro gbogbo wọn. Ó ro gbogbo wọn lù (He added them together)

Ròmọ́, v.t. to add to a previous amount. Ó ro owó yìí mọ́ owó yẹn (He added this money to that)

Rónà, v.t. to block the way for someone with a charm. Ó rónà fún un. (He blocked the way for him with a charm)

Ronú, v.i to think, to meditate, to be sorry. Ó ń ronú (He is thingking)

Ronú Pìwà dà v.i to repent. Ó ti ronú piwa dà. (He has repented)

Ròarẹ́, Ìrorẹ́, n pimple. Ìrorẹ́ sú bò ó lójú (His face is covered with pimples.

Rorò, adj. austere, severe, harsh, fierce. Ó ra ajá tí ó rorò (He bought a fierce dog).

Ròrò, adv. intensifying such adjectives and verbs as ‘Pọ́n, ‘Dan, ‘Pupa, “Le”. Ó pọ́n rorò (It is golden yellows)

Rọ́, v.i. to gush, to give way, to crash. Omi rọ́ jáde láti inú ọ̀pá ẹ̀rọ náà. (Water gushed out from the pipe)

Rọ, v.i. to wither, to manufacture instruments of iron, to set trop, to forge, to droop. Ó rọ ọkọ (He forged a hoe)

Rọ̀ v.t. to urge, to constrain to press upon, to ease, to be easy. Ó rọ̀ fún mi láti ṣe. (It is easy for me to do)

Rọ̀ adj. soft, tender. Ó rọ̀ (It is soft)

Rọbí, v.i to travail, to be in the pains of child-birth. Ó ń rọbí (She is in the pain of child-birth)

Rọ̀bu, v.t. to put under a show-burning fire, to spoil a plan, etc.

Rọ̀ dẹ̀dẹ̀, v.t. to hang over, to impend, to hang from. Ó ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí igi (It is hanging from a tree.

Rọgun, v.t. to get men ready to attack one, to be on the alert, to be ready for war. Ó rọgun (He was ready for war)

Rọ̀gún, v.i. to lean on. Ó rọ̀gún lé e lórí. (He leaned on it)

Rọ̀gbà ká Rọ̀gbà yíká, v.t. to surround, to ecompass, to encircle. A rọ̀gbà yí ìlú náà ká (We surrounded the town)

Rọ̀gbọ̀kú, v.i. to hounge. Ó ń rọ̀gbọ̀kú (He is lounging on a chair)

Rọ̀jò, v.i to rain. Ó ròjò (It rained)

Rọ́jú, adj. to be able to endure pain or suffering, to strain every nerve. Ó ń rọ́jú jà lọ. (He strains to fight on

Rọjú adv. tame, mild, soft, moderate, cheap. Epo ti rọjú lọ́yà. (oil is now cheap in the market)

Rọ́ kẹ́kẹ́, v.i to creak (as the door, etc.) ilẹ̀kùn náà rọ́ kẹ́kẹ́ ó sì ṣí) (The door crealed open)

Rọlẹ̀, v.i. to subside, to abate. Afẹ́fẹ́ náà ti rọlẹ̀. (The wind has abated)

Rọ̀ lójú, adv. tamely, to look as if one has a mild character. O rọ̀ lójú. (He looks as if he has a mild character)

Rọ̀ lóyè, v.t to remove from office, to deprive one of one’s title, to degrade. Wọ́n ti rọ̀ ó lóyè (He has been removed from office)

Rọ́ lù, v.t. to rush against. Ó rọ́ lù mí (He rushed against me

Rọ̀ mọ́ v.t. to ching to, to embrace. Ó rọ̀ mọ́ mi (He embraced me)

Rọ́nú, v.i to be abstemious, able to endure hunger or starvation for a long time. Ó rọ́nú (He is able to endure hunger for a long time)

Rọnú, adj. tender-hearted soft-hearted. Ó rọnú (He is tender-hearted)


Rọ́pá v.t. to fail to successd, to collapse

Rọ́pò, v.t. to take the place of another, to succeed. Òjó ti rópò Adé (Òjó has taken the place of Adé)

Rọra, v.i to be careful, to deal gentle.

Rọra Be careful

Rọ̀rọ̀, n. mane (as of the ram, etc.) the long hair on the neck of a horse or a him. Ó fi ọwọ́ ken rọ̀rọ̀ ẹsin náà. (He touched the long hair on the neck of the horse)

Rọrùn, adj. easy convenient, comfortable. Ó rorùn láti yanjú (It is easy to solve)

Rọ́tì, v.t. to put on one side. Ó rọ́ wọn tì (He put them on one side)

Rù, v.t. to bear, to carry, to support, to sustain, to lose flesh, to be lean. Ó rù (He is lean)

Rú v.t. to stir up, to incite, to spring up, to shoot up, to sprout, to rise (as smoke) Èéfín náà ń rú. (The smoke is rising)

Rú v.i to rise, to swell, to boil over (as hot water), to be moved with anger or grief. Ómi náà ru sókè (The water boiled over)

Rúbọ, v.t. to make or offer sacrifice, to make an offering. Ó ń rúbọ sí òrìṣà (He is making an offering to the deity)

Rúdurùdu, n. confusion, chaos. Lẹ́yìn àsè náà, gbogbo inú ilé rí rúdurùdu (After the party, the house was in chaos)

Rúùfin v.t. to transgress, violate or break the law. Ó rúùfin (He broke the law)

Rúgúdú, Rugudu, adj. small, round. Ó rí rúgúdú. (It is small.) Ó rí rugudu (It is round)

Rúgúdù, n. trouble, quarrel, confusion, muddle. Ó dá brúgúdù sílẹ̀ (He caused a muddle)

Rú jáde, v.i. to emerge, to pring out, to shoot out, to sprout up. Àìmoye olú ni ó rú jade láti inú ilẹ̀ (Hundreds of mushrowns sprouted out from the fround)

Rúkèrúdò, n. tumult, uproar, confusion. láti máà dá rúkùrúdò sílẹ̀, parí ìjà yẹn (To avoid confusion settle that dispute)

Rúlùú, v.i. to cause commotion, to stir up revolt in the town. Ó túlùú (He sterred up revolt in the town)

Rúlùurúlùú, n. a seditious person. Rùlùúrúlùú ni (He is a seditious person)

Rún, v.i to break into pieces, to masticate, to chew, to crush. Ó rún obì (He chewed kolanut)

Run, adj. stranght, direct level, extinct. Irú gò yẹn ti run tan (The type od snake has become extinet)

Run, v.t. to consume, to extirpate, to destroy, to annchilate, to exterminate. Wọ́n ní àwọn ohun ìjà tí wọ́n, fi lè brun gbogbo ayé (They have enough weapons to annchilate the world).

Rùn, v.t. to stink, to emit bad odour. Ó ń rùn (It stinks)

Rún awọ v.t. to prepare leather for use, to cure leather. Ó rún awọ (He cured leather)

Rúnlẹ̀ v.i. to break into a house, to commit burglary. Ó rúnlẹ̀. (He committed burglary)