Atúmọ̀-Èdè (Yorùbá-Gẹ̀ẹ́sì): S

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Atumo-Ede (Yoruba-English): S)

Atumo-Ede (Yoruba-English): ₦

Oju-iwe Kiini[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sáà, n. time, season, interval, semester. A ó ka ìwé náà ní sáà tó ń bọ̀. (We shall read the book next semester)

Sá v.t. to dry in the sun, to air to flee, to run. Ó sí lọ (He ran away)

Sà, v.t. to aim at, to apply medicine according to the direction of the doctor of the doctor, to employ. Ó sa oògùn sí i (He employed charms against him.)

Sáà, adv. awhile, for a time. Ó ṣiṣẹ́ fún sáà díẹ̀ (He worked for a short time).

Sàba, v.i. to incubate, to sit on eggs in order to hatch them (of hens), to brood on eggs. Adìyẹ yìí ń sàba (This hen is brooding on her eggs)

Sábà v.i. to be in the habit of doing etc.) to be accustomed to (doing, etc). Mo máà ń sábàá lọ síbẹ̀. (I am in the habit of going there)

Sábẹ́, prep. under. Ó fi sábẹ́ẹ tábìlì (He put it under the table)

Sá di, v.t. to take shelter under one’s protection. Ó sá di mi. (He took shelter under my protection)

Sado, v.i. to compete in running race

Safá v.t. to spread over something (like cream over boiled milk)

Sáàfúlá astonishment, exclamation

Sá fún, v.t. to flee from, to avoid, to eschew. Ó sá fún ejò náà (He flew from the snake)

Sàga tì, Sàba tì v.t. to besiege, to encamp against. Wọ́n sàgà ti lfè (They besieged lfẹ̀)

Saàgùn, v.t. to make use of charms. Ó saàgùn sí i (He made use of charms against him)

Sagbàra, Sagbàra ká, v.i. to fence round with wood, to stockade, to compass about. Ó sagbàra ká ilẹ̀ẹ rẹ̀ (His land was fenced with wood)

Sagbára, v.i. to make effort, to put more effort. Sagbára sí iṣẹ́ rẹ (Put more effort into your work)

Ságbẹ, v.t. to dry by exposure to the sun to air and be dried. Ó sá a gbẹ nínú oòrùn. (He aired it and it got dried in the sun)

Sáji, Tají, v.i. to wake from sleep suddenly. Ó sáji. (He woke from sleep suddenly)

Sàkáání, n. neighbourhood, vicinity. Sàkáání ilée wa ló wà. (He is in the vicinity of our house)

Sakasaka, n. hay dried ground nut leave, provender. Ó ru ìdì sakasaka. (He carried a bale of hay)

Sáàkísáà, adv. at whatever time. Ṣe é ní sáàkísáà tí ó bá wù ó (Do it at whatever time that you like)

Sakun, v.i. to put forth strength, to make an effort. Sakun gidi láti tètè parí lásìkò. (Make real effort to finish on time)

Sakusa, n. a black long-tailed bind.

Sálà, v.i. to escape, to fless for safety. Ó sá, a là fún èmíi rẹ̀/ Ó sá àsálà fún ẹ̀mí i rẹ̀. (He flee to save his life)

Sà lámì, v.t. to make a mark or sign upon. Mo sà á lámì (I made a mark on it)

Sá lé, v.t. to run after in order to overtake. Ó sá lé e. (He ran after him in order to overtake him)

Sá lọ, v.i. to run away, to flee, to elope, to escape. Ó sá lọ. (He ran away)

Sá lù v.t. to go to another, to intervene in one’s interest, to take refuge with. Ó sá lù mí (He took refuge with me)

Sálúbàtà, n. sandals, slippers. Bọ́ sálúbàtà rẹ (Remove your sandals)

Sàmù, Sànù fún, v.t. to baptize. Mo ti sàmì (I have been baptized)

Sànù sí, v.t. to mark with a view to identification. Ò kúta yìí ló sàmì sí ilẹ̀ wa (This stone marks our land)

Sán, v.t. to gird, to tie round, to bind. Ó sán aṣọ mọ́ ìdí (He tied a cloth round his waist)

Sàn, adj. better, improved in health. Ó sàn jù mú lọ (He is better that I am)

Sán, v.i. to split, to crack, to thunder (as lightning) Ife yìí sán. (This cup is cracked)

Sàn-án adv. in a high degree, loudly, vividly

San, v.t. to pay, to reward. Ó san owó náà (He paid the money)

San àsanlé, v.t to overpay. Máà san àsanlé fún un. (Don’t overpay him)

sánbẹ̀ẹ, Sándàá, v.i. to be armed with short swords)

San gbèsè, v.t. to pay debt, to discharge obligation (fig). Ó ti san gbèsè rẹ̀. (He has paid his debt)

Sàn jù, Sàn díẹ̀ adj. better. Tèmi sàn ju tìrẹ (Mine is better than yours)

Sàn jù lọ adj. best. Tèmi ni ọ́ sàn jù lọ (Mine is the best)

Sanlalu, Salalu, adv. extensively

Sánmà, n. the sky. Ó nawọ́ sí sánmà (He painted to the sky)

sànmọ́-ọ́nnì, n. era, a particular period. Nígbà ti ó fi ilé-ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀, sànmọ́-ọ́nnì ken dópin. (When he left the school, it was the end of an era)

Sàn-nda, n. a short big club.

San padà v.t to refund, to reimburse, to rapay. Ó ti san án padà (He is rapaid it)

Sanra, n. fat, plump. Ó sanra. (He is fat)

Sánsán, adv. fragrantly, odoriferously, sweet. Ó ń ta sánsán (It smells sweet)

San-ánsàn-án, adv. straightforwardly, directly, vividly, freguently, clearly. Ó ń sọ̀rọ̀ sàn-ánsàn-án (He is speaking clearly)

Sànsẹ́ adj. better than. Ó sànsẹ́ ìwé yìí (It is better than this book)

Sanwó v.i to pay money. Ó sanwó (He paid money)

Sán-ányán, n. raw silk, coarse woven silk. Ó ń ta sán-ányán. (She sells the coarse woven silk)

Sá[á kan, adv. aside, apart, to one side. Ó yà sápá kan (He stepped aside)

Sá pamọ́ v.i. to hide, to abscond, to skulk. Wọ́n sá pamọ́ sí abẹ́ igi (They hid under the three)

Sára, prep. on, upon. Ó fi kọ́ sára igi. (He hanged it on the tree.)

Sààráà, Sàhàráà, n. alms, charitable gift. Mo ṣe sàráà. (I giave alms)

Sára, v.i. to keep back, to avoid. Ó sára fún un. (He avoided him)

Sàràkí, Sàràkísàràkí, n. noted (members of a society or town) Wọ́n pe àwọn ọmọ ẹgbẹ́ sàràkísàràkí sí ìpàdé náà (Noted members of the club were called into the meeting)

Sáré, Súré, v.i Wọ́n sáré (They ran)

Sarè, n. square enclosed by buildings, hectare. Ó ra sarè ilẹ̀ kan (He bought an hectare of land)

Sàréè, n. grave, tomb, sepulcher. Wọ́n sin ín sí sàréè ti kò jìn. (He was buried ni a shallow grave)

Sárépẹgbẹ́, n. officer, especially secretary of a club or society. Ó joyè sárépẹgbẹ́. (He was made the secretary)

Sààrì, n. the early meal of the Muslinis before day-break during Ramadan. Ó jẹ sààrì (He ale the early meal of the Musline before day-break during Ramadan)

Sarí v.t. to rub medicinal powder into the scalp. Ó sari rẹ̀ (He rubbed medicinal powder into his scalp)

Sàsè, v.i. Ó sàsè (He made a feast)

Sasọ̀, v.i. to quarrel about, to quarrel with. Ó ń bá mi sasọ̀ (He is quarrelling with me)

Sàsọdun, v.t. to exaggerate. Ilé náà kéré gan-an ni, n kò sì sàsọdun. (The house is too small and I am not exaggerating)

Sàsọté, Sọ àsoyé, v.t. to explain clearly. Ó sọ ọ̀rọ̀ náà ní àsoyẹ́ (He explained the matter clearly)

Sá wò ó. Interj. behold! lo! Sá wò ó ! Behole!

Sé, v.t. to shut, to close, to miss a mark or one’s aim. Ó sé ilèkùn (He shut the door)

Sè, v.t. to cook, to dye cloth or leather. Ó se iṣu. (He cooked yams)

Sebẹ̀, v.i. to cook soup. Ó sebẹ̀. (He cooked soup)

Sébọ́, v.i. to be callous, to become stout, to coagulate. Epo yìí sébọ́ (This oil coagulated)

Ségedehùn, v.i. to affect a fine pronunciation of words

Ségesège, adv. disorderly, awkward. Wọ́n mú wọn fún pé wọ́n ti yó wọ́n sì ń ṣe ségesège. (They were arrested for being drunk and disorderly)

Séhùn, v.t. to break one’s promise, to fail not to keep appointment. Ó séhùn (He failed to caryy out his promise)

Sejú, Sejú sí, v.i. to ogle, to look amorously. Ó sejú sí mi (He ogled me)

Sèlé, v.i. to refine palm-oil by extra boiling. Hence, “Epo ìsèlé,” refined palm oil)

Séle, v.t. to harden (heart or ears) Ó sé ọkàn rẹ̀ le sí mi (He hardened his heart to me)

Sèlésè, v.t. to dye (cloth, etc.) in colour

Sélẹ̀ v.i. to fail, to miscarry. Ète wọn sélẹ̀. (Their paln failed)

Sé lọ́wọ́, v.t. to make a mistake. Ó sé mi lọ́wọ́ (I madea mistake)

Sèlù, v.i. to make a drum. Ó sèlù (He made a drum)

Sémọ́, v.t. to shut in, to enclose, to lack on. Ó ṣe ilẹ̀kùn mọ́ ọn (He locked the door on him)

Sémọ́lé, v.t. to restrict one’s freedom of movement, to shut in, to comfine. Ó sé mi mọ́lé (He restricted my freedom of movement.

Sémọ́de, Sémóde, v.t. to shut out, to lock out. Ó sé e mode. (He locked him out)

Sémú, v.t. to miss taking hold of, to hold one’s nose. Ó sé e mú (He missed taking hold of him)

Sè mu, v.t. to boil herb or vergetable for drinking as medicine or food. Mo sè é mu (I boiled and drank it)

Sénà, v.t. to block the road, to blockade the road. Ó sénà náà (He blocked the road)

Sépa, v.t. to close fast or tight, to close tightly. Ó sé e pa. (He closed it tightly)

Sepo, v.i. Ó sepo náà. (She prepared the palm-oil by boiling it.)

Sépọ́n, v.i. to be barren or unfruithful, to be to fat to bear children. Ó sépọ́n (He is too fat to bear children)

Séra ró, v.i. to keep steady, to be motionless, to be pregnant) Ó séra ró (He was motionless)

Sèsé, n. a kind of bean, yam bean. Eku náà jẹ sèsé (The rat ate yam beans)

Sésẹ̀, v.i. to cease going or coming to a place. Wọ́n sésẹ̀ níbì (They have stopped coming here)

Sèso, v.i. to bear fruit. Igi náà ti sèso (The tree has bore fruits)

Séta, v.t. to miss one’s aim. Ó séta (He shot but missed what he shot at)

Sètà, v.t. to cook for sale. Ó se ẹ̀wà tà (She cooked beans for sale)


Sétí, v.i. to be attentive to a distance noise, to eavesdrop. Ó sétí rẹ̀ (He was attentive to a distant noise)

Sẹ́, v.t. to strain, to filter, to deny, to sift out. Ó sẹ́ ògì. (He sifted out starch from pounded corn)

Sẹ̀, v.t. to beat or sound a drum, to challenge one

Sẹ̀, v.i to flow in drops as milk from the breast, to fall as dew. Ìrì ti sẹ̀ (Dens has fallen)

Sẹ́, adv. denoting emphasis, indeed, surely N kò rí i sẹ́ (Surely, I didn’t se him)

Sẹ̀gẹ̀dẹ̀, v.t. to form a sediment. Omi náà sẹ̀gẹ̀dẹ̀. (Sediments of this water have settled)

Sẹ̀gẹsẹ̀gẹ, adj. dignified, respectable

Sẹ̀gi, n. a variety of valuable beads

Sẹ́gì, v.i. to speak like an Egúngún, to speak in an unnatural tone

Sẹ́gì, v.t. to sift out the starch from the corn after the latter had been well pounded. Ó sẹ́gì. (She sifted out starch from pounded corn)

Sẹ́gíìrì v.i. to tremble from sudden sensation, to shudder. Ara rẹ̀ sẹ́gíìrì. (He shuddered)

Sẹ̀gún, v.i. to strike two iron implements together. Ó sẹ̀gún (He tapped his hammer on iron)

Sẹ̀gbẹ̀, v.i. to cook a pottage made of bean. Ó sẹ̀gbẹ̀. (He cooked a pottage made of beans)

Sẹ́hùn, Sẹ́yìn, adv. backwards. Ó rìn sẹ́yìn. (He moved backwards)

Sẹnà, v.t. to speak so that only those in the secret understand the true meaning of what is said, a code. Ó sẹnà sí i. (He spoke to him in lode)

Sẹ̀n-ẹ́nsẹ̀n-ẹ́n adv. slightly (qualifying ‘dùn’, sweet). Sé ó dùn? Bẹ́ẹ̀ ni, sẹ̀n-ẹ́n sẹ̀n-ẹ́n. (Is it sweet? Yes, slightly)

Sẹ́ra, v.t. to deny, to practice self-denial. Mo sẹ́ra mi (I practiced self denial)

Sẹ̀rì, v.t. to drop des. Ó sẹ̀rì. (It dropped dew)

Sí, v.i to be, to exist calways presceded by “Kò.” meaning ‘not. Ìyá kò sí mọ́ (Mother is no more)

Sí, prep. against, to, at. Into, always used with a verb of motion towards. Mo lọ sí oko. (I went to to the farm)

Sì, conj. and, also, likewise. Ó ra iṣe ó sì jẹ ẹ́ (He bought a piece of yam and ate it)

Sìì, adv. showly (used with the verb ‘crawl’= to drag), laboriously. Ó ń gbá sìì. (He is walking laboriously)

Siàn, Sunwọ̀n, adj. good, fair, pleasant, well nice. Ó siàn. (It is good)

Sìbáta. V.t. to crush, to destroy, to overwhelm)

Síbẹ̀, Síbẹ̀síbẹ̀, adv. still, all the same. Ó ń jó síbẹ̀ (He is still dancing)

Síbi, adv. to the place, to a certain place, on a journey. Ó lọ síbi (He went to a certain place)

Síbì kan adv. to one place, together, in a group. Wọ́n jọ dúró síbì kan náà (They stood together in a group)

Síbo, prep. to what place, whither, where. Síbo ló lọ? (Where did he go? )

Síbòmíràn, adv. to another place, elsewhere. Ó ti lọ síbòmíràn (He has gone to another place)

Sìgasìga, adv. totteringly. Ó ń rìn sìgasìga (He is walking totteringly)

Sìgbẹ, v.t. to store up for future use)

Sìgbọnlẹ̀, adj. tall and stout. Ó sìgbọnlẹ̀ (He is tall and stout)

Síhà, prep. towards, on the side of, to one side. Wọ́n wá síhà ìhín (They came to this side)

Sínhìn-in-sọ́hùn-ún, adv. here and there, hether and thither. Ó ń mì síhìn-ín-sọ́hùn-ún. (It is moving here and there)

Silé, v.i to col down (as fever, etc.) Ibà rẹ̀ ti silé (He fever has cooled down)

Silẹ̀, v.i. to settle down. Omi náà ti silẹ̀. (The water has settled down)

Sìmẹ̀dọ̀, v.i. to keep cool, not to lose one’s temper. Sìmẹ̀dọ̀ (Keep cool)

Simi, v.i. to rest, to pause, to be quiet, imperat mood, hush! Ó ń sime (He is resting)

Sín, to string (as beads or cowries), to sneeze. Ó sín (He sneezed)

Sin, adv. before, first in point of time. Ó ṣe é sin ọ́ (He did it before you)

Sin. V.t. to bury, to be concealed, to force green fruit to ripes. Wọ́n ti sin ín (He has been buried)

Sìn, v.t. to accompany, to lead on the way, to demand debt due, to lord over, to dominate, to serve a superior, to adore. Ó ń sìn ín (He is serving him)

Sindè, v.i. to play a game in which anything is hidden in heaps of sand or earth, unknown to one of the players, who has to discover it.

Singbà, v.i. to work or to give service in lieu of interest on money lent, to work as a pawn. Ó ń singbà (He is working as a pawn)

Sín gbẹ́rẹ́, v.i. to make incisions with a lancet. Ó sín gbẹ́rẹ́ sí apá (He made incisions on his arm with a lancet)

Sìnìka, n. a white metal sold on the coast.

Sínjẹ, v.t. to mimic, to parody. Ó sín in jẹ (He minmicked him)

Sìnkú, v.t. to buy (the dead). Wọ́n ti sìnkú ọkùnrin náà (They have buried the man)

Sínkùrọ́, v.t. to crack palm-nut. Wọ́n ń sínkùrọ́ (They are cracking palm-nuts)


Sínlọ́pàá, v.t. to impale, to string on sticks. Ó sín wọn lọ́pàá (He strung them on the sticks)

Sinra, v.t. to treasure.

Sìnrú, v.t. to labour, to work as a slave, to be a serf. Ó ń sìnrú lọ́dọ̀ rẹ̀ (He is working as a slave for him)

Sínú, Prep. into, among. Ó fi ìwé náà sínú àpótí (He puts the book into the box)

Sínwín, v.i. to be insane, to be mentally deranged, to be crazy or mad. Ó ń sínwín. (He is mentally deranged)

Sípa, prep. in the track of, towards, concerning, to the role, at the role. Ó tọ́ka sípa tó kó nínú iṣẹ́ náà. (He pointed at the role he played in the work)

Sirẹ̀, v.i. to take thought

Sísan, adj. payable. Sísan ni owó náà ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí (The money is payable at the end of this week)

Oju-iwe Keji[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sísán, adj. cracked, split. Apẹ sísán ni ó rà (He bought a cracked pot)

Sísán-àrá, n. thunder-clap. Ó gbọ́ síán-àrá kí òjò ńlá náà tó bẹ̀rẹ̀ (He heard a thunder-clap before the heavy rain started)

Sísanra, n. corpulency, fatness. Sísánra máa ń hàn nínú àwọn ẹbí kan (fatness tends to run in some families)

Sísára, n. evasion. Wọ́n fi ẹ̀sùn sísára fún owó-orí kàn án (He was accused of tax evasion)

Sísáré, n. running. Nípa sísáré gan-an ni ó fi sá lọ. (By running fast, he made good his escape)

Sísàsè, n. feasting. Nípa sísàsè fún àwọn ènìyàn ó di olókìkí (By feasting the people, he became a famous person)

Sísè, n. cooking. Ìkòkò náà wà fún oúnjẹ sisè. (The pot is for cooking for)

Sísé, n missing. Sísé ọta jẹ́ ìjákulè tó ga nínú ẹgbẹ́ wọn. (Missing the target is a great failure in their club)

Sísè, n. dropping, falling. Ìrì sísẹ̀ kò yọ wọ́n lẹ́nu (The falling dew didn’t didn’t bother them)

Sísẹ́, n. denying, denial, draining, sifting, filtering. Ó kópa nímí sísẹ́ ra-ẹni (He practiced self-denial)

Sínsìn, n. the act of worship, service, rearing. Ó sọ̀rọ̀ nípa ẹran sínsìn (He talked about animal rearing)

Sísin, n. burial. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ ránṣẹ́ sílé fún sínsin (His body was sent home for burial)

Sísorọ̀, n. emphatic form of ‘Ìsorọ̀’, hanging. Ẹjọ́ ikú sísorọ̀ ni wọ́n dá a (He was sentenced to death by hanging)

Sísọ, n. throw, speech, utterance. Ó kọ ìwé nípa ọ̀rọ̀ sísọ (He wrote a book about the act of speaking)

Sísọjí, n. revival, awakening. Ó ń kọ̀wé lórí sísọ orin ìbílẹ̀ jí (He is writing about the revival of traditional music)

Sísọjọ̀, Sísọlọ́jọ̀, n. putting together in one place, collecting together a gathering together. Sísọ àwọn ìwé náà lọ́jọ̀ sójú kan kò rọrùn. (Putting the books together in one place is not easy)

Sísọ̀sọkúsọ, n. talking nonsense, prating, babbling. Sísọ̀sọkúsọ ni ó bá a wí sí (He warned for talking nonsense)

Sísú, n. wearing, nauseating

Sísùn, n. sleeping, asleep. Sísùn ló ń sùn (He is asleep)

Sísun, n roasting, flowing, oozing Sísun ni omi ń sun (Water was oozing out)

Sísúré, n. or adj. the same as ‘Sísáré’.

Sísúre, n. mode of pronouncing a blessing, the act of blessing. Sísúre ni ó ń súre fún wọn (He gave his blessing to them)

Síwájú, adv. more, forward, onward. Ó sún síwájú (He moved forward)

So, v.t. to tie, to bind, to bear fruit, to yield, to produce. Ó ti so wọ́n (He has tied them)

Só, v.i. to emit wind from the stomach. Ó ti só (He has emitted wind from the stomach)

Sòbìà, n. guinea-worm. Sòbìà mú un (He was attacked by guinea-worm)

Sòdẹ̀, n. beautiful woman

Sòfin, v.t. to prohibit, to make a law. Ó sòfin (He made a law)


Sogun ró, v.t. to rally an army. Ó sogun ró (He rallied his army)

Sókè, adv. in an upward direction, loudly. Àwọn ènìyàn rẹ́rìn-ín sókè (The people laughed loudly)

Sókèsókè, sókìlókè, adv. very high up. Ó jù ú sókèlókè (He threw it up very high)

Sokọ́, v.t. to hang, to string up. Ó so ó kọ (He hanged it)

Solù, Sopọ̀, v.t. to tie together. Ó so wọ́n pọ̀ (He tied them together)

Somọ́, v.t. to tie together, to unite, to join, to unite with, to suspend, to fasten upon, to tie to. Wọ́n so ó mọ́ igi. (They tied him to the tree)

Sònà, v.t. to hold at bay. Ó sònà mọ́ wọn (He held them at bay)

So ní yìgì, v.t. to marry, to unite in wedlock. Wọ́n so wọ́n ní yìgì. (They were united in wedlock)

Sòpàǹpá, v.t. to plot, to intrigue, to control trade, to conspire against. Wọ́n sòpàǹpá lé e lórí (They conspired against him)

Sopọ̀, Sopọ̀, sọ̀ken, v.t. to tie together to make one. Ó so wọ́n pọ̀ sọ̀kan (He tied them together to make them one)

Sórí, prep. above, on top of. Ó gbé e sórí àpótí (He placed it on the top of the box)

Sórí kodò, v.i. to be dyected, to be cast down. Ó sorí kodò (He felt dejected)

Sorí kọ́, v.t. to droop down the head, to be cast down, to give way to despair. Ó sorí kọ́ (He gave way to despair)

Sooró, n. Sadness, depression

Sorọ̀, v.t. to hang, to suspend. Ó so ó rọ̀ sórí igi. (He hanged it one the tree)

Sowọ́ lù, Sowọ́ pọ̀, v.i. to join hands together, to combine. Wọ́n sowọ́ pọ̀ ṣe iṣẹ́ náà. (They joined hands together to do the work)

So yìgì, v.i. to be married according to Muslim rite. Tàfá àti Múìbá yóò so yìgì (Tàfá and Múìbá are getting married according to Muslim rite)

Sọ, v.t. to speak, to talk, to tell, to shoot out of the ground or out of the stem of a tree. Ó sọ fún un (He told him)

Sọ́, v.t. to push into, to push inside. Ó sọ́ ọ sínú rẹ̀ (He pushed him inside it)

Sọ̀, v.i. to quarrel, to complain or grumble. Ó ń sọ̀ (He is grumbling)

Sọ̀, Sọ̀ kalẹ̀, v.t. to put down (as load) Ó ti sọ ẹrù rẹ̀ kalẹ̀ (He has put down his load)

Sọ̀, Sọ̀ kalẹ̀ v.i. to descend from a height, to desced. Ó ti sọ̀ láti orí igi. (He has descended from the top of the tree)

Sọ àsọdùn, v.t. to exaggerated. Ilé náà ní ẹ̀gbin, n ò sọ àsọdun o (The house is filthy, I am not exaggerating)


Sọ àsọyé, v.t. to define, to explain, to speak clearly. Ó sọ ọ̀rọ̀ náà ní àsọyé (He explained the matter)

Sọ bótibòti, v.i. to prattle. Ó ń sọ bótibòti nípa àwọn ọkùnrin náà ní gbégbo ìrọ̀lẹ́ (He pratted on about the men all evening)

Sọ bótò, v.i. to be loquacious, to be a talkative. Ó ń bsọ bótò (He is loquacious)

Sọdá, v.t. to cross, to cross over (as a stream) Ó sọdá omi náà (He crossed the stream)

Sọ dàbí, v.t. to make to be like to, make to look like. Ó sọ ọ́ dàbó tèmi (He made it to look like mine)

Sọdì, v.t. to make to become, to convert to. A sọ ọ́ di ọmọ ẹ̀sìn wa. (We converted into our religion)

Sọ di ahoro, Sọ dahoro, v.t. to devastate, to make desolate, to cause to fall into decay. Ó sọ ilé náà dahoro (He caused the house to fall into decay)

Sọ di àìmọ́, v.t. to make unclean, to pullute, to defile. Ó sọ ó di àìmọ́ (He made it unclean)

Sọ di aláìkú, v.t. to immortalize. Wọ́n sọ ọ́ di aláìkú (He was immortalized)

Sọ di ara, v.t. to embody to convert into flesh. Wọ́n sọ àkàrà di ara (The bread was converted into flesh)

Sọ di èérí, Sọ dèérí, v.t. to defile, to make unclean. Wọ́n sọ ọ́ dèérí (He was made unclean)

Sọ dìbàjẹ́, Sọ di búburú, v.t. to corrupt, to aggravate, to pollute. Wọ́n sọ ọ́ dìbàjẹ́ (It was polluted)

Sọ di mímọ́ v.t. to purify, to cleanse, to sanctify. Wọ́n sọ ọ́ di mímọ́ (It was purified)

Sọ di ńlá, v.t to enlarge. Wọ́n sọ ọ́ di ńlá (It was enlarged)

Sọ di òfo, So dòfo, v.t. to make empty. Wọ́n sọ ọ́ dòfo (It was made empty)

Sọ di olókùnrùn, v.t. to render sickly, to cause to be an invalid. Wọ́n sọ ọ́ di olókùnrùn (He was made to become an invalid)

Sọ di òmìnira, v.t. to make one free, to liberate. Wọ́n ti sọ wọ́n di òmìnira. (They have been liberated)

Sọ di òrìṣà, Sọ dòrìsà, Sọ dòòṣà, v.t. to make an idol of, to make a deity of, to idolibe. Wọ́n sọ ọ́ di òrìsà. (He was made a deity)

Sọ di ọ̀kan, v.t. to unite, to make one. Wọ́n sọ wọ́n di ọ̀kan (They made them one)

Sọ di ọmọ, Sọ dọmọ, v.t to adopt as one’s own child. Ó ti sọ ọ́ di ọmọ rẹ̀ (He has adopted him as his child)

Sọ di ọ̀tun, Sọ dọ̀tun, v.t. to renew, to make to be as good as new. Wọ́n ti sọ ọ́ dọ̀tùn (It has been renewed)

Sọ́dọ̀, prep. to near to. Ó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ (He went to him)

Sọ́gọ, v.t. to threst away from

Sọ̀gọ́, n. a peculiar style of plaiting the hair by women.

Sọgbà, v.i. to make a wooden fence round an area. Ó sọgbà yí ilé rẹ̀ ká (He made a fence round his house)

Sọgbá, v.t. to repair a broken calabash by sewing up the broken part with a strong with. Ó ń sọgbá náà. (He is repairing the broken calabash by sewing up the broken part with a strong with)

Sọ jáde, v.i. to speak out, to shoot out, to spring out. Ó ti sọ ọ̀rọ̀ jáde (The has spoken out)

Sọjẹ, v.t. to cut with the beak (as the hen, etc) Adìyẹ náà ti sọ ọ́ jẹ (The hen has cut it with its beak)

Sọjí, v.i. to recover from (swoon, etc.) Ó ti sọjí (He has recovered from a swoon)

Sọ́jọ, v.t. to collect together, to gather together. Wọ́n ti sọ́ wọ́n jọ (They have collected them together)

Sọjọ̀, Sọ lọ́jọ̀, v.t. to confine within certine within certain bounds, to keep. Ibí ni ó sọ ọ́ lọ́jọ̀ sí (He kept it here)

Sọ̀ kalẹ̀ v.i. to descend, to dismount, to come down. Ó sọ̀ kalẹ̀ láti orí igi. (He came down from the top of the tree)

Sọ̀kẹ̀sọ̀kẹ̀, n. familiarity, mutual intimacy. Sọ̀kẹ̀sọ̀kẹ̀ wọn pọ̀ (Their mutual intimacy is great)

Sọ́kì, v.i. to shrink, to contract Ó sọ́kì (It shrank)

Sọ kiri, v.t. to publish, to proclaim, to divulge. Wọ́n ń sọ kiri pé olè ni (They are proclaiming that he is a thief)

Sọ̀kọ̀, v.t. to throw stone. Ó sọ̀kò lù ú (He threw a stone at him)

Sọkún, v.t. to cry, to weep, to lament Ó sọkún (He cried)

Sọlẹ̀, v.i. to break into a house, to enter into a house burglariously, to burgle, to dig the ground. Ó sọlẹ̀ (He dug the ground)

Sọ lófin, v.t. to command, to prohibit, to make it a law. Wọ́n sọ ọ́ lófin fún un láti má mutí (He was prohibited from drinking alcohol)

Sọ lóògùn, v.t. to poison. Wóịn sọ ọ́ lóògùn (He was poisoned)

Sọ lóòkúta, v.t. to stone. Wọ́n sọ ọ́ lóòkúta (He was stoned)

Sọ lórúkọ to name, to give name to, to defame. Wọ́n sọ ọ́ hórúkọ (He was given a name)


Sọ lọ́jọ̀, v.t. see Sọjọ̀

Sọlù, v.t. to attack, to assault, to throw (stone, etc.) at. Ó sọ òkúta lù ú (He threw a stone at him)

Sọ lura, v.t. to collide, to encounter, to engage each other (as in battle) Wọ́n sọ òkúta lura (They threw stones at each other)

Sọ méjì, v.i. to equivocate, to be double tongued. Ẹ̀sùn pé ó ń sọ méjì ni wọ́n fí kàn án (He was acussed of being double-tongued)

Sọmídọlọ́tọ̀, Oloyo, n.a yellow-haired monkey

Sọmọ́, v.t. to dovetail, to inter-weave, to interlock. Ó sọ wọ́n mọ́ ara wọn (He interlocked them)

Sọ mọ́ra, v.t. to draw close to one another, to interlock. Ó sọ wọ́n mọ́ra (He interlocked them)

Sọ́ngo, Zóngo, n. a temporary camping place by a group of Hausas)

Sọ níkòó, v.t. to punch on the inead. Ó sọ ọ́ níkòó (He punched him on the head)

Sọnù, v.i. to be lost. Ó sọnù (He was lost)

Sọnu, v.i. to take the evening meal (e.g. the Muslims during their fast) O sọnu (He broke his fast in the evening during fast)

Sọ́ra kì, Súnkì, v.i. to contract, to shrik. Ó súnkì (It shrank)

Sọra nù, v.i. to be careless of oneself. Ó sọra nu (He was careless with himself)

sọ̀rọ̀, v.t. to speak, to talk. Ó ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ (He talk to the people)

Sọ̀rọ̀ lù, Sọ̀rọ̀ pọ̀, v.i. to speak in chorus, to speak together. Wọ́n jọ sọ̀rọ̀ pọ (They spoke together)

Sọ̀sọkúsọ, v.t. to talk nonsense. Ó ń sọ̀sọkúsọ (He was talking nonsense)

Sọ tẹ́lẹ̀, v.i. to tell beforehand, to prophesy. Ó ti sọ fún un tẹ́lẹ̀ (He had told him beforehand)

Sọ tinú ẹni, v.i. to speak out what is in one’s mind. Ó tọ kí a sọ tinú ẹni (It is better for one to speak out what is in one’s mind)

Sótọ̀, adv. aside, apart, separately. Ó yà wọ́n sọ́tọ̀ (He puts them apart)

Sọwò. V.t. to weigh by balancing in the hand, to reattack (as disease) Ó sọ iṣu wáà wò (He weighed the yam by balancing it in his hand)

Sú, v.t. to sow, to retail Coil, liquor, snuff, etc.) to tire, to weary, to loathe, to embarrass, to nauseate, to limp the foot. Ó sú mi (I am tired)

Sú, v.i. to break forth, to erupt, to appear in numbers on the surface, to sprout luxuriously. Ewéko sú (Plants sprouted luxuriously)

Sù, v.i. to congeal (as oil) Epo náà ti sù (The oil has congealed)

Suu, adv. thoughtfully, deliberately extensively. Ó wò ó lo suu (He looked at it thoughtfully)

Súà, adv. extensively, far and wide. Ó tàn lọ súà (It spread extensively)

Sú bọ̀, v.t. to be covered with small pox, measles, etc. Ìrorẹ́ sú bò ó lójú (His face is covered in piniples)

Sùbọ̀, v.i. to have enough and to spare. Oúnjẹ náà sù mú bọ̀ (I have enough food and more to spare)

Sùẹ̀sùẹ̀, n. slothfulness, sheggishness, stupidity, It is also used as an adverb, slothfully, sluggishly, stupidly. Ó ń rìn sùẹ̀sùẹ̀ (He was walking sluggishly)

Súfèé, v.i to whistle. Ó súfèé (He whistled)

Sùgọ̀, adv. stepidly, dull. Ó ń wo àwòrán náà sùgọ̀ (He was starring stupidly at the picture)

Sùgọ̀sùgọ̀, n. dullness, stupidity, awkwardness. Ó rẹ́rìn-ín láti bo ìwà sùgọ̀sùgọ̀ ọkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ (He laughed to cover up his feeling of awkwardness)

Súkèsúkè, n. hiccough. Súkèsúkè ń ṣe é (He had hiccoughs)

Sun, v.t. to roast, to grill, to burn, to ooze or spring out as water. Ó sun ún (He burnt it)

Sún, v.i. to move. Ó sún un (He moved it)

Sun deérú, v.t. to burn to ashes. Ó sun igi náà deérú (He burnt the wood until it become ashes)

Sùn fẹ́ẹ́rẹ́, Sùn yẹ́ẹ́,v.t. Ó sùn fẹ́ẹ́rẹ́ (He had a nap)

Sùn fọnfọn, v.i. to sleep soundly, to sink into a deep sleep. Ö ti sùn lọ fọnfọn (He has sunk into a deep sleep)

Sun jáde v.i. to ooze out, to spring forth. Omi náà sun jáde láti inú àpáta (The water springs forth from the rock)

Súnkì, Sọ́kì, v.i. to shrink, to contract. Ó súnkì (It shrank)

Sùn lé v.t. to wean a child from the breast. Wọ́n fẹ́ sùn lé ọmọ náà (They wanted to wean the child from the breast)

Sún mọ́, v.t. to move close to, to approach, to draw near. Ó sún mọ́ ọn (He moved close to him)

Sún mọ́dọ̀, v.t. to approach, to draw near. Ó sún mọ́dọ̀ mi. (He drew near me)

Sùmmọ̀mí, n. foray, raid. A gbé sùnmọ̀mí lọ sí ìlú wọn (We raided their town)

Sún mọ́tòsí, Sún mọ́lé, v.i. to draw near, to be in the neighbourhood. Ó ti sún mọ́tọ̀sí (He is already in the neighbourhood)

Súnramú, v.i. to be prepared beforehand. Ó ti súnramú (He has prepared beforehand)

Sun-unrun Sun-unrun, n. Sleeping sickness, drowsiness. Àìsàn ilẹ̀ olóoru ni sun-unrunsun-unrun sleeping sickness is a tropical disease)

Súnsẹ̀, v.i. to limp in walking, to drag one’s foot. Ó ń súnsẹ̀ (He is dragging his feet)

Sún síwájú, v.t. to push forward, to promote an object or enterprise. Ó sún un síwájú (He pushed it forward)

Sunwọ̀n, adj. Ó sunwọ̀n (It is good)

Súrà, n. Kind, sort, variety. Irú súrà won i? of what sort is it?

Súré, sáré, v.i. to run, to hasten, to be rash. Ó sáré (He ran)

Súùre, Súùre fún, v.t. to bless. Ó súùre fún un (He blessed him)

Súrénbájà, v.t. to struggle desperately, done hastily and in a slapdash fashion. Súrénbájà ní ó fi ṣe (He did it hastly and in a slapdash fashion)

Súré Ṣáájú, v.i. to run before one. Ó súré ṣáájú rẹ̀ (He ran before him)

Sùúrù, n. patience. Ó ní sùúrù (He showed patience)

Súúsùùsú, adv. stealthily. Ó pa súúsùùsú (He went stealthily)

Sútà, v.t. to retail liquor, snuff, etc. to sell by measure. Ó sú ọtí tà (He sold liquor by measure)

Sùtì, Ṣùtì, n. a contemptuous pointing of the lips, a hiss, to purse up lips in contempt. Ó yọ sùtì ètè sí mi (He pursed up his lips in comtempt of me)